Ounje omo
Oúnjẹ ọmọ tàbí Oúnjẹ ìkókó jẹ́ àwọn oúnjẹ tí wọ́n rọ̀, tí wọ́n lè ṣe é jẹ fún àwọn ìkókó yàtọ̀ sí omi ọmú tàbí àwọn oúnjẹ ọmọdé ìgbàlódé tí wọ́n ṣe fún jíjẹ ọmọ jòjòló tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò ju ọmọ oṣù mẹ́fà sí ọdún méjì lọ. Àwọn oúnjẹ wọ̀nyí máa ń wà lóríṣiríṣi pẹ̀lú adùn oríṣiríṣi tí wọ́n máa ń rà lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n ṣe wọ́n sílẹ̀, tàbí àwọn oúnjẹ tààrà tí wọn lọ̀ fún jíjẹ.
Oúnjẹ ọmọ títà sáàbà máa ń jẹ́ nǹkan ìfifúnni fún ìrànlọ́wọ́. Àwọn ènìyàn máa ń bu ẹnu àtẹ́ lu ṣíṣe ìfifúnni àwọn oúnjẹ ọmọ ìgbàlódé nítorí kìí jẹ́ kí àwọn ìyá ọmọ máa fún ọmọ ní ọyàn déédéé, àti pàápàá, àwọn omi tí wọ́n fi ṣe àwọn oúnjẹ wọ̀nyí lè máa dára tó fún mímu nípa pé wọ́n lé tí fi àwọn nǹkan tí ènìyàn kò lè jẹ bàwọ́n jẹ́, tí èyí yóò jẹ́ kí oúnjẹ ẹfun tí wọ́n fiwọ́n ṣe lè máa dára fún jíjẹ. | |
Àdàkọ:Wikibooks-inline
|
Àkókò tó tọ́ láti fọ́mọ lóúnjẹ ọmọ àti Ìlera ọmọ
àtúnṣeÀkókò tó tọ́ láti fọ́mọ lóúnjẹ ọmọ
àtúnṣeTítí di ọdún 2023, àwọn àjọ ìlera àgbáyé, World Health Organization, UNICEF àti àwọn àjọ mìíràn lórí ìlera dá àbá pé ó dára kí ọmọ ìkòkò tó oṣù mẹ́fà kí àwọn ìyá ọmọ tó máa gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ sí fún ọmọ lóúnjẹ. Èyí ni wọ́n gbà pé kò pẹ́ tàbí yá jù.[1][2]
Ìlera ara
àtúnṣeGẹ́gẹ́ bí àbá àjọ àgbáyé lórí ìlera àwùjọ, àjọ World Health Organization, wọ́n dábàá pé, ọmọdé ni lati fi omi ọyàn nìkan ṣe oúnjẹ fún odidi oṣù mẹ́fà láti lè ní ìdàgbàsókè àti ìlera tí péye, wọn gbà pé ọmọ oṣù mẹ́fà tí dàgbà tó nípa tara àti àyíká láti lè jẹ onírúurú oúnjẹ.[3] Àwọn onímọ̀ tí wọ́n ń gba àjọ ìlera àgbáyé World Health Assembly ní ìmọ̀ràn tí fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rí pé fífún ọmọ tí kò tó oṣù mẹ́fà oúnjẹ òkèlè tàbí oúnjẹ líle lè fa àìlera fún ọmọ ìkòkò, tí ó sì lè ṣàkóbá fún ìdàgbàsókè àti ìlera rẹ̀.[4]
Ọ̀kan lára àwọn àkóbá fífún ọmọ tí kò tó oṣù mẹ́fà lóùnjẹ́ líle ni àìní-áyọ́ọ̀nù tó (iron deficiency). Fúnfún ọmọ lóúnjẹ pọ̀ mọ́ omi ọmú ni kíákíá lè dẹ́kun ebi pípa fún ọmọ, tí yóò sì tún dín bí ọmọ yóò ṣe máa mú ọmú kù, tí yóò sì ṣàkóbá fún bí ọmú ìyá ọmọ yóò ṣe sẹ̀ daadaa sí. Nítorí pé ṣíṣẹ̀dá èròjà oúnjẹ "iron" láti inú ọmú máa a dínkù nígbà tí omi ọmú bá ń pàdé àwọn èròjà oúnjẹ mìíràn nínú ikùn kékeré tí ọmọdé máa ń ní, fúnfún ọmọ lóúnjẹ láti pẹ̀kún omi ọyàn lè ṣokùnfà àìlágbára èròjà oúnjẹ, "iron" àti anemia.[3]
