Ifá
Ifá jẹ́ òrìṣà kan pàtàkì láàárín àwọn Yorùbá. Àwọn Yorùbá gbàgbọ́ wí pé Olódùmarè ló rán ifá wá láti òde ọ̀run latí wá fi ọgbọ́n rẹ̀ tún ilé ayé ṣe. Ọgbọ́n, ìmọ̀, àti òye tí olódùmarè fi fún ifá ló fún ifá ní ipò ńlá láàárín àwọn ìbọ ní ilẹ̀ Yorùbá. “A-kéré-finú-ṣọgbọ́n” ni oríkì ifá. Ifá sì jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnu Olódùmarè tí ó sì fi rán òjíṣẹ́ rẹ̀ Ọ̀rúnmìlà baba Àgbọnmìrègún.
Àwọn Odù mẹ́rindínlógún | ||||
---|---|---|---|---|
Name | 1 | 2 | 3 | 4 |
Ogbe | I | I | I | I |
Oyẹku | II | II | II | II |
Iwori | II | I | I | II |
Odi | I | II | II | I |
Irosun | I | I | II | II |
Iwọnrin | II | II | I | I |
Ọbara | I | II | II | II |
Ọkanran | II | II | II | I |
Ogunda | I | I | I | II |
Ọsa | II | I | I | I |
Ika | II | I | II | II |
Oturupọn | II | II | I | II |
Otura | I | II | I | I |
Irẹtẹ | I | I | II | I |
Ọsẹ | I | II | I | II |
Ofun | II | I | II | I |
Sixteen Principal Afa-du (Yeveh Vodou) | ||||
Name | 1 | 2 | 3 | 4 |
Gbe-Meji | I | I | I | I |
Yeku-Meji | II | II | II | II |
Woli-Meji | II | I | I | II |
Di-Meji | I | II | II | I |
Abla-Meji | I | II | II | II |
Akla-Meji | II | II | II | I |
Loso-Meji | I | I | II | II |
Wele-Meji | II | II | I | I |
Guda-Meji | I | I | I | II |
Sa-Meji | II | I | I | I |
Lete-Meji | I | I | II | I |
Tula-Meji | I | II | I | I |
Turukpe-Meji | II | II | I | II |
ka-Maji | II | I | II | II |
Ce-Meji | I | II | I | II |
Ose orogbe | II | I | II | I |
Fu-Meji | II | I | II | I |
Ìgbàgbọ́ Yorùbá ni wípé ní ìgbà kan rí, ifá gbé òde-ayé fún ìgbà pípẹ́ kí o tó padà lọ sí ọ̀rùn. Ní ìgbà tí ifá fi wà ní ilé ayé, ó gbé ilé-ifẹ̀ fún ìgbà péréte. Ṣùgbọ́n ní ìgbà tí ọ̀rúnmìlà fi wà láyé yìí náà, a tún máa lọ sí òde ọ̀run lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí olódùmarè bá pèé láti wá fi ọgbọ́n rẹ̀ bá òun tún òde-ọ̀rùn ṣe. Nítorí náà gbáyégbọ́run ni ifá ńṣe.
Ìtàn sọ fún wa wípé ọmọ mẹ́jọ ni ọ̀rúnmìlà bí nígbà tí ó wà láyé, nígbà tí ó di ọjọ́ kan ti ọ̀rúnmìlà ńṣe ọdún ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ yìí tíí ṣe àbíkẹ́hìn pátápátá bá ṣe àfójúdi sí ọ̀rúnmìlà, ni ọ̀rúnmìlà bá bínú fi ayé sílẹ̀ lọ sí òde ọrun. Ni ìfá bá relé olókun kòdé mọ́. Ó lẹ́ni tí ẹ bá rí, ẹ ṣá máa pè ní baba”. Ṣùgbọ́n ọ̀rúnmìlà fún àwọn ọmọ rẹ̀ méjẹ̀ẹ̀jọ náà ní ìkín mẹ́rìndínlógún ó ní bẹ́ ẹ délé bẹ́ẹ bá fówóó ní, ẹni tẹ̀ ẹ́ maa bi nù u.
