Olusegun Mimiko
Olusegun Mimiko jẹ olósèlú ọmọ ilẹ̀ Nàíjíríà àti Gómìnà Ìpínlẹ̀ Òǹdó láti ọdún 2009 dé ọdún 2017. Ọjọ́ kẹ́ta oṣù Ọ̀wàwà ní wọ́n bí Olúṣẹ́gun Rahman Mimiko ọdún 1954. Ó jẹ́ olùdíje fún ipò sẹ́nẹ́tọ̀ ní agbègbè àárín gbìngbùn Òǹdó lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Zenith Labour Party nínú ìdìbò tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Òǹdó.[1]
Olusegun Rahman Mimiko | |
---|---|
Gomina Ipinle Ondo | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga 24 February 2009 | |
Asíwájú | Olusegun Agagu |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 3 Oṣù Kẹ̀wá 1954 |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | Labour Party |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Olukemi Mimiko |
Occupation | physician |
Olúṣẹ́gun ní gómìnà alágbádá ẹlẹ́ẹ̀karùn-ún ní ìpínlẹ̀ Òǹdó, ní orílẹ̀-èdè Nàíjíríà láti 2009 sí 1017. Mimiko ti fi ìgbà kan jẹ́ mínísítà ìjọba àpapọ̀ fún ilé àti ìdàgbàsókè ìgbèríko, sẹ́kétírì sí ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo, bẹ́ẹ̀ náà ni ó jẹ́ gómìnà àkọ́kọ́ tí ó jẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour party ní orílẹ̀-èdè Nàíjírià. Bákannáà ni ó jẹ komíṣọ́nà léèmejì fún ètò ìlera.
Ìlú Ondo ní ìpínlẹ̀ Ondo, apá Ìwọ̀-oòrù̀n gúsù orílẹ̀-èdè Nigeria. Àti kékeré ni ó ti nífẹ̀ẹ́ si òṣèlú, èyí sì farahàn nínú àwọn ipò tí ó dì mú nìgbà tí oh wà ní ilé-ìwé àwọn oníṣègùn òyìnbó ní University of Ife (tó di Obafemi Awolowo University lónìí).
Lẹ́yìn ìgbà tí ó parí agùnbánirọ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ oníṣègùn òyìnbó. Ní ọdún 1985, ó dá ilé-iṣẹ́ MONA MEDICLINIC sílẹ̀ ní Ondo èyí ti ó dúró gẹ́gẹ́ bí ohun ètò ọ̀fẹ́ fún àgbègbè náà.[2]
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Itokasi
àtúnṣe- ↑ "Mimiko Pulls out of Presidential Race for Senate" (in en-US). ThisDay. https://www.thisdaylive.com/index.php/2018/11/15/mimiko-pulls-out-of-presidential-race-for-senate/.
- ↑ Olu, Obafemi. Mimiko‘s Odyssey, A Biography of Revelations, 2017. Print.