Ìdíje French Open(Ṣíṣí Faransé) (Faransé: Internationaux de France de Tennis), tí a tún mọ̀ sí Roland-Garros (Faransé: [ʁɔlɑ̃ ɡaʁos]), jẹ́ gbajúgbajà ìdíje bọ́ọ̀lù Orí pápá Alámọ̀ tennis tournament tí ó máa ń wáyé láàárín ọ̀sẹ̀ méjì ní pápá ìṣeré Stade Roland-Garros Ní ìpínlẹ̀ Paris, ní orílẹ̀-èdè Faransé, ní òpin oṣù karùn-ún ọdọọdún. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdíje náà máa ń wáyé gẹ́gẹ́ bí àlàkalẹ̀ láàrin oṣù karùn-ún sí oṣù kẹfà, àwọn ìgbà kan wà tí kò wáyé ní ìgbà náà fún àwọn ìdí bí í:

  • Àwọn ìdíje ọdún 1946 àti ọdún 1947 wáyé ní oṣù keje lẹyìn ìdíje Wimbledon àti ràlẹ̀rálẹ̀ ohun àgbáyé keta aftermath of World War II;
  • Ti ọdún 2020 wáyé ní òpin oṣù kesàn-án leyin ìdíje US Open nítorí àrùn COVID-19 pandemic;
  • Ti ọdún 2021 yìí náà jẹ́ sísún síwájú nítorí àrùn yìí bákan náà fún bí ọ̀sẹ̀ kan.
Pápá iṣeré Roland Garros, ní ọdún 2007.

Ìdíje yìí àti pápá ìṣeré rẹ̀ ni wọ́n fi sọrí Roland Garros tí ó jẹ́ onímọ̀ nípa ọkọ̀ òfurufú. Ìdíje French Open jẹ́ gbóògì láàrin àwọn ìdíje orí pápá Alámọ̀ lágbàáyé. Òun ni ó ṣe ipò Kejì nínú mẹ́rin tí ó jẹ́ pàtàkì bíi irú rẹ̀. Àwọn mẹ́ta yòókù ni ìdíje Australian Open, Wimbledon, atì Ìdíje US Open. Ìdíje French Open nìkan ni ìdíje pàtàkì tí wọ́n ń ṣe ni orí Amọ̀. Títí di ọdún 1975, ìdíje yìí nìkan ni wọn ò tíì ma gbá ní Orí pápá oníkoríko. Nínú àláálẹ̀ méjèèje tí wọ́n fi ń mọ ìdíje tí ó yanrantí, ìdíje French Open yìí ni wón lérò pé ó gba agbára jùlọ.

Itokasi àtúnṣe