Roukiata Ouedraogo
Roukiata Ouedraogo (tí a bí ní 1979) jẹ́ ònkọ̀tàn, òṣèré àti apanilẹ́ẹ̀rín ọmọ orílẹ̀-èdè Bùrkínà Fasò.
Roukiata Ouedraogo | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 1979 (ọmọ ọdún 44–45) |
Orílẹ̀-èdè | Burkinabé |
Iṣẹ́ | Playwright, actress, and comedian |
Ìsẹ̀mí rẹ̀
àtúnṣeRoukiata dàgbà ní ìlú Fada N'Gourma. Ó jẹ́ ọmọbìrin ti òṣìṣẹ́ ìjọba kan. Bàbá rẹ̀ náà ti kópa rí nínu eré ìtàgé. Nígbà tí ó wà lọ́mọdé, Ouedraogo lọ sí ìlú Ouagadougou láti tẹ̀síwájú nínu ẹ̀kọ́ rẹ̀.[1] Nígbà tí ó wà ní ilé-ìwé girama, ó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ìtàgé, èyí tí ó fun ní ànfààní láti káàkiri orílẹ̀-èdè náà.[2] Ní àkókò náà, ó maá n dirun tó sì tún maá n ránṣo fún àwọn èyàn láti máa fi bọ́ ararẹ̀. Lẹ́hìn ìparí ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó kó lọ sí ìlú Paris ní ọdún 2000, níbití ẹ̀gbọ́n rẹ̀ n gbé.
Ó ti ṣiṣẹ́ rí gẹ̀gẹ̀ bi aṣaralóoge àti afẹwàṣiṣẹ́ láìmoye ọdún. Ní ọdún 2007, Ouedraogo pinnu láti gbájúmọ́ eré ìtàgé, ó sì rí ànfààní láti kópa nínu eré tẹlifíṣònù <i>Cours Florent</i> lẹ́hìn àyẹ̀wò.
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Roukiata Ouédraogo : actrice sinon rien – Jeune Afrique" (in French). https://www.jeuneafrique.com/136480/societe/roukiata-ou-draogo-actrice-sinon-rien/. Retrieved 5 October 2020.
- ↑ "Roukiata Ouedraogo". Africultures.com (in French). Retrieved 5 October 2020. .