Rabia Zuberi
Rabia Zuberi (c. 1941 – 16 January 2022), tí àwọn ará Pakistan tún máa ń pè ní Queen Mother of Arts,[1] jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Pakistani, tó fìgbà kan jẹ́ agbẹ́gilére, ayàwòrán, alága Pakistan Arts Council, olùkọ́, àti obìnrin Ilẹ̀ Pakistan àkọ́kọ́ tó máa ṣiṣẹ́ agbẹ́gilére. Ó ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn tí ó ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè Pakistan. Lára àwọn àwòrán rẹ̀ ni Duputta, Quest for Peace, àti àwọn igi tí a gbẹ́ lére kan, tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Peace Message from the Progressive World and Peace Message, èyí tí National Art Gallery, Pakistan gbà lásìkò ìṣàfihàn kan ní ọdún 2003.[2]
Rabia Zuberi | |
---|---|
Ilẹ̀abínibí | Pakistani |
Ẹ̀bùn | Pride of Performance (2010) |
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí i ní ọdún 1940, ní United Province, British India (tí ó ti di Kanpur, Uttar Pradesh, báyìí ní India).[3] Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè láti Aligarh Muslim University ní ọdún 1959[4] lẹ́yìn náà ló lọ sí ìlú Lucknow, níbi tí ó ti lọ sí Lucknow College of Arts and Crafts pẹ̀lú àbúròbìnrin rẹ̀, ìyẹn, Hajra Mansoor.[5] Léyìn tí orílẹ̀-èdè India pínyà, ìdílé rẹ̀ kó lọ sí orílẹ̀-èdè Pakistan ní ọdún 1961, tí òun àti àbúròbìnrin rẹ̀ sì ń kàwé ní orílẹ̀-èdè India, kí wọ́n ṣẹ̀ tó wá kó lọ sí ìlú Karachi ní ọdún 1964.[3]
Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeLáti ìgbà tí ó wà ní ọmọdún mẹ́wàá ló ti ń ya àwòrán. KÍ ó tó kó lọ sí ilẹ̀ Pakistan, ó kópa nínú ìṣàfihàn ìta gbangba ọdọọdún ní All-India Youth Art Exhibitions, ní Delhi, níbi tí wọ́n ti fún un ní àmì-ẹ̀yẹ láti ọdún 1960 wọ ọdún 1963. Ní ọdún 2010, ìjọba ilẹ̀ Pakistan fún un ní àmì-ẹ̀yẹ tí wọ́n pè ní Pride of Performance, látàri àwọn awòrán rẹ, èyí tó ṣe àfihàn ojú ọmọ aláìníyàá.[6][7]
Ó gbẹ́ ère kan fún àwọn ológun Pakistan ní ọdún 1978 nígbà tí wọ́n yàn án láti ṣiṣẹ́ fún ìjọba àpapọ̀ ilẹ̀ Pakistan. Wọ́n padà gbé èrè náà sí pápá ìṣere Zamzama. Bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n yàn án láti gbé èrè fún ilé-iṣẹ́ aládàáni àti ti ìjọba ní Islamabad.[8] Ní ọdún 1964, ó ṣe ìdásílè Karachi School of Art, èyí tó jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ fún iṣẹ́-ọnà àti ìdárayá.
Ìtàn ayé rẹ̀ wà nínú ìwé kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Rabia Zuberi: Life and Work láti ọwọ́ Marjorie Husain, èyí tí wọ́n ṣàgbéjáde ní ọdún 2009. Ìtàn nípa iṣẹ́ rẹ̀ ni wọ́n kọ sínú ìwẹ́ Unveiling the Visible: Lives and Works of Women Artists of Pakistan láti ọwọ́ Salima Hashmi, èyí tí wọ́n ṣàgbéjáde ní ọdún 2002.[9] Gẹ́gẹ́ bí i Hindustan Yimes, Ìwé Rabia Zuberi: Life & Works, ò sọ̀rọ̀ nípa ìkólọ rẹ̀ lọ sí ilè Pakistan.[8]
Ìgbésí ayé ara ẹni àti ikú rẹ̀
àtúnṣeZuberi kú sí ìlú Karachi ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣụ̀ kìíní ọdún 2022, ní ọmọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin.[10]
Àwọn ìwé rẹ̀
àtúnṣe- Zuberi, Rabia; Husain, Marjorie (2008). Rabia Zuberi: Life and Work. Foundation for Museum of Modern Art. ISBN 9789698896041. https://books.google.com/books?id=sp_mAAAAMAAJ.
- Hashmi, Salima (2002). Unveiling the Visible: Lives and Works of Women Artists of Pakistan. ActionAid Pakistan. ISBN 9789693513615. https://books.google.com/books?id=WsifAAAAMAAJ.
Àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀ àti ìdálọ́lá
àtúnṣe- Àmì-ẹ̀yẹ Pride of Performance Award láti ọwọ́ Ààrẹ orílẹ̀-èdẹ̀ Pakistan ní ọdún 2010[11]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Singh, Khushwant (1 August 2008). "Our failing political esteem". Hindustan Times.
- ↑ Husain, Marjorie (25 September 2015). "Art work: A tryst with destiny". Dawn. Retrieved 18 September 2022.
- ↑ 3.0 3.1 Chatterjee, Partha (4 December 2009). "Gentle rainbow" . Frontline. Retrieved 18 September 2022.
- ↑ "Department of Fine Arts - Notable Alumni of the Department". Aligarh Muslim University. Archived from the original on 19 September 2022. Retrieved 18 September 2022. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Ahmed, Munir (23 December 2017). "Ninth National Art Exhibition dedicated to nine legendary Pakistani artists commences at PNCA". Daily Times.
- ↑ Chatterjee, Partha (4 December 2009). "Gentle rainbow" . Frontline. Retrieved 18 September 2022.
- ↑ Profile of Rabia Zuberi on Karachi School Of Art website[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́] Published 3 April 2019, Retrieved 5 October 2020
- ↑ 8.0 8.1 Singh, Khushwant (1 August 2008). "Our failing political esteem". Hindustan Times.
- ↑ Muhajir, Tauqeer (22 Mar 2020). "Saluting women artists of Pakistan". Khaleej Times.
- ↑ "Rabia Zuberi passes away". Dawn. 17 January 2022. https://www.dawn.com/news/1669858.
- ↑ Profile of Rabia Zuberi on Karachi School Of Art website Archived 2021-06-13 at the Wayback Machine. Published 3 April 2019, Retrieved 5 October 2020