Ondo je ilu ni Ipinle Ondo ni Naijiria. Ki a to ri wakati mji lẹhin ti a ti gunlẹ si Okitipupa, a ti de Ondo. Bi a ti wọ Ondo, ilu meji li o sọ si mi lọ́kàn: mo ranti Eko, mo sit un ranti Ijẹbu-Ode. Ti enia ba kọ́kọ́ ri awọn ile nlá nlá ti o wà li apa ọtun ati li apa osi títì, oluwa rẹ̀ yio ṣebi igboro Eko li on wa. ti enia bas i yi ile ọja awọn oyinbo oniṣowo ati awọn ṣọpu ké-kè-ké kakiri daradara, yio mọ pe ilu oniṣowo pataki kan li Ondo jẹ lárin awọn ilu nla nla ilẹ Yoruba.

ÒpópónàYaba ni Ondo

Ile ọkan ninu awọn gbajumọ ilu ti o jẹ oniṣòwò li a wọ̀ si li ọjọ ti a de Ondo. Nigbati o di alẹ, ti a jẹun tan, ti a ntàkúrọ̀sọ, li ọkan ninú awọn ọrẹ mi berè lọwọ bale ile wa, o ni, ‘Ẹ jọwọ, ẹ má pe mo ntọpinpin o, òwò kili ẹnyin ara Ondo nṣe ti ẹ fi li owó lọwọ to bayi, ti ile mèremère si fi pọ̀ ni ilu nyin to bawọnyi?”…...

  • E.L Laṣebikan (1956), London; Ojúlówó Yoruba Iwe Kini Oxford University Press. Ilẹ Yoruba Apa Kini: Ilẹ Yoruba Apa Karun: Ondo; Ojú-ìwé 32-38.

Coordinates: 7°05′N 4°50′E / 7.083°N 4.833°E / 7.083; 4.833