Ògbómọ̀ṣọ́

(Àtúnjúwe láti Ogbomosho)

Ògbómọ̀ṣọ́ jẹ́ ìlú kan tó gbajúmọ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lórílẹ̀-èdè Naijiria.[1][2]

Ògbómọ̀ṣọ́
Ìlú
Ìlú Ògbómọ̀ṣọ́ lati oju satellite
Ìlú Ògbómọ̀ṣọ́ lati oju satellite
Orílẹ̀-èdè Nigeria
IpinleOyo
Agbegbe Ijoba IbileOgbomoso

ìtàn nípa Ìlú Ògbómọ̀ṣọ́

àtúnṣe

Ogunlọlá jẹ ọdẹ, ògbótari, tí ó mọ̀n nípa ọdẹẹ síse ó féràn láti máa lọ sísẹ́ Ọdẹ nínú igbó ti a máa ni ìlú Ògbómòsọ́ tí à pè ní igbó ìgbàlè, ṣùgbọ́n ọkùnrin yii ti o jẹ ogunlọlá ṣe Baale àdúgbọ̀ tí ó Ogunlọlá gbé nígbà nàá. Baale o ríi wí pe Ogunlọlá gbé àdùtú àrokò náà lọ sí ọ̀dọ̀ Aláàfin. Aláàfín àti àwọn emẹ̀wà rẹ̀ yìí àrokọ̀ náà títí, wọ́n sì mọ̀ ọ́ tì. Pẹ̀lú líhàhílo, ìfòyà, aibalẹ ọkàn nípa OGUN Ọ̀GBÒRỌ̀ tí ń bẹ ló de Ọ̀yọ́, kò mú wọn ṣe ohunkóhun lórí ọ̀rọ̀ Ogunlọlá, wọ́n si fi í pamọ́ si ilé olósì títí wọn yóò fi ri ìtumọ̀ sí àrokò náà. Ní ọjọ́ kan, Ogunlọlá ń sẹ ọdẹ nínú igbó ìgbàlè-àdúgbò i bi tí Gbọ̀ngàn ìlú ògbímòṣọ́ wà lonìí. Igbó yìí, igbó kìjikìji ni, ó ṣòro dojúkọ̀ kí jẹ́ pé ọdẹ ní ènìyàn, kó dà títí di ìgbà tí ojú tí là sí i bí ọdun 1935, ẹ̀rù jẹ́jẹ́ l’o tún jẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ìlú láti wọ̀ ọ́ ńitorí wí pé onírúurú àwọn ẹnranko búburú l’ó kún ibẹ̀. Àní ni ọdún 1959, ikooko já wo Ile Ògúnjẹ́ ńlé ni ìsàlè-Àfọ́n gẹ́gẹ́ bi ìròyìn, ikooko já náà jáde láti inú igbó ìgbàlè yìí ni àwọn ALÁGỌ̀ (àwọn Baálè tí wọ́n ti kú jẹ rí ní ògbómọ̀ṣọ́, tí wọ́n sì jẹ́ ẹlẹsin-ìbílẹ̀) máà ń gbé jáde nígbà tí ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀ bá ń ṣe ọdun Ọ̀LẸ̀LẸ̀. Láti pa á mọ́ gẹ́gẹ́ bi òpẹ títí di òní, nínú Gbọ̀ngàn Ògbómòṣọ́ ní àwọn Alágà náà ń ti jáde níwọ̀n ìfbà tí ó jẹ́ wí pé ara àwọn igbí ìgbàlè náà ní ó jẹ́. Ogunlọlá kó tí í tin jìnnà láti ìdí igi Àjàbon (ó wá di òní) tí ó fi ń ri èéfín. Èéfín yìí jẹ́ ohun tí ó yá à lẹ́nu nítorí kò mọ̀ wí pé iru nǹkan bẹ́ẹ̀ wà ní itòsí rẹ̀ Ogunlọlá pinnu láti tọ paṣẹ̀ èéfín náà ká má bá òpò lọ sílé Olórò, àwọn ògbójú ọdẹ náà rí ara wọn, inú swọn sí dùn wí pé àwọn jẹ pàdé. Orukọ àwọn tí wọ́n jẹ pàdé awa wọn náà ní:- AALE, OHUNSILE àti ORISATOLU. Lẹ̀yìn tí wọn ri ara wọn tan, ti wọn si mọ ara wọn; wọ́n gbìdánwò láti mọ ibi tí Olukaluku dó sí ibùdó wọn. Nínú gbogbo wọn Ogunlọla níkan l’ó ni ìyàwó. Wọ́n sì fi ìbùdó Ogunlọlá ṣe ibi inaju lẹ́yìn iṣe oojọ wọn. Lọ́rùn-ún-gbẹkun ń ṣe ẹ̀wà tà, ó sí tún ń pọn otí ká pẹ̀lú; ìdí niyìí tí o fi rọrun fún àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ Lọ́rùn-un-gbẹ́kún láti máa taku-rọ̀sọ àti lati máa bá ara wọn dámọ̀ràn. Bayíí, wọ́n fí Ogunlọla pamọ́ sí ọ̀dọ̀ Olósì. Ìtàn fi yé wa wí pé Ọba Aláàfin tí ó wà nígbà náà ni AJÁGBÓ. Rògbò dèyàn àti aápọn sì wà ní àkókò ti Ogunlọlá gbé aro ko náà lọ si Ààfin Ọba; Ogun ni, Ogun t’ó sì gbóná girigiri ni pẹ̀lú-Orúkọ Ogun ni, Ogun náà ni OGUN Ọ̀GBỌ̀RỌ̀. Nínú ilé tí a fi Ogunlọla. sí, ni ó ti ráńṣe sí Aláàfìn wí pé bí wọ́n bá le gba òun láàyè òun ní ìfẹ́ sí bí bá wọn ní pa nínú Ogun ọ̀gbọ̀rọ̀ náà. Ẹni tí a fi tì, pàrọwà fún Ogunlọla nítorí wí pé Ogun náà le púpọ̀ àti wí pé kò sí bí ènìyàn tilẹ́ lé è ní agbára tó tí ó le ṣégun ọlọ̀fè náà. Wọn kò lée ṣe àpèjúwe ọ̀lọ̀té náà; wọ́n sá mọ̀ wí pé ó ń pa kúkúrú, ó sí ń pa gigun ni. Aláàfin fún Ogunlọlá láṣẹ láti rán rán òun lọ́wọ́ nípa Ogun ọ̀gbọ̀rọ̀ náà. Aláàfín ka Ogunlọlá sí ẹni tí a fẹ́ sun jẹ, tí ó fi epọ ra ara tí o tún sún si ìdìí ààro, ó mú isẹ́ẹ sísun Yá ni. Alaafin súre fún Ogunlọlá. iré yìí ni Ogunlọla bà lé. Ogunlọlá dójú Ogun, ó pitu meje tí ọdẹ pa nínú igbo ó sẹ gudugudu meje Yààyà mẹ́fà. Àwọn jagun-jagun Ọ̀yọ́ fi ibi ọta gunwa sí lórí igin han atamatane Ogunlọlá, Ogunlọá sì “gán-án-ní” rẹ̀. Nibi ti ọta Alaafin yìí tí ń gbiyanju láti yọ ojú síta láti ṣe àwọn jagun-jagun lọ́sé sé ọfà tó sì loro ni ọlọ̀tẹ̀ yìí ń ló; mó kẹ̀jẹ̀ ní Olọ̀tẹ̀ kò tí ì mórí bọ́ sínú tí ọrun fi yo lọ́wọ́ Ogunlọlá; lọrun ló sí ti bá Olọ̀tẹ̀; gbirigidi la gbọ to Ọlọ̀tè ré lulẹ lógìdo. Inú gbogbo àwọn jagun-jagun Ọ̀yọ́ sì dún wọ́n yọ sẹ̀sẹ̀ bí ọmọdé tí seé yọ̀ mọ̀ ẹyẹ. Ogunlọlá o gbé e, o di ọ̀dọ̀ Aláàfin; nígbà yìí ni Aláàfin to mo wí pé Ẹlẹ́mọ̀sọ̀ ni ń ṣe alèṣà lẹ́yìn àwọn ènìyàn òun. Bayìí ni Ogunlọlá ṣe àseyorí ohun ti ó ti èrù jẹ̀jẹ̀ sí ọkan àyà àwọn ara ilu ọ̀yọ́. Aláàfin gbé Oṣiba fún Ogunlọlá fún iṣé takun-takun tí ó ṣe, o si rọ̀ ó kìí ó dúró nítòsi òun; ṣùgbọ́n Ogunlọlá bẹ̀bẹ̀ kí òun pasà sí ibùdó òun kí ó ó máa rańsẹ sí òun. Báyìí Aláàfin tú Ogunlọlá sílẹ̀ láàfín nínú ìgbèkùn tí a fii sí kò ní jẹ́ àwáwí rárá láti sọ wí pé nínú ìlàkàkà àti láálàà tí Ogunlọlá ṣe ri ẹ̀yín Ẹlẹ́mọsọ ni kò jọ́ sí pàbó tí ó sí mú orukọ ÒGBÓMỌ̀SỌ́ jade. Erédì rẹ nìyìí Gbara tí a tú Ogunlọla sílẹ̀ tán pẹ̀lu asẹ Alaafin tí ó sì padà si ibùdó rẹ̀ nì ìdí igi Àjàgbọn ni bí èrò bá ń lọ́ tí wọn ń bọ́, wọn yóò máa se àpèjuwe ibudo Ogunlọlá gẹ́gẹ́ bíí Bùdó ò-gbé-orí-Ẹlẹmọsọ; nígbà tí ó tún ṣe ó di Ògbórí-Ẹlẹmọ̀ṣọ́ kó tó wà di Ògbẹ́lẹ́mọ̀sọ́; ṣùgbọ́n lónìí pẹ̀lú Ọ̀làjú ó di ÒGBÓMỌ̀SÓ