ìkín ifá mẹ́rìndínlógún náà ni à ń lò lòníí láti bèèrè nǹkan lọ́wọ́ ifá.
Díẹ̀ lára àwọn ohun èlò Ifá dídá
àtúnṣeOríṣìíríṣìí ni àwọn ohun èlò tí àwọn babaláwo fì nkí ifá ifá ni àdáyẹ̀na
Ìkín
Ìkọ awọ́lẹ́ẹ̀gbẹ́=== ifá:=== Èyí jẹ́ mẹ́rìndínlógún. Àwọn mìíràn máa pè é ní èkùrọ́ ifá. Àwọn babaláwo máa ń sábàá lo ikin ifá tàbí èkùrọ́ ifá yìí nígbà tí wọ́n bá ń bọ ifá ní ọọ̀dẹ̀ẹ̀ wọn, wọ́n a sì lo ọ̀pẹ̀lẹ̀ fún ará òdé tí ó wá dá ifá lọ́dọ̀ọ wọn
Ọ̀pẹ̀lẹ̀:
àtúnṣeOhun èlò ifá-dídá míìran ni ọ̀pẹ̀lẹ̀, èyí ló wọ́pọ̀ jù fún ifá dídá ní ayé òde òní. Àwọn babalàwo máa ńsábàá lọ ọ̀pẹ̀lẹ̀ tí wọ́n bá fẹ́ dáfá fún ẹlòmíràn. Lára igi èso ọ̀pẹ̀lẹ̀ ni a ti ń mú ọ̀pẹ̀lẹ̀ ifá.
Ìrọ́kẹ́ Ifá:
àtúnṣeOhun èlò ifá dídà míìran ní ìrọ́kẹ́ tàbí ìrọ́fá èyí jé gbóńgbó kan báyìí tí a ńmú lu ọpọ́n ifá bí a bat í ńki ifà lọ. Àwọn olóyè ifá a máa fi ehín erin gbẹ́ ìrọ́kẹ́ẹ ti wọn.
Ọpọ́n Ifá:
àtúnṣeOhun èlò ifá dídá míìran ọpọ́n ifá, nínú ọpọ́n ifá ni a ní lati kó gbogbo ohun èlò ifá dídá tí a ti ká sílẹ̀ wọnyìí sí bá a bá ti ńdá ifá. Orísi ọpọ́n ifá ló wà ọpọ́n kékeré wà, ọpọ́n ńlá sì wà pẹ̀lú.
Owó Ẹyọ Àti Egungun:
àtúnṣeÀwọn babaláwo a máa ní owó ẹyọ àti egungun nínú ohun èlò ifá dídá wọn, owó ẹyọ dúró fún bẹ́ẹ̀ni, egungún sì dúró fún bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà tí a bá di ìbò béèrè nǹkan lọ́wọ́ ifá-owó-ẹyọ àti égúngún yìí tí a dì mọ́wọ́ ni à ń pè ni ìbò.
Àpò Jèrùgbé:
àtúnṣeÈyí àpò tí àwọn Babaláwo máa ń kó gbogbo ohun èlò ifa dídá tí mo kà wọ̀nyí sí. Àwọn Babaláwo a máa gbé àpò Jẹ̀rùgbá kọ́ èjìká tí wọ́n bá ń re òde ifá.
Ẹbọ Ifá Rírú
àtúnṣeẸbọ rírú se pàtàkì fún ẹni tí a bá dá ifá fún. bí ifá tí a dá fún ènìyàn bá se rere tàbí búbúru, oní tọ̀hùn ni lati rúbọ kí ohun tí ó dá ifá sí náà ó lè baà dará: lọ́nà kìní:- Ẹbọ ifá jẹ́ ounjẹ fún òrìṣà tí ifá bá so wí pé kí á rúbọ, Fun àpẹẹrẹ, tí ènìyàn bá fẹ́ se nǹkan. ti o ba bèrè lọ́wọ́ ifá, wọ́n le sọ pé ki o lọ rubọ fun ògun, Ẹbọ ifá jẹ́ ètùtù pàtàkì nítorí tí Babaláwo bání kí ènìyàn se nǹkan óní láti se é, ki òun pàápàá ólè ba à ni ìgboyà wípé àteégún-àteésà, nítori èyí ní àwọn babaláwo fi máa ńwí fún ẹní tí a ní kí ó rúbọ̣ pé kí ó wá oúnjẹ fún àwọn aládùgbóó rẹ.
