Richard Akuson
Richard Akuson (tí a bí ní ọjọ́ kẹrìndílọ́gbọ̀n oṣù keje ọdún 1993) jẹ́ agbẹjọ́rò ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ajà fún ẹ̀tọ́ lórí LGBTQ, òǹkọ̀wé, olóòtú àti olùdásílẹ̀ [1] ìwé ìròyìn tí wọ́n ǹ pé A Nasty Boy,[2] èyí tíí ṣe ìwé àtẹ̀jáde äkọ́kọ́ lórí LGBTQ+ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ní ọdún 2019, Richard wà lára Forbes Áfíríkà ọgbọ̀n tí wọ́n dárúkọ lábẹ́ ọgbọ̀n[3] àwọn ènìyàn tí wọ́n dúró gégé bíi olútakò fún àyípadà láti tako àwọn ìmọràn líle nípa ako, abo, àti Ìbálòpọ̀ ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà níbití Ìbálòpọ̀ láàrín ako pẹ̀lú akọ àti abo pẹ̀lú abo tí jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ pẹlú ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìnlá. Ni ọdún 2017, wọ́n yáàn fún àmì-ẹ̀yẹ ti The Future Award Africa's, èyí tíí ṣe àmì-ẹ̀yẹ tuntun ti media. Richard tún jẹ́ ẹnití wón ti yàn ní èèmejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ gégé bíi ẹni tí ó dára jùlọ nípa ìwé kíkọ lori fashion fún àmì-ẹ̀yẹ Abryanz Style and Fashion Award. Lẹ́hìn ìfilọ́lẹ̀ ìwé ìròhìn kan tí wọ́n ń pè ní Nasty Boya ní ọdún 2017, Richard wà lára àwọn ogójì ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà tí ó lágbára jùlọ tí ó sì wípé ọjọ́ orí I wọn kò ì tí tó ogójì ọdún tí Ynaija dárúkọ.[4]
Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé rẹ àti ẹ̀kọ́.
àtúnṣeWọ́n bí Richard ní Akwanga, ní Ipinle Nasarawa, orílè-èdè Nàìjíríà. Richard ni wọ́n bí ṣe ìkejì nínú àwọn ọmọkùnrin mẹ́ta, ó dàgbà sí ìdílé tí wọn kò là tí wọn kò dára ṣagbe. Bàbá rẹ jẹ olóṣèlú nígbàtí ìyá rẹ jẹ olùkọ́ ní kọ́lẹ́ẹ̀jì. O lọ sí ilé-ìwé gíga tí Shepherd's International, èyí tí ó jẹ́ lára ilé-ìwé aládàáni ti àwọn onìgbàgbọ́ níbití wọ́n ti ń pèsè ibùgbé fún àwọn ọmọ ilé-ìwé. Lẹ́hìn èyí ni ó lọ sí ilé-èkó gíga Yunifásítì ti Ipinle Nasarawa tí ó wà ní Kefi, fún ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ìjìnlè àkọ́kọ́ nínú òfin. Wọ́n pèé sí ilé ìgbìmọ̀ òfin ti ilé Nàìjíríà gégé bíi onídàájọ́ àti agbẹjọ́rò ti ilé aṣòfin àgbà ilẹ̀ Nàìjíríà ní ọdún 2017, lẹ́hìn tí ó ti kọ́ ẹ̀kọ́ gba oyè ní ilé-èkó amofin ti ilé Nàìjíríà tí ó wà ní Èkó.