Iselu ni Ogbomoso

àtúnṣe

Baálẹ̀ ni Olórí ìlú Ògbómọ̀ṣọ́. Nínú ìlànà ètò ìjọba, agbára rẹ̀ kò jut i ìgbìmọ̀ àwọn ìjòyè ìlú rẹ̀ lọ. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ti ṣe àlàyé wipe irú ètò báyìí wà láti rí pé Baálẹ̀ tàbí Ọba kò tàpá sí àwọn ìgbìmọ̀ ìjòyè kí gbogbo nǹkan lè máa lọ déédéé ni ìlú. Irú ètò yìí yàtọ púpọ̀ sí ìlànà ètò Ìjọba àwọn ìlú aláwọ̀-funfun ninú eyi ti àṣẹ láti ṣe òfin wà lọ́wọ́ ilé aṣòfin, tí ètò ìdájọ́ wà lọ́wọ́ ìgbìmọ̀ ìjọba. Ẹkìínní kò gbọ́dọ yọ ẹnu sí iṣẹ́ èkejì, oníkálukú ló ni àyè tirẹ̀. Ní ti ètò ìjọba Yorùbá, Ọba atì àwọn ìjòyè ńfi àga gbá’ga ni nínú èyí tí ó jọ pé ìjà le ṣẹlẹ̀ láàrin wọn bi ọ̀kan bá tayọ díẹ̀ sí èyí. Ohun tí ó mu un yàtọ̀ ni wípé Ṣọ̀ún, baba ńlá ìdílé àwọn Baálẹ̀, dé sí ibi tí ó di Ògbómọ̀ṣọ́ lónìí lẹ́hìn tí àwọn mẹ́ta ti ṣaájú rẹ̀ dé ibẹ̀. Nipa akíkanjúu rẹ̀ ló fi gba ipò aṣíwájú lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ yókù. Akẹ́hìndé sì di ẹ̀gbọ́n lati igba yi lọ títí di òní, àwọn baálẹ ti a ti jẹ ní Ògbómọ̀ṣọ́ kò jẹ́ kí àwọn ìdílé ẹni mẹ́ta ti o ṣaáju Ṣọ̀ún dé ìlú jẹ oyè pàtàkì kan. Ẹ̀rù mbà wọ́n pé ìkan nínú àwọn ọmọ ẹni mẹ́ta yìí lè sọ wípé òun ní ẹ̀tọ́ láti ṣe Olórí ìlú. Nitorina ni o fi jẹ́ pé àwọn ìjòyè ìlú tí o mbá Baálẹ̀ dámọ̀ràn láàrin àwọn ẹni tí ó dé sí ìlú lẹ́hìn Ṣọhún ní a ti yan wọ́n. Síbẹ̀ náà, Baálẹ̀ kan kò gbọdọ̀ tàpá si ìmọ̀ràn àwọn ìjòyè ìlú, pàápàá nínú àwọn ọrọ tí ó jẹ mọ iṣẹ̀dálẹ̀. Èyí ṣe pàtàkì jù ní nǹkan ọgọ́rùn ọdún sí àkókò ti a ńsọ nípa rẹ̀ yìí. Àwọn ópìtàn ìlú Ògbómọ̀ṣọ́ sọ pé gbogbo àwọn Baálẹ̀ ti wọn tàpá si ìmọ̀ràn ìjòyè ìlú ni Aláàfin rọ̀ lóyè. Abẹ́ Aláàfin ni Ògbómọ̀ṣọ́ wà ní ìgbà náà....