Èṣù àti Ifá
àtúnṣeBí a bá wọ ilé àwọn babaláwo, a ó ri i wí pé ère Èsù kìí wọ́n nibẹ̀. Yangí ńlá kan o máa wà ní ẹ̀bá ilé àwọn babalawo. Yangí yìí dúró fún àmì Ẹ̀sù. Ìgbà gbogbo ni àwọn babaláwo máa gbé ẹbọọ lọ si ibẹ́, nwọn a máa bu epo lé yangí náà lórí, a máa rin sún nígbà gbogbo.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ẹsẹ ifá tí o jẹ mọ Ẹ̀sù. Nígbà míìran, Èṣú jẹ́ ìrán ńṣé fún ifá. Nígbà miran ẹ̀wẹ̀, Èsú sí dá bí ẹni tí ńfún ifá ni agbára. Nínú ẹsẹ ifá a lè rí ohun tí o jọ bayin “…ni ọ̀rúnmìlà ba ti àṣẹ Èṣù bọnu”. ìtumọ̀ èyí ni wí pé bí ifá bá fẹ́ẹ́ ṣe nǹkan lile ti ó rí bí idan, àṣẹ Èṣù ló ní láti lò. Nígbà mìíràn, Èṣù jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ifá. Nígbà mìíràn, Èṣù sì jẹ́ olùdánwò fún ifá.
Oríkì Èṣù tí ó wà nísàlẹ̀ yí ti fi hàn wà gba-n-gba pé Èṣù kì ba ẹnìkan sọ̀rẹ́
Oríkì Èṣù nìyí: “Òkú yan ọmọ tié lódì átóńtórí ọmọ ọlọmọ”.
Ipò Ifá láàrín òrìṣà tókù
àtúnṣeIfá jẹ́ agbọ̀ràndun fún gbogbo àwọn òrìṣà yókù. Bí eégún ilée baba ẹni ba fẹ́ẹ́ bínú sí ni, láti ọdọ ifá ni a ó ti gbọ̀ èyí wáá fún ifá ni ipo asojú fún gbogbo àwọn irúnmọlẹ̀ yókù. Bí kò bá sí ifá, iyì àti ọlá ti àwọn Yorùbá mbú fun gbogbo àwọn òrìṣà ilẹ̀ẹ Yorùbá ró, tí ó sì ǹwà ońjẹ sí wọn lẹ́nu.
Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ síwájú, àwọn ọmọ òrúnmìlà ni ọ̀rúnmìlà fún ní ikin ifá mẹ́rìndínlógún nígbà tí ó padà lọ si ọ̀run tí ló sí wa sílé ayé mọ́.
Nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ ìkín, a kò ni se aláìmẹ́nuba àwọn ojú odù merẹẹrindínlógún nítori ìkín mẹ́rìndínlógún náà ni à ń lò lónìí láti bèèrè nǹkan lọwọ ifá. Àwọn ojú odù mẹ́rìndínlógún àti bí wọ́n ṣe to tẹ̀le ara wọn:
(1) Èjì Ògbè
Èjì ògbè Ẹsè kínní
“sGbogbo orí àfín ewú
Abuké ló rẹrú òòsà mọ́sọ̀
Lààlààgbàjà ló ti isé ẹ̀ de
Adíá fún ọ̀rúnmìlà
Níjó ti ńlọ rẹ̀mí ọmọ olódùmarè sóbìnrin Ẹsẹ̀ kejì.
