Otan Ayegbaju
Ọ̀tan Ayégbajú (Òtan tabi Ọ̀tan Kòtò gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń pe ni ìgbà ìwáṣẹ̀ ) jẹ́ ìlú ìtàn ní ilẹ̀ Yorùbá tí wọ́n jẹ́ ọmọ bíbí Odùduwà tí wọ́n wá láti Ilé-Ifẹ̀ ní nǹkan bí ọdún ẹ̀ẹdẹ́gbẹ̀ta sẹ́yìn,Ó jẹ̣́ olú-ìlú tí ó wà ní Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Bólúwadúró . Àwọn ìlú tí ó wà nítòsí rẹ̀ ni : Eripa, Ìrẹ̀sì, Ìgbájọ, Òkè-run àti Ọ̀yan. [1]
Otan Otan Aiyegbaju | |
---|---|
Town | |
Otan Ayegbaju | |
Coordinates: 7°57′N 4°48′E / 7.950°N 4.800°ECoordinates: 7°57′N 4°48′E / 7.950°N 4.800°E | |
Country | Nigeria |
State | Osun |
Local Government area | Boluwaduro |
First settled | 1500s |
Founded by | Descendants of Oduduwa |
Government | |
• Type | Monarchy |
• Owa of Otan Ayegbaju | Oba Lukman Adesola Ojo Fadipe, Arenibiowo II, Owa Olatanka III |
Area | |
• Total | 100 km2 (40 sq mi) |
Ọwá ni oruko ti won n pe Ọba Ọ̀tan Ayégbajú. Ọwá ti Ọ̀tan Ayégbajú ni ó jẹ́ ọmọ ìkẹrìndínlọ̀gbọ̀n tí Odùduwà. Ọwá ti ó wà ní orí apèrè lọ́wọ́lọ́wọ́ ni Ọba Lukman Adéṣọla Òjó Fádípẹ́ Arẹ́níbíowó(Ọwá Ọlátànká III). O goróyè ní inú oṣù kẹfà ọdún 2009.[citation needed]
Ìtàn
àtúnṣeOhun tí ìtàn àtẹnudẹ́nu fi yé wa ni wípé àwọn ọmọ Odùduwà tí wọ́n rin ìrìn-àjò wá sí Ọ̀tan ní ǹkan bí ọgọ́rùn ún márùn ún ọdún sẹ́yìn láti Ilé-Ifẹ̀ ni wọ́n tẹ̀dó sí Ọ̀tan-Ilé ṣáájú kí wọ́n tó lọ sí Ọ̀tan Kòtò tí ó di Ọ̀tan Ayégbajú lónì-ín. Ọ̀tan jẹ́ ìlú tí àṣà àti ìṣe Yorùbá ti fìdí múlẹ̀ púpọ̀, tí púpọ̀ nínú àwọn olùgbé ibẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn ọmọ bíbí ibẹ̀ jẹ́ àwọn elédè Ìjẹ̀ṣà àti Ọ̀yọ́.[2]
Bí Ọ̀tan ṣe rí
àtúnṣeỌ̀tan wà ní agbègbè àríwá Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, ó sì jìnà sí ìlú Òṣogbo ní ǹkan bí ibùsọ̀ mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n. Àwọn ìlú tí Ọ̀tan bá pààlà ni: Erípa, Ìrẹ̀sì, Òkè-run, Ìgbájọ àti Ọ̀yan. Lára àwọn ìlú tí ó yí Òtan ka ni Òkè-ńlá, Igbó Ńlá, Eweko àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Àwọn ìtọka sí
àtúnṣe- ↑ "Otan Aiyegbaju Map". Nigeria Google Satellite Maps. Retrieved 2021-07-17.
- ↑ "History Of Otan-Ile". villagespec.com. 2018-08-15. Retrieved 2021-07-21.