  • Oludare Olajubu Ìwé Àsà ìbílè Yorùbá, Ojú-iwé 1-11, Ikeja; Longman Nigeria Limited, 1975.
  • Babátúndé Agírí. Ètò Ìsèlù ní Ògbómòsó ní ìwòn Ogórùn Odún séhìn; Ojú-iwé 97-104.

Àtòjọ orúkọ àwọn olórí ìṣájú

àtúnṣe

Olùṣèdásílẹ̀ Ogbomoso ni Soun Olabanjo Ogunlola Ogundiran. Òun ni Ṣọ̀ún Ògbómọ̀ṣọ̀ àkọ́kọ́. Ó ní ọmọ márùn-ún, orúkọ wọn ni, Lakale, Kekere Esuo, Eiye àti Jogioro. Ọmọ àbígbẹ̀yìn rẹ̀, ìyẹn Erinbaba Alamu Jogioro ló gorí oyè lẹ́yìn rẹ̀, òun sì ni Sọ̀ún ẹlẹ́ẹ̀kejì. Àwọn ìdílé máràràrún tí wọ́n ṣèjọba ní Ògbómọ̀ṣọ̀ wá láti ìran àwọn ọmọ márùn-ún tí Soun Ikomeyede, èyí tó jé Sọ̀un kẹta ti Ògbómọ̀ṣọ́ (àti ọmọ Jogioro), àwon ọmọ náà ni Toyeje, Oluwusi, Baiyewu, Bolanta Adigun, àti Ogunlabi Odunaro. Oyè Soun fìgbà kan jẹ́ oyè Baale (èyí tó jẹ́ olóyè kékeré) nítorí Ògbómọ̀ṣọ̀ fìgbà kan jẹ́ ìlú kékeré láàárín Ọ̀yọ́. Ní ọdún 1952, oyè náà yí padà sí Ṣọ̀ún, ó sì jẹ́ oyè tí gbogbo ènìyàn mọ̀ títí dọ̀ní.[3] Èyí ni àtòjọ orúkọ àwọn olórí ìṣáájú:

