Olúṣọlá Momoh jẹ́ adarí àwọn ilé íròyìn kan ní Nàìjíríà.[1] Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùdásílẹ̀ àti Igbákejì Alága ti Àwọn Channels Media Group, ilé-iṣẹ́ tí ó ń darí Channels TV. Momoh gboyè B.Sc ní Mass Communicatio láti Yunifásitì ìlú Èkó. Ó tún gba àmì ẹyẹ pí polongo ìròyìn ní Yunifásitì ìlú Èkó.[2]

Olusola Momoh
Orílẹ̀-èdèNigerian
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigerian
Ẹ̀kọ́University of Lagos, Harvard Business School
Iṣẹ́Media executive, Journalist
Ìgbà iṣẹ́42 Years
OrganizationChannels Television
Olólùfẹ́John Momoh
Àwọn ọmọThree

Ní ọdún 2014, Ó wà lára àwọn women leadership forum program ti ilé-ìwé ìsòwò Harvard.[3]

Iṣẹ́-ṣíṣe

àtúnṣe

Ṣáájú kí ó tó dá Channel Television àti Channels Media Group silẹ̀, Momoh jẹ́ oníròyìn pẹ̀lú Nigeria Television Authority(NTA), láàrin ọdún 1979 sí 1987. Ní àkókò yìí, ó ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgbéjáde lórí bí Nàìjíríà ṣe ń sọ epo nù.[4]

Yàtò sí isẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi akàròyìn, Momoh ṣiṣẹ́ fún ọdún méje ní àwọn ilé-ìfowópamọ́. Ó ṣiṣẹ́ ní International Merchant Bank (IMB).[5]

Àwọn àmì ẹyẹ

àtúnṣe

Ní ọdún 2019, Momoh gbà Àmì-ẹ̀yẹ Doctorate degree nínú ìṣàkóso ìṣòwò ní Yunifásitì Achievers, ọ̀wọ̀, Ìpínlẹ̀ Oǹdó.[6] Ní Oṣù Kọkànlá ọdún 2021, àjọ Women in Management, Business and Public Service (WIMBIZ) ká mọ́ ọkàn lára àwọn obìnrin tí ó lókìkí jù. Àjọ náà tún ká mọ́ ọkàn nínú àwọn obìnrin tí ó lókìkí jù nínú àwọn oníròyìn obìnrin ní Nàìjíríà.[7]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Executive Vice-Chairman – Channels Television". Retrieved 2021-11-23. 
  2. Admin (2020-07-01). "MOMOH, Olusola". Biographical Legacy and Research Foundation (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-11-23. 
  3. "Executive Vice-Chairman – Channels Television". Retrieved 2021-11-23. 
  4. "Mrs. Olusola Momoh". The Aart of Life Foundation (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-11-23. 
  5. "Biography of Olusola Momoh, Vice-Chairman, Channels Television.". biography.hi7.co. Retrieved 2021-11-23. 
  6. "Ijeoma Nwogwugwu, Stella Din, Kadaria Ahmed named among 25 most powerful Nigerian female journalists". TheCable (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-10-02. Retrieved 2021-11-23. 
  7. "Ijeoma Nwogwugwu, Stella Din, Kadaria Ahmed named among 25 most powerful Nigerian female journalists". TheCable (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-10-02. Retrieved 2021-11-23.