Orúkọ Àdúgbò ní Òndó, Ìpínlẹ̀ Òndó, Nàìjíríà
ÒNDÓ
àtúnṣe- Àdúgbò:Òkòòtúnba
Ìtumọ̀:Ibi ti olóyè Ọ̀túnba kọ́ ilé sí tí ó n gbé ni à n pè ní òkè ọ̀túnba
- Àdúgbò:Òkè-Àyàdié
Ìtumọ̀: Ibi ti àwọn òyìnbó tó mú èsìn ìgbàgḅó wá, ilé ibi tí wón ń gbé tí ó wà lórú òkè tú wọ́n ń pè ni yádì ni àwọn so di òke àyàdí tí àdúgbò náà ń jé dòní.
- Àdúgbò:Odòjọ̀mù
Ìtumọ̀:Ìsàlè òndó tí olóyè Ọjọmù kọ́lé sí ni wọn ń pè ni Odòjọ̀mù.
- Àdúgbò:Òdòlúà
Ìtumọ̀: Òrìsà kan tí wọ́n ń pè ní odòlúà ní ó tè àdúgbò yí dò, Ibìtí o wọlẹ̀ si ni à ń pè ni odòlúà.
- Àdúgbò:Òkèlísà
Ìtumọ̀: Òkè ibi ti ó kọ́lé sí tí ó ń gbé ti peka sí tí wọ́n ń pè ni íÒkèlísà. Lísà ni o wa ní àdúgbò ti a ń pè ni Òkèlísà.
- Àdúgbò:Ìdímògé
Ìtumọ̀:Ìdi igi kan ti ẹyẹ oge máa ń pọ̀sí ni wọ́n sọ di Ìdímògé ní ìlú Òndó.
- Àdúgbò:Ìdí Isin
Ìtumọ̀: Igi kan wa ti wọ́n ń pè ní igi sin. Abẹ́ igi yíì fẹjú, ó tutu, ó sì gbòòrò tó bẹ́ẹ̀ tí o lè gba èèyàn púpọ̀ láti seré bíì ìjàkadì ayò ọpọ́n abbl. Béì tití ni àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí kọ́lé sí àyíká igi yi ti ó wá di ibi tí à ń pè ni idi isin di òní.
- Àdúgbò:Òkèròwò
Ìtumọ̀: ni àdúgbò ti àwọn onísòwò tí ó jẹ́ ìsòbò pọ̀ si wọn a sì máa se kárà kátà wọn ní àdúgbò náà idi nìyí tí Òndó ń fi ń pe àdúgbò náà ni Òkè ìsòwò ni wọ́n igbati ó jẹ́ wí pé òkè ni ó wà. Òkè ìsòwò yíì ni àwọn ìsòbò yíì se àsìse ni pípé rè tí wọ́n fi ń pè ní òkè ìròwò ti ó di òkèrówó títí di òní.
- Àdúgbò:Ògbònkowò
Ìtumọ̀:Ó jẹ́ ibi ti Ògbóni ti bẹ̀rẹ̀ ti wọn n ko ìlédi wọn si, ti wọn bà si ń lọ wọn a mú Ogbó dani gẹ́gẹ́ bí àmìn ẹgbẹ́ wọn. Wọn á ma so wí pé à kìí wòó Àdúgbò yí ni wọn sọ di Ogbo-ti-a-kii-wò tì ò fi di Ògbònkowo lónìí
- Àdúgbò:Odòtù
Ìtumọ̀: Ọjọ́ ti Òndó ìbá dàrú tí Òndó ìbá túká nítorí awo nlá kan to sẹlẹ̀, ojú ibi tí wọn joko si pètù sọ́rọ̀ òhún.
- Àdúgbò:Òkà
Ìtumọ̀: ìdí tí wọ́n fi ń pè wọ́n ni ọ̀kà ni pé àwọn ará Ọ̀kà Àkókó lo fi agbègbè yí se ibùgbé. Àwọn ará òkà yii si ti pẹ̀ ni Òndó to bee je ti won ti gbo èdè Òndó yinrinyirin se téwé bá pe lára ose a dose ìdí nì yen tí won ń fi pé won ní òkà Ondo ti o doruko àdúgbò won ti a mo si oka
- Àdúgbò:Odò yègè
Ìtumọ̀: Ijoye nla kan lo nje yege, ibi to tedo di to n gbe bo si owo isale Òndó ìdí niyi ti won fi n pe won ni òdò yègè.
- Àdúgbò:Igele ale
Ìtumọ̀: Ojà ni won n pen i igele ni èdè Òndó. Tomodé tàgbà won ni o ma fi aro wọn lo oko ni agbèègbè ti a n soro bayii nigba ti o ba di owo, ale won a pate oja won si ita ile won, titi ti o fid i ojà ti won náà ni alale.
