Omi Ọ́mú

(Àtúnjúwe láti Omi Omú)

Omi Omú(tí àwon ènìyàn tún mò sí "Omi Oyàn") jẹ́ omi tí ó ma ń jáde nínú omú aláboyún tàbí ìyá tí ó ń fún ọmọ lọ́yàn. Omi omú jẹ́ orísun okun gbòógì fún ọmọ titun, ó sì ní gbogbo èròjà tí omo nílò láti dàgbà, àwọn èròjà bi omi, carbohydrate, aramuaradagba àti òrá.[1]

Àfiwé ọmọ tí ó ń mu ọmú ìyá rẹ̀

Omi ọmú sì tún ní àwọn eroja tó ma ń bàrùn jà nínú ara, omi omú ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ànfàní fún ọmọdé, Aájọ Ètò Ìlera Àgbáyé sí ti pàrọwà fún àwọn ìyá láti fún ọmọ wọn ní omi ọmú nìkan fún osù mefa àkọ́kọ́ ayé wọn láì fun ní ounje mirán,[2] wọ́n sì tún pàrọwà pé láti fún ọmọ ní omi omú fún pẹ̀lú oúnjẹ miran fún ó kéré jù, odún méjì.

Ànfàní omi ọmú

àtúnṣe

Fífún ọmọ lọ́yàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ànfàní fún ọmọ àti ìyá.[3] Díẹ̀ nínú àwọn ànfàní yìí ni pé ó mú kí ọpọlọ ọmọ sí,[4] ó sì ma ń ran ara ọmọdé lọ́wọ́ láti dojú kọ àrùn bí àrùn etí,[5] òfìkìn àti flu[6]

Fífún ọmọ lọ́yàn tún ní àwọn ànfàní fún ìyá ọmọ, ó ma ń jẹ́ kí ilé ọmọ ìyá padà sí bí ó ti rí tẹ́lẹ̀ kí ó tó lóyún, ìwádìí sì ti fi hàn pé àwọn ìyá tí ó ń fún ọmọ lọ́yàn kìí sábà ní àwọn àrùn Diabetics tàbí àrùn Breast Cancer bí àwọn tí kò fún ọmọ lọ́yàn.

Àwon Ìtókasí

àtúnṣe
  1. "Breast Milk Composition Over Time: What's in it and How Does it Change?". Family & Co. Nutrition. 2021-05-03. Archived from the original on 2023-08-13. Retrieved 2023-08-05. 
  2. Breastfeeding..., the Global (2019-11-11). "Breastfeeding". World Health Organization (WHO). Retrieved 2023-08-05. 
  3. "The World Health Organization's infant feeding recommendation". Archived from the original on January 8, 2012.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. "Breastfeeding Associated With Increased Intelligence, Study Suggests". Archived from the original on 2021-01-15. Retrieved 2018-02-28.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. "Recurrent middle-ear infections in infants: the protective role of maternal breast feeding". Ear, Nose, & Throat Journal 62 (6): 297–304. June 1983. PMID 6409579. 
  6. "Prevention of mother-to-infant transmission of influenza during the postpartum period". American Journal of Perinatology 30 (3): 233–40. March 2013. doi:10.1055/s-0032-1323585. PMID 22926635.