Ọba Olúwọlé ( tí ó kú lọ́dún 1841) jẹ́ ọba ìlú Èkó láti ọdún 1837 sí 1841. Bàbá rẹ̀ ni Ọba Adele.[1]

Olúwọlẹ̀
Èkó
1837 - 1841
Adele
Akitoye
Father Adele
Born Lagos
Died Ọdún 1841
Lagos
Burial Lagos
Religion Ifá

Ìjà orogún pẹ̀lú Kọsọ́kọ́

àtúnṣe

Ìbẹ̀rẹ̀ ìjà orogún Ọba Olúwọlé àti ọmọba Kòsọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ nípa dúdupò Ọba Èkó lẹ́yìn tí Ọba Àdèlé kú.[2] Nígbà tí Olúwọlé di Ọba, ó lé àbúrò Kọsọ́kọ́, Opo Olú kúrò ní ìlú Èkó, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé adífá dá a láre ẹsùn wíwà nínú ẹgbẹ́ àjẹ́ tí wọ́n fi kàn án.[3] Síwájú sí i, nígbà tí Kọsọ́kọ́ paná ogun Ewé Kókò,[4] Olúwọlé rán Balógun rẹ̀, Yesufu Badà níjà ogun láti lọ kó ìkógun tí Kòsọ́kọ́ kó lójú ogun.[5]

Ikú rẹ̀ láti ara àṣìta ìbọn-olóró

àtúnṣe

Olúwọlé kú lọ́dún 1841 nígbà tí sísán àrá fàá tí àgbá àdó-olóró l'áàfin Ọba fi dún gbàmù. Gbogbo ẹran ara Olúwọlé ló fọ́n túká káàkiri, débi pé ilẹ̀kẹ̀ oyè rẹ̀ ní kan ni wọ́n fi dá a mọ̀.[3]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Mann, Kristin (2007). Slavery and the Birth of an African City: Lagos, 1760-1900. Indiana University Press, 2007. p. 45. ISBN 9780253348845. 
  2. Fasinro, Hassan Adisa Babatunde. Political and cultural perspectives of Lagos. University of Michigan. p. 61. 
  3. 3.0 3.1 Mann, Kristin (2007-09-26). Slavery and the Birth of an African City: Lagos, 1760--1900. Indiana University Press, 2007. pp. 47–48. ISBN 9780253117083. 
  4. Smith, Robert (January 1979). The Lagos Consulate, 1851-1861. University of California Press, 1979. pp. 14–17. ISBN 9780520037465. 
  5. Yemitan, Oladipo. Madame Tinubu: Merchant and King-maker. University Press, 1987. p. 8.