  • Soun Olabanjo Ogunlola Ogundiran (c. 1659 – c. 1714)
  • Soun Erinsaba Alamu Jogioro (ọmọ Ogunlola) (c. 1741 – c. 1770)
  • Soun Ikumoyede Ajo (ọmọ Jogioro) (c. 1770 – c. 1797)
  • Ologolo (ọmọ Jogioro) àti Olukan (ọmọ ọmọ Lakale àti ọmọ-ọmọ-ọmọ-ọmọ Ogunlola) ṣèjọba lásìkò yìí àmọ́ Alaafin ìlú Oyo yọ wọ́n lórí oyè.
  • Soun Toyeje Akanni Alebiosu, tó jẹ́ Aare Ona Kakanfo ti ìlú Oyo (ọmọ Ikumoyede) (c. 1800 – c. 1825)
  • Soun Oluwusi Aremu (ọmọ Ikumoyede) (c. 1826 – c. 1840)
  • Soun Jayeola Bayewu Kelebe "Are Arolofin Alao" (ọmọ Ikumoyede) (c. 1840 – c. 1842)
  • Soun Idowu Bolanta Adigun (ọmọ Ikumoyede) (c. 1842 – c. 1845)
  • Soun Ogunlabi Odunaro (ọmọ Ikumoyede) (c. 1845 – c. 1860)
  • Soun Ojo Olanipa "Aburumaku," tó jẹ́ Aare Ona Kakanfo ti ìlú Oyo (ọmọ Toyeje) (c. 1860 - September 1869)
  • Soun Gbagungboye Ajamasa Ajagungbade I (ọmọ Oluwusi) (1869 - c. 1871)
  • Soun Laoye Atanda Orumogege (ọmọ Bayewu) (c. 1871 – c. 1901)
  • Soun Majengbasan Elepo I (ọmọ Bolanta) (1901 - 1907)
  • Soun Adegoke Atanda Olayode I (ọmọ Odunaro) (1908 - 1914; deposed by the Colonial Government)
  • Soun Itabiyi Olanrewaju Ande (ọmọ Aburumaku, grandson of Toyeje) (1914 - 1916)
  • Soun Bello Afolabi Oyewumi Ajagungbade II (ọmọ Ajagungbade I, ọmọ-ọmọ Oluwusi) (1916 - February 18, 1940)
  • Soun Amao Oyetunde (ọmọ Oyekola (tí wọn o yàn), ọmọ-ọmọ Laoye, àti ọmọ-ọmọ-ọmọ Bayewu) (1940 - June 12, 1944; deposed by the Colonial government, removed from some monarch lists); he was succeeded by his uncle
  • Soun Lawani Oke Lanipekun (ọmọ Laoye, ọmọ-ọmọ Bayewu) (October 16, 1944 - March 19, 1952)
  • Oba Olatunji Alao Elepo II (ọmọ Elepo I, ọmọ-ọmọ Bolanta) (1952 - 1966)
  • Oba Emmanuel Olajide Olayode II (ọmọ Olayode I, ọmọ-ọmọ Odunaro) (July 22, 1966 - July 1, 1969; tí wọ́n pa lásìkò rògbòdìyàn Agbekoya
  • Oba Salami Ajiboye Itabiyi II (ọmọ Itabiyi, ọmọ-ọmọ Aburumaku, ọmọ-ọmọ-ọmọ Toyeje) (June 4, 1972 - June 2, 1973)
  • Oba Jimoh Oyewunmi Ajagbungbade III (ọmọ Ajagungbade II, ọmọ-ọmọ Ajagungbade I, great-grandson of Oluwusi) (October 24, 1973 - December 12, 2021) HM Jimoh Oyewunmi Ajagbungbade III ti Oluwusi Royal House jẹ́ Ṣọ̀ún tó pẹ ju láyé, ó sì kú and died on December 12, 2021, at the age of 95
  • Oba Ghandi Afolabi Olaoye Orumogege III (Olaoye is the paternal great-grandson of Soun Laoye Atanda Orumogege through his son Emmanuel Oladayo Olaoye, who was a brother of Soun Lawani Oke Lanipekun) (September 8, 2023 -)[4][5][6]

Ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, 02 of September, 2023, wọ́n yan Ṣọ̀ún ìmíì sípò, òun sì ni Prince Afolabi Ghandi Olaoye, ẹni tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kéde rẹ̀.

Ètò-ẹ̀kọ́

àtúnṣe

Ogbomosho ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga mẹ́rin tí ń fúnní ní oyè ẹ̀kọ́ àti àmì-ẹ̀yẹ ìgbẹ̀kọ́.[7] Ladoke Akintola University of Technology (LAUTECH) jẹ́ èyí tí wọ́n fi orúkọ ọmọ Ogbomosho soọrí, tí ó sì gbajúmọ̀ ní apá Ìwọ̀-oòrùnilẹ̀ Nàìjíríà, órúkọ rẹ̀ ni Samuel Ladoke Akintola (SLA). Wọ́n fi LAUTECH ṣáájú àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga tó gbòkè bọ̀ ní Nàìjíríà. Ó ń ṣètò oyè ẹ̀kọ́ nínú ìmọ̀ science, engineering, technology àti èkọ́ ìsègùn (medicine).[8] Ilé-ẹ̀kọ́ gíga yìí ní ilé-ìwòsàn tí wọ́n sọ ní orúkọ rẹ̀, ìyẹn Lautech Teaching Hospital.[9]

