Rosaline Patricia Irorefe Bozimo (ọjọ́-ìbí ọjọ́ kìíní oṣù kìíní ọdún 1946) jẹ́ agbẹjọ́ro ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n yàn-án gẹ́gẹ́ bí Adájọ́ àgbà ìpínlẹ̀ Delta láti ọjọ́ kẹta-lé-lógún oṣù kẹta ọdún 2003. Ó fẹ̀hìn ipò tì ní ọjọ́ kìíní oṣù kìíní ọdún 2011 tí Honorable Justice Abiodun Smith sì tèlé ẹ̀.[1] Nígbà àkókò Walter Onnoghen gẹ́gẹ́ bí adájọ́ àgbà ilẹ̀ Nàìjíríà (CJN), ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Alákoso, National Judicial Institute (NJI).[2]

Rosaline Patricia Irorefe Bozimo
Chief Judge of Delta State
In office
3 April 2003 – 1 January 2011
Arọ́pòHonorable Justice Abiodun Smith
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí1 Oṣù Kínní 1946 (1946-01-01) (ọmọ ọdún 78)
Udu, Delta State, Nigeria
Ọmọorílẹ̀-èdèNigerian
(Àwọn) olólùfẹ́Alaowei Broderick Bozimo
Alma materAhmadu Bello University
OccupationLawyer, Judge

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀

àtúnṣe

Rosaline Bozimo ni wọ́n bí ní ọjọ́ kìíní osù kìíní ọdún 1946 ní ìjọba ìbílẹ̀ Warri South ní Ìpínlẹ̀ Delta. Ó lọ sí ilé-ìwé St. Maria Goretti Grammar, Ìlú Benin fún ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀, lẹ́hìn náà Urhobo College, Effurun. Ní Oṣù Kẹ́sàn-án ọdún 1970 wọ́n gbà á wọlé sí Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Ahmadu Bello, Zaria, tí ó gba òye nípa òfin ní ọdún 1973. Lẹ́hìn náà ó lọ sí Ilé-ẹ̀kọ́ òfin ti Nàìjíríà (Nigerian Law School) àti pé wọ́n pè é láti di aṣòfin (Called to Bar) ní ọdún 1974. Lẹ́hìn tí National Youth Service ní Enugu àti Onitsha ní East Central State nígbà náà, ó di ìkọkọ amòfin ní ọdún 1975. Pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ Alaowei Broderick Bozimo ó jẹ́ igbákejì olùdásílẹ̀ ti Broderick Bozimo & Co. Ó jẹ́ ní ṣókí ọmọ ẹgbẹ́ ti Ìdájọ́ ti Ìpínlẹ̀ Bendel àtijọ́ gẹ́gẹ́ bí adájọ́, ṣáájú kí ó tó padà sí iṣẹ́ òfin aládani (ní ọdún 1978 sí ọdún 1983). Ní Oṣù Kejìlá ọdún 1983 wọ́n tún yàn-án Májísíreéétì ti Ìpínlẹ̀ Bendel, ó di Olóyè Adájọ́ ní Oṣù Kẹjọ ọdún 1988. Nígbàtí a ṣẹ̀dá Ìpínlẹ̀ Delta láti Ìpínlẹ̀ Bendel àtijọ́ ní ọdún 1991, ó di Alága àkọ́kọ́ ti Ìgbìmọ̀ Tenders ti Ilé-ẹjọ́ gíga ti Ìpínlẹ̀ Delta, àti olóyè alákoso ti Ilé-ẹjọ́ gíga ti Ìpínlẹ̀ ní Oṣù Kẹsàn-án ti ọdún kan náà. Ní Oṣù Kejìlá ó ti búra gẹ́gẹ́ bí adájọ́ ilé-ẹjọ́ gíga kan.

Àwọn Ìtọ́ka Sí

àtúnṣe
  1. "Delta Gets New CJ". Nigerian Observer. July 1, 2011. Archived from the original on 2013-01-30. Retrieved 2012-01-12.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "Bozimo dismisses fraud allegations, labels them outright falsehood". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-07-24. Archived from the original on 2022-03-25. Retrieved 2022-03-25.