Razak Akanni Okoya
Ọjọ́ìbí12 Oṣù Kínní 1940 (1940-01-12) (ọmọ ọdún 84)
Lagos, Nigeria[1]
Ibùgbé"Oluwa ni Shola" Estate, Ajah, Lagos, Nigeria
Iṣẹ́Billionaire industrialist, chairman of the Eleganza Group and the RAO Property Investment Company[1]
Olólùfẹ́
Àwọn ọmọ
  • Subomi Okoya
  • Wahab Okoya[3]
  • Olamide Okoya
  • Oyinlola Okoya[2]
Parent(s)
  • Idiatu Okoya
  • Tiamiyu Ayinde Okoya

[1][4]

Àwọn olùbátanWosilat Okoya (sister)[2]
Websiteeleganzagroups.com

Oloye  Razak Akanni Okoya je omo Ipinle Eko ti won bi ni  (12 January 1940). O je olowo billionaire to nile ise repete ti o si tun je  Aare gbogbo ipinle Eko.[5] O lo sile eko alakobere  Ansar-un-deen Primary, Oke popo, nilu Eko. Oun ni o ni ile ise ati oludasile ile ise  akojopo Eleganza , ti o ti taja kaakiri iwo oorun Adulaw.

Ibere aye re

àtúnṣe

Razak Okoya je omo Yoruba lati apa ariwa iwo Oorun Ile Naijiria. Won bi sidile ogbeni Tiamiyu Ayinde Okoya ni ipinle Eko, ti o je olu fun orile ede Naijiria tele. O n sise ni labe baba re to je aranso  ti o si tun n ta nkan elo ero aranso gbogbo.[6] Imo ti o ti ni nibi ise yii fun ni igboya lati beere ise aranso tire naa. O ma n toju owo titi o fi pe ogun poun (20 pounds). Iya re naa si tun raan lowo pelu aadota poun (50 pounds),[7]  ti o si bere si ni ko awon oja wole lati ilu okere Japan.

Ise okowo re

àtúnṣe

Okowo Razak Okoya gbooro kia kia, o si bere si ni serin ajo kaakiri orile agbaye ti o si n ko ogbon lorisi risi bi won se n se orisirisi nkan pelu igbagbo wipe orile ede Naijiria yoo le pese awon nkan wonyi dara dara .

Iyawo re akoko, Kuburat Okoya, ni opolopo ohun oso ara ti o si ma n ya Razak lenu ti o ba so iye ti okookan won je. O pinu wipe iye owo awon oso ara naa poju nigba ti o je pe owo irin ko tonkan ti won fi n se won ko tonkan ni Naijiria. Lati le mo okodoro, o gbera lo si oke okun lati lo ra awon ero ti won fi n se awon nkan wonyii, ni eyi o fi bere ile ise Eleganza Jewelry. Aseyori ise yi gbooro debi wipe apa ile ise naa ko ka ibeere awon onibara won nitori awon ohun oso naa dara,won rewa, won lalope owo pooku si ni won.Bi o se di gbajugbaja ninu ise ipese ohun oso niyi.

Laipe, o tun bere lati kiko bata wo orile ede Naijiria ni yanturu, ni eyi ti o je pe awon bata naa ki saba tete de . O lo si ile Itili lati lo ri olupese bata naa, ti o si ri wipe won ti lo owo oun si ona miran. O binu, o si bere si n pese bata tire naa. O ra awon ero (machines) ti o lagbara lati se ise naa latilu okere ti o si gba awon akose-mose ti o ke awon osise re nimo naa.

Loni, labe akoso re, ile ise  Eleganza  n pese orisirisi ohun elo ile bi: Sibi, abo igbonje pamo (food warmers), ice chest, electric fan, cosmetics and ballpoint pen. Ibi ti awon ile ise re ni: Oregun-Ikeja, Isolo, Alaba and Iganmu. Ile ise naa ti o le ni egberun lona Aadota osise ti won je omo ile Naijiria ati  awon omo ile okere ti won n sise ni RAO. Lara awon ile ise to tobi ju ni orile ede Naijiria ni Eleganza Group wa ni aarin awon akegbe re, ti o le ni ile ise mefa ti o wa labe akoso Eleganza ti o si tun ni je okan laarin awon ile ise ti oruko re han si awon orile ede to sun mo Naijiria gbogbo..