Nigerian Baptist Theological Seminary (NBTS),[10] jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga tó pè jù ní Nàìjíríà, ó sí jẹ́ ilé-èkọ́ gíga àkọ́kọ́ tí wọ́n ti gboyè ẹ̀kọ́ nínú ìmọ̀ ẹ̀sìn bíi theology, sociology àti philosophy. Ilé-ẹ̀kọ́ yìí wá̀ lábẹ́ Baptist Church in Nigeria, The Nigerian Baptist Convention (NBC), tó máa ń wáyé bákan náà ní Ibadan, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.[11]

Bowen University Teaching Hospital Ogbomoso- (BUTH) [12] tó jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ tí àwọn Kìrìsìtẹ́ẹ́nì fún àwọn tó fé gboyè ẹ̀kọ́ nínú ìmọ̀ ìṣègùn, jẹ́ èyí tí wọ́n dásílẹ̀ ní March 1907,[13] ó sì di ilé-ẹ̀kọ́ tí wọ́n ́ kọ́ nípa ètò ìṣègún ní 2009. BUTH ní orí-ìbùsùn 400, òṣìṣẹ́ tó ju 800 lọ, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́, pẹ̀lú àwọn ohun àmúyẹ lóríṣiríṣi. Lára àwọn oyè ẹ̀kọ́ tí wọ́n sì ń fúnni ni B.Sc. Anatomy, B.Sc. Physiology àti MB/BS.[14][15]

Ìjọba àpapọ̀ ti orílẹ-èdẹ̀ Nàjíríà ti fòǹtẹ̀ lu ìdásílẹ̀ Federal Polytechnic, Ayede, tó wà ní ìlú kékeré kan ní Ògbómọ̀ṣọ́. Ìgbẹ̀kọ́ àti iṣẹ́-ìwádìí á tó bẹ̀rẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ yìí láìpẹ́.[16]

Bákan náà,ilé-ìwé ti ìjọba àpapọ̀ eyí tí ń ṣe Federal Government College, Ogbomosho àti Nigerian Navy Secondary School, Ogbomosho wà ní ìlú náà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé-ìwé aládàáni ló wà ní ìlú náà bí i Pine Valley High School, Faith Academy, Smith International Baptist Academy, Gomal Baptist College, George Green Baptist College, Zoe Schools, Maryland Catholic High School, Lautech International College, Royal International College, Zion Christian Academy, àti Command Secondary School, Gambari.[17]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Ogbomoso". placeandsee.com. 2019-10-05. Retrieved 2022-05-03. 
  2. Okunade, Johnson (2019-03-13). "THE FULL HISTORY OF OGBOMOSO". WELCOME TO MY WOVEN WORDS. Archived from the original on 2022-07-04. Retrieved 2022-05-03. 
  3. "Soun Dynasty". 
  4. "The Souns | the Land of Ogbomoso". Archived from the original on 2023-04-25. Retrieved 2023-12-03. 
  5. "Soun Dynasty". 
  6. "Aare Muhammadu Buhari ránṣẹ́ sí ìlú Ogbomoso lórí ikú Soun". 12 December 2021. 
  7. Nigeria, Guardian (2018-05-20). "Nigerian baptist theological seminary at 120". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2023-06-10. Retrieved 2023-06-10. 
  8. "Ladoke Akintola University". lautech.edu.ng. Ladoke Akintola University. Retrieved 19 January 2014. 
  9. Bola Bamigbola. "Osun renames LAUTECH Teaching Hospital". www.google.com. Retrieved 2023-06-10. 
  10. NBTS
  11. "The Nigerian Baptist Theological Seminary". nbts.edu.ng. The Nigerian Baptist Theological Seminary. Retrieved 19 January 2014. 
  12. BUTH
  13. "6: Christian Missionary Activities in West Africa – History Textbook" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-09-18. 
  14. "Bowen University Teaching Hospital Ogbomoso - BUTH". Archived from the original on 2016-03-08. Retrieved 2016-03-08.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  15. "History of Bowen University Teaching Hospital Ogbomoso". www.buth.edu.ng. Retrieved 2020-05-28. 
  16. Adejumo Kabir. "FG approves establishment of new polytechnic in Oyo". www.premiumtimesng.com. Retrieved 2023-06-10. 
  17. "George Green Baptist College - GGBC Ogbomoso". ggbc.buth.edu.ng. Retrieved 2023-06-10.