Iṣẹ́
àtúnṣeAkuson bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bíí olùkọ ní àrà nígbàtí ó pé ọmọ ọdún méjìdínlógún. Ní ọdún 2014, ó lọ́wọ́ pẹlú ṣe àgbékalẹ̀ ILLUDED, èyí tíí ṣe pẹpẹ pínpín fọ́tò lórí ẹ̀rọ ayélujára. Ní ọdún 2016, wọ́n yàn án sí ipò láti ṣe olórí i ẹ̀ẹ̀ka fashion àti style ti BellaNaija. Ipò yì ní ipò tí ó ṣe ìfilọ́lẹ̀ iṣẹ́ ẹ rẹ̀. Iṣẹ́ ẹ rẹ̀ ní BellaNaija mu kí ó gba àmì ẹ̀yẹ ti Abryanz Style Fashion. Wọ́n sì tún yàn án láti jẹ́ oǹkọ̀wé fashion tí ó peregedé jùlọ ní odún 2016. Léhìn náà ní ọdún kanna ni Richard fi BellaNaija sílẹ̀ láti lọ ṣe ìfilọ́lẹ̀ Ọmọkunrin PR. Ní ọdún 2017, nígbàtí ó wà ní ilé-èkó ìmọ̀ òfin ti orílè-èdè Nàìjíríà, ọ ṣe ìfilọ́lẹ̀ A Nasty Boy, èyí tó jẹ́ títarí ààlà [5] àtẹ̀jáde LGTBQ+ èyí tí ó wípé láìpẹ́ ni ó dàgbà tí ó sì ní òkìkí káríayé.[6]
Àròkọ
àtúnṣeNí oṣù kẹrin ọdún 2019 Richard ṣe onígbàgbọ ìtàn-àkọlé kan fún ilé-isé CNN tí ó sì sọ àwọn oun tí ó fàá tí òún fi sá kúrò ní orílè-èdè Nàìjíríà wá sí orílè-èdè Améríkà fún ààbò. Ni oṣù keje ọdún 2019, ó kọ àròkọ tí ó jẹnilọ́kàn[7] fún ìwé ìròyìn New York Times, èyí tí ó jẹ ti "àtúnyẹ̀wò ọjọ Sunday" tí àkọlé rẹ jẹ́ "This is Quite Gay". Eléyìí ni wọ́n ti jáde gbangba ní ojú abala àkókò ìwé ìròyìn Times ti orí ẹ̀rọ ayélujára. Bákannáà ni ó tún jáde nínú ìwé ìròhìn tí wọ́n tẹ̀ jáde lójú ewé pàtàkì tí kò farasin ní ọjọ́ Kejì.
Akitiyan àti ibi ààbò
àtúnṣeRichard wá ibi ààbò lọ sí orílè-èdè Amẹ́ríkà ní ọdún 2018 lẹ́yìn tí ó sálọ kúrò ní orílè-èdè Nàìjíríà lẹ́yìn tí ó ti yọ nínú ìkọlù àwọn oníwà ìbàjẹ́ kan. Ní ìlú Amẹ́ríkà, o síwájú láti máa sọ̀rọ̀ ní gbangba nípa ìkọlù àti àṣà àìbíkítà nípa ìbálòpọ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó ti fi ààyè sílẹ̀ fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú awọn OkayAfrica, Very Goog Light[8] àti The Black Youth Project,[9] níbití ó tí ṣe àlàyé lọ́pọ̀lọpọ̀ àwọn oun tí ó yí ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yìí ká. Richard asíwájú láti máa jẹ́ onígboyà ajà-fún-ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn fún LGBTQ+ àti àwọn tí ó wà ní agbègbè ibi ààbò ní ìlú Améríkà.
Àwọn ìtọ́ka sí.
àtúnṣe- ↑ Akinwotu, Emmanuel (2017-11-16). "Nigeria's Nasty Boy: 'People in my law class thought I worked for a porn site'". the Guardian. Retrieved 2021-09-14.
- ↑ "Get to know Nigeria’s most controversial fashion magazine". Dazed. 2017-06-29. Retrieved 2021-09-14.
- ↑ "Richard Akuson, Founder of A Nasty Boy, & Upile Chisala in Forbes Africa's 30 under 30 List for 2019". Brittle Paper. 2019-07-05. Retrieved 2021-09-14.
- ↑ Okafor, Chinedu (2018-01-03). "Amaka Osakwe, Richard Akuson, Tokyo James… See the #YNaijaPowerList2017 for Fashion and Beauty » YNaija". YNaija. Retrieved 2021-09-14.
- ↑ "A Nasty Boy: The Nigerian magazine breaking gender taboos". BBC News. 2017-08-31. Retrieved 2021-09-14.
- ↑ Idowu, Torera; CNN, for (2017-06-13). "Is this Nigeria's most controversial magazine?". CNN. Retrieved 2021-09-14.
- ↑ "Opinion - ‘This Is Quite Gay!’". The New York Times. 2019-07-06. Retrieved 2021-09-14.
- ↑ "Crunching the numbers for coronavirus - Imperial College London". Imperial News. 2020-03-13. Retrieved 2021-09-14.
- ↑ "Richard Akuson: the 'A Nasty Boy' editor talks the future of his queer fashion magazine and life as an asylum seeker in the U.S.". The Black Youth Project. 2019-07-15. Retrieved 2021-09-14.