Ibadan Peoples Party (IPP): Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò

Content deleted Content added
kNo edit summary
Ìlà 4:
Ní àsìkò ìdìbò sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti apá ilẹ̀ [[Yorùbá]] ní apá Ìwọ̀ Oòrùn ti wá sópin ní ọdún 1951, ó jẹ́ ohun tí ó ya púpọ̀ọ̀ nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìṣèlú [[Action Group]] (AG) lẹ́nu wípé iye awọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn tí wọ́n wọlé sílé aṣòfin kò ju mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) lọ nínú àádọ́rin ayé tí ó ṣófo. Ba kan náà ni ẹgbẹ́ AG pàdánù pátá pátá ní ilú Ìbàdàn ati ní ìlú [[Èkó]] tí ó jẹ́ ola ìlú fún orílẹ̀-èdè [[Nàìjíríà]] nígbà náà. Èrò ẹgbẹ́ ìṣèlú AG ni wípé àwọn yóò ní ìbò tó pọ̀ jaburata nígbà tí ó jẹ́ wípé àwọn ni àyò àwọn ọmọ Yorùbá; ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ ìṣèlú IPP pèsè àwọn ọmọ oyè mẹ́fà ní Ìbàdàn, nígbà tí 3gbẹ́ ìṣèlú NCNC kó gbogbo àyè márùn a tó kú níléẹ̀ ní ìlú [[Èkó]].
Bí ìtàn náà ṣe lọ ni wípé: Ọ̀gbẹ́ni Harold Cooper, tí ó jẹ́ aṣojú ìjọba nígbà náà ní kí gbogbo ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan ó ṣe akọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọmọ oyè wọn kí ó Ma báà sí ìdàrú-dàpọ̀ níbi ètò ìdìbò lọ́dún náà. Ẹgbẹ́ Action Group nìkan ni ó tẹ̀lé àlàkalẹ̀ yí, àwọn ọmọ oyè ìdíje dupò lábẹ́ ẹgbẹ́ ìṣèlú wọn sì ni: [[Obafemi Awolowo]] àti M.S. Sowole láti ẹkùn Ìjẹ̀bú Rẹ́mọ; S.O. Awokoya láti ẹkùn Ijẹ̀bú Òde, Rev. S.A. Banjo ati V.D. Phillips; Láti ẹkùn [[Ọ̀yọ́]]- Chief Bode Thomas, Abiodun Akerele, A.B.P. Martins, T.A. Amao ati SB Eyitayo; láti ẹkùn [[Ọ̀ṣun]]– SL Akintola, JO Adigun, JO Oroge, S.I. Ogunwale, I.A. Adejare, J.A. Ogunmuyiwa àti S.O. Ola; Láti ẹkùn [[Òndó]] – P.A. Ladapo ati G.A. Deko; Ẹkùn [[Òkìtìpupa]] – Dr. L.B. Lebi, CA Tewe àti SO Tubo; láti ẹkùn [[Ẹ̀pẹ́]] – SL Edu, AB Gbajumo, Obafemi Ajayi ati C.A. Williams; láti ẹkùn [[Ìkẹjà]]- O. Akeredolu-Ale, SO Gbadamosi ati FO Okuntola; Bẹkùn [[Agbádárìgì]] – Chief CD Akran, Akinyemi Amosu ati Rev. GM Fisher; Ekùn [[Ẹ̀gbá]] – [[J.F. Odunjo]], Alhaji A.T. Ahmed, CPA Cole, Rev S.A. Daramola, Akintoye Tejuoso, SB Sobande, IO Delano àti A Adedamola.
Lára wọn náà tún ni : ẹkùn ti [[Ẹ̀gbádò]] – J.A.O. Odebiyi, D.A. Fafunmi, Adebiyi Adejumo, A. Akin Illo àti P.O. Otegbeye; ẹkùn Ifẹ́ – Rev S.A. Adeyefa, D.A. Ademiluyi, J.O. Opadina, ati S.O. Olagbaju; ẹkùn [[Èkìtì]] – E.A. Babalola, Rev. J Ade Ajayi, S.K. Familoni, S.A. Okeya ati D Atolagbe; ẹkùn [[Ọ̀wọ̀]] – [[Michael Adekunle Ajasin]], A.O. Ogedengbe, JA Agunloye, LO Omojola àti R.A. Olusa; ẹkùn Ìwọ̀ Oòrùn [[Ijaw]] – Pere EH Sapre-Obi ati MF Agidee; láti ẹkùn [[Ishan]]] – [[Anthony Enahoro]]; láti ẹkùn [[Urhobo]] – WE Mowarin, J.B. Ohwinbiri àti JD Ifode; láti ẹkùn [[Warri]] – Arthur Prest àti O. Otere, àti [[Kukuruku Division]] – D.J.I. Igenuma.
Lara àwọn adíje-dupò tí a ka sílẹ̀ wọ̀nyí, MA Ajasin láti ẹkùn Ọ̀wọ̀ nìkan ni ó pinu láti má díje mọ́ látàrí ìṣọ̀kan ẹgbẹ́ ìṣèlú náà. Ó dúró láti fún akẹgbẹ́ rẹ̀ A.O Ògèdèngbé àti R.A Oluwa láti díje sí ipò méjì nínú mẹ́ta tí ó wà nílẹ̀ ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, nígbà tí D.K. Olumifin bọ́ sí orí àga ẹyọ̀kan tí ó kù lábẹ́ ẹgbẹ́ ìṣèlú NCNC.
Àwọn ọmọ oyè lábẹ́ ẹgbẹ́ ìṣèlú Action Group tí wọ́n sì borí ni: [[Dauda Soroye Adegbenro|Alhaji D.S. Adegbenro]], ẹkún Ẹ̀gbá; J.O. Osuntokun, ẹ́kùn Ekiti ati S.O. Hassan, láti ẹkùn Ẹ̀pẹ́.
 
==Àwọn ìtọ́ka sí==