Radio Lagos
Radio Lagos 107.5 FM tí a tún Mo sí (Tiwa n' Tiwa) ni ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu ní ọdún 1977 ni ó jẹ́ ẹ̀ka ti Nigerian Broadcasting Corporation. Ilé-iṣẹ́ asọ̀rọ̀mágbèsì yí jẹ́ ilé-iṣẹ́ ìròyìn àkọ́kọ́ tí yóò jẹ́ ti Ìpínlẹ̀ lórí ìkanì FM.
City | Èkó |
---|---|
Broadcast area | Ìpínlẹ̀ Èkó |
Frequency | 107.5 MHz FM |
Language(s) | Èdè ìbílẹ̀ abínibí ati èdè Gẹ̀ẹ́sì |
Transmitter coordinates | 6°37′10.767″N 3°21′12.719″E / 6.61965750°N 3.35353306°ECoordinates: 6°37′10.767″N 3°21′12.719″E / 6.61965750°N 3.35353306°E |
Owner | Lagos State Radio Corporation |
Ilé-iṣẹ́ asọ̀rọ̀mágbésì yí ń gbòhùn sáfẹ́fẹ́ lórí ìkànì A.M méjì (990 kHz.303mtrs àti 918 kHz.327mtrs) tẹ́lẹ̀. Látàrí ìṣèwádí ọ̀nà ọ̀tun láti lè ma kàn sí ọ̀gọ̀rọ̀ ènìyàn ni ó bí ojú-òpó Radio Lagos tí ó wà ní orí ìkànì 107.5 FM (Tiwa n'Tiwa) lábẹ́ àṣẹ àti ìdarí ilé-iṣẹ́ Lagos State Radio Service ní ọdún 2001.
Ilé-iṣẹ́ asọ̀rọ̀mágbèsì Radio Lagos ni ó kọ́kọ́ jẹ́ ilé-iṣẹ́ agbóhùn-sáfẹ́fẹ́ tí ó ń lo èdè Yorùbá àti èdè Ègùn láti fi gbóhùn -sáfẹ́fẹ́ tí wọ́n sì ń lo ìdá méjì péré nínú ìdá ọgórùn ún èdè Gẹ̀ẹ́sì láti fi sọ ìròyìn. Àwọn tí ilé-iṣẹ́ rédíò yí fi sọ́kàn jùlọ láti jẹ́ olùgbọ́ wọn ni àwọn ọmọ Yorùbá nílé àti kókó. [1]
Ẹ tún lè wo
àtúnṣeÀwọn itọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Haris Aslam (20 November 2014). "Radio Lagos 107.5 Online". RadioAfrican. Archived from the original on 1 October 2020. Retrieved 13 March 2021.
Àwọn ìjásóde
àtúnṣe- "Radio Lagos". Archived from the original on 2015-02-01. Retrieved 2021-03-13.