Omotosho Olakunle Rasaq
Omotosho Olakunle Rasaq jẹ́ olóṣèlú ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí ó ń ṣàmójútó agbègbè Isin, ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Isin, ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ilẹ̀ Kwara.[1]
Omotosho Olakunle Rasaq | |
---|---|
Member of the Kwara State House of Assembly | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga 18 March 2023 | |
Member of the Kwara State House of Assembly from Isin Local Government | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga 18 March 2023 | |
Constituency | Oke-onigbin |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 3 Oṣù Kàrún 1973 Agbonda,Irepodun Local Government Kwara State Nigeria |
Ọmọorílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | All Progressive Congress |
Alma mater | |
Occupation |
|
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Rasaq ní ọjọ́ karùn-ún oṣù Kẹta ọdún 1973 ní Oke-Onigbin, ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Isin, ní Ìpínlẹ̀ Kwara, Nàìjíríà. Ó lọ sí ilé-ìwé Oke-Onigbin Community primary school àti Oke-Onigbin Secondary School láàárín ọdún 1986-1995. Ó gba oyè National Diploma (Nigeria) àti ìwẹ́-ẹ̀rí Higher National Diploma láti Kwara State Polytechnic ní ọdún 1998 àti 2003 bákan náà.
Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeRasaq jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ètò Ìṣirò owó àti Olùdásílè Àgbà ti ilé-iṣẹ́ Bellumin Int’l àti Oko Omo Aro kí ó tó wọ iṣẹ́ Òṣèlú, nígbà tí ó díje dupò kan lábẹ́ àsíà Accord Party ní ọdún 2007 kí ó tó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ olóṣèlú All Progressive Congress láti díje dupò ní ọdún 2023 tí ó sì wọlé gẹ́gẹ́ bí i ọ̀kan lára àwọn Ọmọ-ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ aṣòfin ẹlẹ́ẹ̀kẹwàá ti ìpínlẹ̀ Kwara.
Awọn itọkasi
àtúnṣe- ↑ "HON. OMOTOSHO OLAKUNLE RASAQ". Kwara State House of Assembly (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-12-03.