- Àdúgbò:Ìgbònkúta
Ìtumọ̀: Ó jé agbègbè ti okuta pos i agbegbe yin i àwon molé molé ti n ma wa ko okuta àwon ni o si so agbegbe naa di ibi-a-n-gbo-òkútà oun lo wa di ìgbònkúta lóní
- Àdúgbò:Ìtapín
Ìtumọ̀:Ibi tí Ondo ati Bágbè ti pinya ni a npe ni ìtapín
- Àdúgbò:Lósìnlá
Ìtumọ̀: lósìnlá-là gbalá ni àpètán lósùlá ibè ni won ti kókó ń se osùn tí won ńrà osìn, tí won ńtà osìn ní Ondo.
- Àdúgbò:Sùrúlérè
Ìtumọ̀: àwon òlàjú ti o kókó lo sí Èkó ti won tàjò dé ni won so agbegbe yin i sùrúlérè nigba ti won tàjò de lati ma fí rántí agbègbè tí won gbé ni Èkó
- Àdúgbò:Yaba
Ìtumọ̀: Àwon òlàjú ti o koko lo sí Èkó ti won tajo dé ni won so agbègbè yin í Yaba nígbà tí won tàjò dé láti le ma fi rántí àgbègbè ti won gbé ní Èkó.
- Àdúgbò:Akínjàgunlà
Ìtumọ̀: O je akínkanjú okùnrin kan tí ó lòkíkí ti a wa fi orúko re so agbègbè tí ó ńgbé.
- Àdúgbò:Idim- Sòkòfí
Ìtumọ̀:Olóyè ló ń jé sokoti àdúgbò rè ni won wá so di idim-sòkòtí.
- Àdúgbò:Odòsídà
Ìtumọ̀:Jé ìtà oba tí won ti ń ma pa olè àti òdaràn idà ni a fi ń pa won ibi tí a n tójú idà náà sí ni Ìsídà níwòn ìgbà tí ó si jé pé apá ìsàlè Ondo ló bó sí ni a fi ń pè ní Odòsíndà.
- Àdúgbò:Òde-Ondó
Ìtumọ̀:Ibi tí àwon ará Ondó tí máa ń jo ibi tí ó téjú tí ó gba èrò púpò ni, ó sì bó sí àrín ìlú a sì ma ń se ìpàdé níbè náà pèlú agbègbè yíì ni won ń pè ní òde Ondó.
- Àdúgbò:Àdúgbò Obitun
Ìtumọ̀:Ibè ní agbèbbè tí a ma ńkò àwon omobìnrin tí kò tí mo Okunrin si fun Idabobo lowo isekuse ki won tó ní oko ní ayé àtijó agbègbè náà sì ni eré obìtun ti bèrè.
- Àdúgbò:Ìjòkà
Ìtumọ̀: O je agbègbè tí òkà ti ń pò ti àwon èèyàn ń rà tí won si ń tà. Ìdí nìyí ti won fi ń pè ní ibi-ìje-okà ti ó di ìjòkà lónìí.
- Àdúgbò:Tèmídire
Ìtumọ̀: O je àdúgbò ti èèyàn kan tédó ni pe bayìí ti o so àdúgbò náà ni orúko Tèmídire: Tèmi-di-ire.
- Àdúgbò:Odòmíkàn
Ìtumọ̀: Ó jé agbègbè tí babaláwo kan tí ó gbójú wa ni àtijó a sì máagbà èmí eniyan la pupo lowo iku. Igbàgbó sì ni wipe eni ti o bat i mikanlè lówó Iku lódò rè ko le rí ajínde mo idi niyi ti won fi ń pè ni odò-ìmí-kanlè tí àgékúrú rè wa di odòmíkàn.
- Àdúgbò:Odòlílí
Ìtumọ̀: Eni tó ní ilé ni a ń pè ni ‘nuli’ ni èdè Òndó. Agbègbè yi si wa je agbègbè ti àwon oní ilé ń gbé idi niyi ti won fi n pe ni odò-núlí ti ó wá di odòlÍlí
- Àdúgbò:Ajíférere
Ìtumọ̀: Orúko ìlagije akíkanjú kan ló ń jé béè. Agbègbè tí ó n gbe ni a fi orúko re so lati se aponle fún un.
- Àdúgbò:Lípàkálà
Ìtumọ̀: Baba kan wa ti o ni, irúfé, irúgbìn kan ti a mo si pakala ni ede Oǹdó.
- Àdúgbò:Òkègbàlà
Ìtumọ̀: Àgbègbè tí àwon elésìn Kiriyó ti máa se ìsìn won fún ìgbalà okàn ni won pè ní òkè-ìgbàlà ti o wa di okegbala lónìí yíì.