Eri ńlá níí sunkún ibú
Agbara giri nii sunkun ọ̀gbun
Adíá fun Aadelọ́wo nífẹ̀
Nwọ́n ní ó ká a kío mọ́lẹ
(2) _ọ̀yẹ̀kú méjì,
(3) Ìwòrí méjì,
(4) Òdí méjì,
(5) Ìrosùn méjì,
(6) Ọwọ́nrin méjì
(7) Ọbara méjì,
(8) Ọ̀kànrùn méjì,
(9) Ògúndá méjì,
(10) Ìká méjì,
(11) Ótúúrúopọn méjì,
(12) Òtúá méjì
(13) Òsá méjì,
(14) Ìrẹtẹ̀ méjì
(15) Ọ̀sẹ́ méjì,
(16) Ofún méjì,
Àwọn ọmọ odù Ifá
àtúnṣeLẹ́yìn àwọn ojú odù mẹ́ríndinlógún yìí, àwọn òjìlérúgba odù míràn tún wà tí à ń pè ni ọmọ odù tàbí àmúlù odù wọ́n jẹ́ ọmọ odù nitorí pé a gbà pé wọn se ọmọdé si àwọn ojú odù, à ń pè wọ́n ni Àmúlù odù nítorí pé orúkọ odù méjì ni ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n jẹ́. F.A., èkíni nínú àwọn odù wọ̀nyìí a máa jẹ ogbeyẹ̀kú.
Àwọn Yoruba ka àwọn odu wọ̀nyú si òòsà pàtàkì jùlọ, àwọn ojù odú. F.A. Ẹsẹ-ifa òwònrín méjì
(a) Ikin níi fagbáríí selé
Àtàrí ni o jóòrún ó pagbin ìsàlẹ̀
Ọlọbọnhunbọnhun ni fapa ara rẹ dá gbẹ̀dú.
Níní
ṣàà
à
sa Yoruba Ifá A ti rí i ni ojú ewé 46 Apa Kini ìwe yi irú ipò pataki ti Orìṣà-nla tabi Ọbàtálá kó laarin awọn òrìṣà ati irúnmalẹ̀ ilẹ Yoruba. A ti gbọ́ pẹlu pe jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ Yorùbá ni nwọn maa mbọ́ ọ́, nitoripe oun ni awọn àgbà àtijọ́ gbà ninu ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn pe o jẹ igbákejì Olódùmarè, ti o si nràn an lọ́wọ́ lati tún enia dá nipa fífún un ni ojú, imú, eti, ati gbogbo ẹ̀yà ara miran ti o yẹ ki ẹ̀dá ní ki o fi lè di enia pipe. ...
Àwon nnkan pàtàkì tí Ifá máa ń dá lé lórí
àtúnṣe- [1]Ọ̀rọ̀ nípa orì,ẹ̀sẹ́ àti àyà
- Ìwà
- Ìtàn àwọn òrìṣà
- Àwọn Ajogun àti àwọn Ẹlẹyẹ
- Ẹbọ
- Ire àti
- Àkíyèsí nípa ẹ̀dá
- ìbáṣepọ́ láàárín ọkọ àti aya
- ọ̀rẹ́ sí ọ̀rẹ́
- àìrọ́mọ bí
Iwe fun kika
àtúnṣe- J. F. Odunjo (1969), Eko Ijinle Yoruba, Alawiye Fun Awon Ile Eko Giga, Apa Keji, Longmans of Nigeria, Ojú-ìwé 78-87.
- E. A Lijadu (1895) Ifa Mimo Alabalase United Star printers Ltd.
- P.O. Ògúnbòwálé (1980) Àwon Irúnmalè Ilè Yorùbá Evans Brothers (Nigeria Publishers) Limited. ISBN 978-167-090-8.
- Débò Awé (2006) Àkóyawó Àlàyé Àti Ìbéèrè lórí Àwọn Ojú Odù Ifá Elyon Publishers Iléṣá. ISBN 978-2148-25-3.
ORIN IFA: ti o je mo orisa Orunmila ni iyere. Awon babalawo lo maa n sun iyere. Ko si igba ti a ko le sun iyere. Bose wa fun etutu lo wa fun ayeye. Enikan ko le da iyere ifa sun nitori o ni egbe. Apeere lati inu odu ifa ìwòrì meji niyi:
È le: E e riwoo ya a, omo agbonniregun Ègbè: Ha in/hen-en Ale: Eni a ba wade, las ba deleted eni aja ba wa Laja n ba lo Ègbè: ha in Egbele je hain tabi hen-en Ale: IFA teju mo Mi O womi ire Ejiwori Oju to fin so Mi Mama fi sun ooo Ègbè: hain....
- ↑ ISBN9780309063