Ibadan Peoples Party (IPP)
Ẹgbẹ́ òṣèlú Ibadan Peoples Party (IPP) [1] ni àwọn lààmì-laaka ọmọ bíbí ilẹ̀ Ìbàdàn tí wọ́n tako bí nkan ṣe ń lọ ní apá ìjọba ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Yorùbá ṣe ń lọ sí. Wọ́n da ẹgbẹ́ ìṣèlú yí sílẹ̀ ní ọdún 1950s. Àwọn tí wọ́n jẹ́ abẹnugan inú ẹgbẹ́ náà ni Augustus Akinloye tí ó jẹ́ alága, nígbà tí ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà jẹ́: Adegoke Adelabu, Olóyè Kola Balogun, Olóyè T. O. S. Benson, Olóyè Adeniran Ogunsanya àti H. O. Davies. Lara àwọn tí.wọ́n tún jẹ́ àgbà-gbà nínú ẹgbẹ́ náà ni: Olóyè S. A. Akinyemi, Olóyè S. O. Lanlehin, Olóyè Moyo Aboderin, Olóyè Samuel Lana, Olóyè D. T. Akinbiyi, Olóyè S. Ajunwon, Olóyè S. Aderonmu, Olóyè R. S. Baoku, Olóyè Akin Allen àti Olóyè Akinniyi Olunloyo.
Ipa tí ẹgbẹ́ ìṣèlú náà kò nínú ìdìbò ọdún 1951
àtúnṣeNí àsìkò ìdìbò sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti apá ilẹ̀ Yorùbá ní apá Ìwọ̀ Oòrùn ti wá sópin ní ọdún 1951, ó jẹ́ ohun tí ó ya púpọ̀ọ̀ nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìṣèlú Action Group (AG) [2] lẹ́nu wípé iye awọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn tí wọ́n wọlé sílé aṣòfin kò ju mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) lọ nínú àádọ́rin ayé tí ó ṣófo. Ba kan náà ni ẹgbẹ́ AG pàdánù pátá pátá ní ilú Ìbàdàn ati ní ìlú Èkó tí ó jẹ́ ola ìlú fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà náà. Èrò ẹgbẹ́ ìṣèlú AG ni wípé àwọn yóò ní ìbò tó pọ̀ jaburata nígbà tí ó jẹ́ wípé àwọn ni àyò àwọn ọmọ Yorùbá; ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ ìṣèlú IPP pèsè àwọn ọmọ oyè mẹ́fà ní Ìbàdàn, nígbà tí ẹgbẹ́ ìṣèlú NCNC kó gbogbo àyè márùn a tó kú níléẹ̀ ní ìlú Èkó. Bí ìtàn náà ṣe lọ ni wípé: Ọ̀gbẹ́ni Harold Cooper, tí ó jẹ́ aṣojú ìjọba nígbà náà ní kí gbogbo ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan ó ṣe akọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọmọ oyè wọn kí ó Ma báà sí ìdàrú-dàpọ̀ níbi ètò ìdìbò lọ́dún náà. Ẹgbẹ́ Action Group nìkan ni ó tẹ̀lé àlàkalẹ̀ yí, àwọn ọmọ oyè ìdíje dupò lábẹ́ ẹgbẹ́ ìṣèlú wọn sì ni: Obafemi Awolowo àti M.S. Sowole láti ẹkùn Ìjẹ̀bú Rẹ́mọ; S.O. Awokoya láti ẹkùn Ijẹ̀bú Òde, Rev. S.A. Banjo ati V.D. Phillips; Láti ẹkùn Ọ̀yọ́- Chief Bode Thomas, Abiodun Akerele, A.B.P. Martins, T.A. Amao ati SB Eyitayo; láti ẹkùn Ọ̀ṣun– SL Akintola, JO Adigun, JO Oroge, S.I. Ogunwale, I.A. Adejare, J.A. Ogunmuyiwa àti S.O. Ola; Láti ẹkùn Òndó – P.A. Ladapo ati G.A. Deko; Ẹkùn Òkìtìpupa – Dr. L.B. Lebi, CA Tewe àti SO Tubo; láti ẹkùn Ẹ̀pẹ́ – SL Edu, AB Gbajumo, Obafemi Ajayi ati C.A. Williams; láti ẹkùn Ìkẹjà- O. Akeredolu-Ale, SO Gbadamosi ati FO Okuntola; Bẹkùn Agbádárìgì – Chief CD Akran, Akinyemi Amosu ati Rev. GM Fisher; Ekùn Ẹ̀gbá – J.F. Odunjo, Alhaji A.T. Ahmed, CPA Cole, Rev S.A. Daramola, Akintoye Tejuoso, SB Sobande, IO Delano àti A Adedamola. Lára wọn náà tún ni : ẹkùn ti Ẹ̀gbádò – J.A.O. Odebiyi, D.A. Fafunmi, Adebiyi Adejumo, A. Akin Illo àti P.O. Otegbeye; ẹkùn Ifẹ́ – Rev S.A. Adeyefa, D.A. Ademiluyi, J.O. Opadina, ati S.O. Olagbaju; ẹkùn Èkìtì – E.A. Babalola, Rev. J Ade Ajayi, S.K. Familoni, S.A. Okeya ati D Atolagbe; ẹkùn Ọ̀wọ̀ – Michael Adekunle Ajasin, A.O. Ogedengbe, JA Agunloye, LO Omojola àti R.A. Olusa; ẹkùn Ìwọ̀ Oòrùn Ijaw – Pere EH Sapre-Obi ati MF Agidee; láti ẹkùn Ishan] – Anthony Enahoro; láti ẹkùn Urhobo – WE Mowarin, J.B. Ohwinbiri àti JD Ifode; láti ẹkùn Warri – Arthur Prest àti O. Otere, àti Kukuruku Division – D.J.I. Igenuma. Lara àwọn adíje-dupò tí a ka sílẹ̀ wọ̀nyí, MA Ajasin láti ẹkùn Ọ̀wọ̀ nìkan ni ó pinu láti má díje mọ́ látàrí ìṣọ̀kan ẹgbẹ́ ìṣèlú náà. Ó dúró láti fún akẹgbẹ́ rẹ̀ A.O Ògèdèngbé àti R.A Oluwa láti díje sí ipò méjì nínú mẹ́ta tí ó wà nílẹ̀ ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, nígbà tí D.K. Olumifin bọ́ sí orí àga ẹyọ̀kan tí ó kù lábẹ́ ẹgbẹ́ ìṣèlú NCNC. Àwọn ọmọ oyè lábẹ́ ẹgbẹ́ ìṣèlú Action Group tí wọ́n sì borí ni: Alhaji D.S. Adegbenro, ẹkún Ẹ̀gbá; J.O. Osuntokun, ẹ́kùn Ekiti ati S.O. Hassan, láti ẹkùn Ẹ̀pẹ́.
Àwọn ìtọ́ka sí
àtúnṣe- ↑ "WikiVisually.com". WikiVisually. Retrieved 2021-05-29.
- ↑ "Action Group". Encyclopedia Britannica. Retrieved 2021-05-29.