Pápá Parsonage ní Nuenen
Pápá Parsonage ní Nuenen (Duki: De pastorie in Nuenen), tí wọ́n tún máa ń pè ní Pápá Parsonage ní Ìsun-omi Nuenen (Duki: De pastorie in Nuenen in het voorjaar) tàbí Pápá Ìsun-omi (Duki: Lentetuin: F185, JH484), jẹ́ isẹ́-ọ̀nà àwòrán yíyà ayé àtijó tí wọ́n fi epo yà ní sẹ́ńtúrì ókàndínlógún sẹ́yìn, tí oníṣẹ́-ọ̀nà ayawòrán, Vincent van Gogh, ṣẹ̀dá lóṣù karùn-ún ọdún 1884 nígbà tí ó ń gbé pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀ ní Nuenen. Arákùnrin Van Gogh ya ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwòrán pàápàá jù lọ èyí tí ó fi epo yà káàkiri pápá náà tí ó kojú sí ilé ìgbé àwọn àlùfáà tí wọ́n ń pè ní Parsonage. [1]
Àwọn àwòrán wọ̀nyí wà nínú àkójọpọ̀ àwọn ohun méèlegbàgbé ní ilé ìtọ́jú àwọn ohun méèlegbàgbé ní Netherlands lọ́dún 1962 sí 2020. Lọ́gbọ̀n ọjọ́ oṣù kẹta ọdún 2020, wọ́n jí àwọn nǹkan wọ̀nyí kó níbi ìpàtẹ kan ní ilé ìtọ́jú ohun méèlegbàgbé ní Laren, lẹ́yìn tí wọ́n tì í pa nítorí àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19. [2]
Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀
àtúnṣeArákùnrin Van Gogh gbé ní The Hague pẹ̀lú Sien Hoornik lẹ́yìn èyí ó dá gbé fún oṣù díẹ̀ ní Drenthe lápá àríwá orílẹ̀-èdè Netherlands. Lẹ́yìn èyí, ó lọ gbé ní ilé ìgbé àwọn àlùfáà tí Dutch Reformed Church ní Nuenen lẹ́bàá Eindhoven lóṣù Kejìlá ọdún 1883 níbi tí bàbá rẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́ àlùfáà.[3] Ẹbí rẹ̀ yí ilé ìfọṣọ tí ó wà ní ẹ̀yìnkùlé wọ́n sí ilé ayawòrán .[4]
Van Gogh wà pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀ ní Nuenen fún nǹkan bí ọdún méjì, ní àkókò yìí ó ya oríṣiríṣi àwòrán tó tọ́ igba, lára èyí tí iṣẹ́ àkọ́kọ́ tó gbajúmọ̀ tí wọ́n ń pè ní The Potato Eaters. Ó kó lọ sí ìlú Antwerp lóṣù kọkànlá ọdún 1885[5] lẹ́yìn náà, ó tún kó lọ sí Paris lọ́dún 1886.[6]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "The Parsonage Garden at Nuenen in Spring by GOGH, Vincent van". Web Gallery of Art. Retrieved 30 March 2020.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedartnet News 2020
- ↑ "Vincent van Gogh in Nuenen, The Netherlands". Van Gogh Route. Retrieved 30 March 2020.
- ↑ "The Vicarage at Nuenen, 1885". Permanent Collection. Van Gogh Museum. 2005–2011. Archived from the original on 28 October 2007. Retrieved 15 May 2011.
- ↑ "Peasant Painter". Van Gogh Museum. Retrieved 31 March 2020.
- ↑ Siegal, Nina (October 16, 2013). "Becoming Vincent Van Gogh: The Paris Years". The New York Times (New York City: New York Times Company). https://www.nytimes.com/2013/10/17/arts/international/becoming-vincent-van-gogh-the-paris-years.html.