Ní Canada, wọ́n máa ń ṣe àmójútó èròjà oúnjẹ sodium nínú oúnjẹ ọmọdé bíi oúnjẹ tí wọ́n ṣe jáde láti inú èso, ohun mímu láti inú èso, bẹ́ẹ̀ náà wọn kìí jẹ́ kí wọ́n ta àwọn oúnjẹ ọmọdé tí wọ́n fi àgbàdo ṣe tí kò bá ní èròjà oúnjẹ sodium tí ó tó ìwọ̀n gram 0.05 - 0.25 grams fun ìwọ̀n 100 gram nínú, èyí sáàbà máa ń dá lé irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀.[5]
Bí a bá ní ọmọ kan tí ó ní ìtàn àtakò àwọn oúnjẹ tí kò bá ara rẹ̀ mu, a lè gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ sí fún ọmọ ni oúnjẹ ẹyọ kan péré ní ìwọ̀nba, tí wọn á sí fi àlàfo ọjọ́ díẹ̀ sí àárín wọn láti lè mọ irú oúnjẹ tí kò bá ọmọ náà ni ara mú. Nípa èyí, bí ọmọ kan kò bá gba oúnjẹ kan jẹ, à á lè mọ irú oúnjẹ tí ó ń àìlera fún irú ọmọ bẹ́ẹ̀.[6]
Fúnfún àwọn ọmọdé ní àwọn oúnjẹ tí wọn ní àwọn èròjà oúnjẹ tí ọmọ nílò nínú ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsókè àti ìlera ọmọ.[7] Fúnfún ọmọ lóúnjẹ lọ́nà àìtọ́ tàbí oúnjẹ tí kò léròjà oúnjẹ pípéye nínú lè fa àìlera ara àti pípé ọpọlọ pípé ọmọ kékeré jòjòló.[7] Àwọn ìpolongo ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n máa ń dáni lẹ́kọ̀ọ́ àsìkò tí ó tọ́ láti fún ọmọ lóúnjẹ líle, irú oúnjẹ tí ó tọ́ fún ọmọ láti jẹ àti ìmọ́ tótó máa ń dára, tí wọ́n sì ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iranlọwọ lórí àṣà funfun ọmọ lóúnjẹ.[7]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Infant and young child feeding". www.who.int (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-01-15.
- ↑ "Feeding your baby: 6–12 months". www.unicef.org (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-01-15.
- ↑ 3.0 3.1 "Transition to Solid Foods". canada.gc.ca. 7 June 2008. Archived from the original on 7 June 2011. Retrieved 7 June 2011.
- ↑ "Australian Breastfeeding Association.". Archived from the original on 26 January 2009. Retrieved 7 May 2021. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Branch, Legislative Services. "Consolidated federal laws of canada, Food and Drug Regulations". laws.justice.gc.ca (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2017-07-14.
- ↑ CDC (2021-08-24). "When, What, and How to Introduce Solid Foods". Centers for Disease Control and Prevention (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-02-28.
- ↑ 7.0 7.1 7.2 Arikpo, Dachi; Edet, Ededet Sewanu; Chibuzor, Moriam T.; Odey, Friday; Caldwell, Deborah M. (2018-05-18). "Educational interventions for improving primary caregiver complementary feeding practices for children aged 24 months and under". The Cochrane Database of Systematic Reviews 2018 (5): CD011768. doi:10.1002/14651858.CD011768.pub2. ISSN 1469-493X. PMC 6494551. PMID 29775501. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=6494551.