Pallas Kunaiyi-Akpannah
Pallas Daemi Kunaiyi-Akpannah (tí wọ́n bí ní July 12, 1997) jẹ́ agbábọ́ọ̀lù alájùsáwọ̀n ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Ó gbá bọ́ọ̀lù náà lásìkò tó ṣì wà ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga fún Northwestern Wildcats[2][3] bákan náà ni ó gbá bọ́ọ̀lù fún Italian Seria A, ti Faenza Basket Project.[4]
No. 22 – Faenza Basket Project | ||||||||||
---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|
Position | Center /power forward | |||||||||
League | Seria A | |||||||||
Personal information | ||||||||||
Born | 12 Oṣù Keje 1997 Port Harcourt, Rivers State, Nigeria | |||||||||
Nationality | Nigerian | |||||||||
Listed height | 6 ft 2 in (1.88 m) | |||||||||
Career information | ||||||||||
High school | Rabun Gap-Nacoochee School, Rabun County, Georgia | |||||||||
College | Northwestern Wildcats | |||||||||
NBA draft | 2019 / Undrafted | |||||||||
Pro playing career | 2019–present | |||||||||
Career history | ||||||||||
2019–2019 | Chicago Sky | |||||||||
2019–2020 | Pallacanestro Vigarano | |||||||||
2020–2021 | BC Namur-Capitale | |||||||||
2021–present | Faenza Basket Project | |||||||||
Medals
|
Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeKunaiyi-Akpannah bẹ̀rẹ̀ ilé-ìwé girama ní Nàìjíríà ilé-ìwé tó ń pèsè ilé-ìgbé fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́. Ọmọdún mẹ́rìnlá ló wà tó fi bẹ̀rẹ̀ sí ní gbá bọ́ọ̀lù yìí. Ó lọ sí àpérò kan tí wọ́n gbé kalẹ̀ fún àwọn agbábọ̀ọ́lù alájùsáwọ̀n, èyí ti Hope for girls gbé kalẹ̀, láti ọwọ́ Mobolaji Akiode ní Abuja, ní Nàìjíríà, ibẹ̀ sì ni wọ́n ti ṣàwárí ẹ̀bùn rẹ̀.[5] Kunaiyi-Akpannah lọ sí Rabun Gap-Nacoochee School, ní Rabun County, Georgia, ní United States, láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, nígbà tó wà ní ọmọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Lásìkò tó wà ní ilé-ìwé girama, ó ń gba bọ́ọ̀lù lásìkò ọlúdé. Ó ṣojú ẹgbẹ́ rẹ̀, ó sì gbé ipò kejì ní ìdíje ti State Tournament, ti ọdún 2014.[6][7] Bákan náà ni ó kópa nínú àwọn eré-ìdárayá mìíràn ní ilé-ẹ̀kọ́.[8]
Iṣẹ́ tó yàn láàyò
àtúnṣeWọ́n mú Kunaiyi-Akpannah wọ ẹgbẹ́ WNBA Chicago Sky ní ọjọ́ oṣù karùn-ún ọdún 2019, àmọ́, wọ́n yọ ọ́ kúrò ní ọjọ́ kẹjọ oṣù karùn-ún ọdún 2019.[9][10]
Kunaiyi-Akpannah lọ sí ẹgbẹ́ Italian Seria A side Pallacanestro Vigarano ní ọdún 2019, ó sì gbá bọ́ọ̀lù náà ní àárín ẹgbẹ́ náà.[11] Ní ọjọ́ karùndínlógún osụ̀ kẹwàá, ọdún 2019, ó gbá bọ́ọ̀lù tako Broni, ó sì jáwe olúborí nínú ìdíje náà, pẹ̀lú 11.[12]
Ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣụ̀ kẹfà ọdún 2021, ó tọwọ́ bọ̀wé pẹ̀lú ẹgbẹ́ Italian Seria A ti Faenza Basket Project fún ìdíje ti ọdún 2021 wọ 2022.[13]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Pallas KUNAIYI-AKPANAH at the FIBA Women's Afrobasket 2019". FIBA.basketball.
- ↑ "Pallas Kunaiyi-Akpanah - 2018-19 - Women's Basketball". Northwestern University Athletics.
- ↑ Wangman, Ryan (March 6, 2019). "Pallas Kunaiyi-Akpanah reflects on Northwestern women's basketball career".
- ↑ "Pallas Kunaiyi Basketball Player Profile, Pallacanestro Vigarano, Northwestern, News, Serie A1 stats, Career, Games Logs, Best, Awards - eurobasket". Eurobasket LLC.
- ↑ Minichino, Adam. "Pallas Kunaiyi-Akpanah finds her voice". Espn.com. https://www.espn.com/espnw/news-commentary/story/_/id/10482977/basketball-recruit-journey-us-nigeria-espnw.
- ↑ "pallas-kunaiyi-akpanah". ESPN.com.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedauto3
- ↑ "Pallas Kunaiyi-Akpanah - Stats". MileSplit GA.
- ↑ "Pallas Kunaiyi-Akpanah WNBA Stats & News". www.rotowire.com.
- ↑ "Chicago Sky Waive Leslie Robinson, Pallas Kunaiyi-Akpanah". Chicago Sky.
- ↑ "Pallacanestro Vigarano basketball, News, Roster, Rumors, Stats, Awards, Transactions, Details - eurobasket". Eurobasket LLC.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "ITALY Basketball BoxScores, ITALY Basketball Scoreboard - eurobasket". Eurobasket LLC.
- ↑ "SERIE A: BENVENUTA PALLAS". Faenza Basket Project. 29 June 2021. Retrieved 19 July 2021.