Won fun ni oye  "Business Entrepreneur of Our Time" lati ile ise iwe iroyin Thisday Newspapers.[8]

Oun lo ni ile igbe akojopo (estate) kan ti o n je "Oluwa ni shola" (The Lord creates wealth) ti o wa ni titi marose Lekki/Ajah. Ibe  si ni ibugbe re . Ile akojopo "Oluwa ni shola", ni won tun n dape ni ile awon ara oke okun (expatriates) nitori awon ohun amaye derun to  wa nibe. Gege bi Bellanaija se so, o ni "Inu ogba Oloye Razak Okoya ni won ti ya aworan orin [Suddenly] iyen 'Oluwa Ni shola' Estate.[9]

Awon oro ojogbon

àtúnṣe

"O rorun fun mi lati fara mo ise okowo eyi to wumi nigba ti mo ba ri awon oluko mi ninu aso to ti gbo ati onisowo opopona Dosumu ti o je oju oja lEko nigba naa ti o mura gidi."mi

" Mi o ki n wo aago alaago sise. Mo ma n nitelorun pelu ohun ti mo ba ni. Mi o ki n wa ofe. Mi o ki n wa ise kongila bee si ni mi o ki n je ki iselu o wo mi lori."

"A ma n sowo nitori ohun ti awon eniyan ba re ra ni kii se nitori wipe o ni owo. Ninu okowo re, o gbodo ri wipe awon eniyan le ra ohun ti o ba fe ta fun won. Eyi je okan ninu awon asiri mi,"

"Ohun to wu mi lori ju ni wipe mo fe lola, mo si mo pe mo ti sise gidigid lati depo ola."

"N ko ni leboleru si iwe kika. Sugbon nigba miran, iwe kika ma n fun awon eniyan ni igboya ofo. O ma n je ki eniyan sinmi le iwe eri won dipo ki won sise kara kara."

Awon omo re

àtúnṣe

Oloye Razak Okoya ni awon omo to po, sugbon eyi ti o gbajumo ju ninu awon omo re ni Sade okoya Olamide,Subomi,Oyinlola,Wahab. OLamide ni tire lo ti pe ninu iwe kiko ti o si saba ma n sefe. Olamide ti o je obinrin ni won bi ni ayajo ojo ibi baba re Okoya. Subomi Okoya ni o feran ere idaraya nile eko re. Oyinlola naa je okan to feran igbafe pelu awon eniyan. Wahab Okoya ni o kere julo ti o si feran oge.

Iyawo re

àtúnṣe

Razak Okoya je oniyawo pupo tele, sugbon iyawo re to wa loju opon ni oruko re n je Folasade Okoya ti o so wipe o looto ti o si je akinkanju. Folasade lo bi : 'Olamide, Oyinlola, Subomi ati Wahab'. nSade naa ti gba orisirisi ami eye gege bi eni to mo ara mu julo ati esin iwaju fun awon ero eyin.

Awon itoka si

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 1.2 Lanre-Aremu, Kemi (19 January 2014). "I like to be stylish". Punch. Archived from the original on 28 March 2014. https://web.archive.org/web/20140328210349/http://www.punchng.com/spice/personalities/i-like-to-be-stylish-razaq-okoya/. Retrieved 28 March 2014. 
  2. 2.0 2.1 2.2 "From Ghetto To Wealth: The Story Of Sade Okoya – How She took over Okoya’s household". Global News. http://www.globalnewsnig.com/from-ghetto-to-wealth-the-story-of-sade-okoya-how-she-took-over-okoyas-household/. Retrieved 28 March 2014. 
  3. "We were brought up to see realities of life — Okoya, Director, Fico Solutions". Nigerian Best Forum. Retrieved 28 March 2014. 
  4. "Razaq Okoya – Eleganza Group". Financial Freedom Inspiration. Archived from the original on 28 March 2014. 
  5. Lanre-Aremu, Kemi (16 March 2014). "Between Dupe Oguntade and Shade Okoya". Punch. Archived from the original on 24 March 2014. https://web.archive.org/web/20140324143216/http://www.punchng.com/spice/society/between-dupe-oguntade-and-shade-okoya/. Retrieved 28 March 2014. 
  6. Sotunde, Oluwabusayo. "Portrait of a Mercurial Industrialist: Rasaq Akanni Okoya". Ventures Africa. Retrieved 28 March 2014. 
  7. Olaode, Funke (12 January 2008). "Nigeria: My Mother Started Me Off in Business – Rasaq Akanni Okoya". This Day. http://allafrica.com/stories/200801140577.html. Retrieved 28 March 2014. 
  8. "When Teachers Got Their Rewards on Earth". This Day. 3 March 2013. Archived from the original on 24 March 2014. https://web.archive.org/web/20140324143609/http://www.thisdaylive.com/articles/thisday-awards-when-teachers-got-their-rewards-on-earth/141078/. Retrieved 28 March 2014. 
  9. "New Video: D’Banj tells the story of ‘Suddenly’". Bellanaija. Retrieved 11 October 2013. 

[[Ẹ̀ka:Àwọn ojọ́ìbí ní 1940]] [[Ẹ̀ka:Àwọn ènìyàn alààyè]] [[Ẹ̀ka:Àwọn oníṣòwò ará Nàìjíríà]]