Olayemi Ogunwole
Ọláyẹmí Ògúnwọlé jẹ́ gbajúgbajà pẹ̀lú orúkọ oníṣẹ́ rẹ̀ (Honey Pot) lórí èrò àsọ̀rọ̀-mágbèsì àti èrọ amóhùn-máwòrán TVC Communications ní ìpínlẹ̀ Èkó.[1]
Olayemi Ogunwole | |
---|---|
Olayemi Ogunwole popularly known as HoneyPot in Lagos, Nigeria | |
Alma mater | Obafemi Awolowo University |
Show | Chat Hour |
Station(s) | 102.3 MAX FM, Lagos |
Network | TVC Communications |
Time slot | 8pm - 11pm (GMT +1), Mondays - Thursdays |
Show | Entertainment Splash |
Station(s) | TV Continental |
Network | TVC Communications |
Time slot | 1pm - 2pm (GMT +1), Mondays - Fridays |
Country | Nigeria |
Previous show(s) | Midday Belt |
Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeOníṣẹ́ (Honey Pot) kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì nílé ẹ̀kọ́ àgbà Ilé Ifẹ̀ Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ University, Nàìjíríà.[2][3]
Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeÌbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìròyìn rẹ̀
àtúnṣeỌláyẹmí bèrè iṣẹ́ ìròyìn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ lásìkò ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní OAU, Ilé-Ifẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùgbàlejò lórí ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán NTA ti Ilé-Ifẹ̀ níbi tí ó tí ń darí ètò tí ó ń jẹ́ Fact Finding with Yemi. Ó tún jẹ́ ọ̀kan lára àjọ Orientation Broadcasting Service (OBS) nigba tí ó ń ṣe Àgùnbánirọ̀ National Youth Service Corps rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Anambra, Nàìjíríà.[4][5]
Lẹ́yìn tí ó parí Àgùnbánirọ̀ (NYSC), ó tè síwájú láti ṣe agbátẹrù Bísí Ọlátilọ Show (BOS). Ó tún lọ sí ilé èkọ́ FRCN láti kẹ́kọ̀ọ́ síwájú si. Ó tún ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ ìgbóhùn-sáfẹ́fẹ́ Rock City 101.9 FM, ní Abẹ́òkúta, níbi tí ó tí ṣètò Rock Game tí ó sì tún jẹ́ aka ìròyìn. Ó sì tún ṣiṣẹ́ ní Star 101.5 FM, níbi tí ó ti ṣ̀ètò Midday Belt tí ó sì tún ka ìròyìn ojoojúmọ́, ṣáájú kí ó tó ta àtapò sí ilé iṣẹ́ ìgbóhùn-sáfẹ́fẹ́ Rainbow 94.1 FM, níbi tí ó ti jẹ́ ọ̀gá àgbà àwọn elétò ní ilé iṣẹ́ ìgbóhùn-sáfẹ́fẹ́ Max FM tí ó ń jẹ́ (Radio Continental) tẹ́lẹ̀.[6]
Àwọn iṣẹ́ rẹ̀ mìíràn
àtúnṣeYàtọ̀ sí iṣẹ́ ìgbóhùn-sáfẹ́fẹ́,ó tún ti ṣe ìpolówó ọjà fún Harpic, First Monie ti First Bank àti àwọn ilé iṣẹ́ ọlọ́jà mìíràn. Òun àti Ruggedman ni ó ṣagbá-tẹrù ìgbàlejò àmì ẹ̀yẹ ayẹyẹ City People Music Awards ní ọdún 2017.[7][8]
Àwọn àmì ẹyẹ fún ìdánimọ̀
àtúnṣeWọ́n fun ní àmì ìdánimọ̀ àtàtà Special Recognition Award fún iṣẹ́ ribi-ribi àti ipa mále gbàgbé rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìjábọ̀ ìdárayá lórí àmóhùn-máwòrán pàá pàá jùlọ City People ní ọduń 2016.[9]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Ajose, Kehinde. "There is no limit to how far women can rise in the media". Vanguard Nigeria. https://www.vanguardngr.com/2016/05/no-limit-far-women-can-rise-media/amp/. Retrieved 5 July 2018.
- ↑ "- 102.3 Max FM". Archived from the original on 2018-01-08. Retrieved 2018-10-13.
- ↑ Sokoya, Seye. "I’m comfortable with my body —Honey Pot". Nigerian Tribune. http://www.tribuneonlineng.com/110449/. Retrieved 5 July 2018.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Meet The Honey Pot of MaxFM , Olayemi Ogunwole - 102.3 Max FM". 7 April 2018. Archived from the original on 25 January 2021. Retrieved 13 October 2018.
- ↑ Kehinde, Seye (31 July 2017). "I am a Happy-Go-Lucky Girl - Honeypot, TVC Entertainment Splash Presenter". City People online. http://www.citypeopleonline.com/happy-go-lucky-girl-honeypot-tvc-entertainment-splash-presenter/. Retrieved 5 July 2018.
- ↑ Anonymous (25 October 2017). "TVC Communications launches 102.3 Max FM". The Guardian Nigeria (online). Archived from the original on 5 July 2018. https://web.archive.org/web/20180705150713/https://guardian.ng/features/tvc-communications-launches-102-3-max-fm/amp/. Retrieved 5 July 2018.
- ↑ Webdesk (8 August 2017). "TVC OAP Honeypot and Ruggedman host City People music awards". TVC online. https://www.tvcontinental.tv/2017/08/tvc-oap-honeypot-ruggedman-host-city-people-music-awards/. Retrieved 5 July 2018.
- ↑ City People (14 August 2017). "Music Stars Storm 2017 City People Music Awards Details of the Colourful Event in Lagos". City people online. http://www.citypeopleonline.com/music-stars-storm-2017-city-people-music-awards-details-colourful-event-lagos/. Retrieved 5 July 2018.
- ↑ Webdesk (26 July 2016). "TVC rejoices with her presenter ‘HoneyPot’ as she bags award from City People". TVC online. https://www.tvcontinental.tv/2016/07/tvc-rejoices-presenter-honeypot-bags-award-city-people/. Retrieved 5 July 2018.