Ruth Gordon
Ruth Gordon (ti a bí ní Oct 30, 1986, ti ósì fi ayé sílè ní August 28, 1985) jé òsèrébìnrin àti olùko òsèré omo orílè-èdè Amerika, Ó gba Ebun Akademi fún Obinrin Osere Keji Didarajulo.
. Ó bèrè isé òsèré ní odun 1915, ìgbàyen ni ó jé omo odún kandinlogun.[1]
Apere àwon eré to sere nínú won ni: Rosemary's Baby (1968), What Ever Happened to Aunt Alice (1969), Where's Poppa? (1970), Harold and Maude (1971), Every Which Way but Loose (1978), and Any Which Way You Can (1980). Ó tún ko ko òpòlopò eré àti ìwé
Àárò ayé àti Èkó rè
àtúnṣeA bi Ruth Gordon ní agbegbe 41 Winthrop Avenue ti ìlú Quincy, Massachusetts. O padà gbé ni agbègbè 41 Marion Street (1901–1903) ati 14 Elmwood Avenue (1903–1914) ti ìlú kanáà.[2] A bi sínú ìdíle Annie Tapley àti Clinton Jones, oun nikan ni ìyá àti baba rè by papò, bo tilè jé wipé bàbá rè ti bí omobinrin kan ni igbeyawo rè àkókó, èni tí orúko rè njé Claire.[3] Ìgbà tó kókó di ìlú mò mí ni ìgbà tí won lo àwòrán rè ní ipolowo kan tí ògá bàbá rè se fún ilé-isé Mellin's food for infants and invalids.[4] Nígbà ti o wà ní ilé-ìwé Quincy High School, o ko létà si òpòlopò òsèrébìnrin fún àwòrán wón ti wón jàn ní oùntè, ìdáhùn ti òsèrébìnrin Hazel Dawn fún létà rè rú lókàn sókè láti di Òsèrébìnrin. Bí o tilè jé wípé bàbá rè n se iyè méjì nígbà síse rere rè gégé bí òsèré, o fi igbagbo mú Ruth lo sí ilé-ìwé American Acedemy of Dramatic Art ti o wà ní New York ni odun 1914.
Isé rè
àtúnṣeNi odún 1915, Gordon farahan ní ere kan ti wón se nípa Vernon and Irene Castle. Ni odún kanáà, o se eré ninú filmu Peter Pan.[5]
Ni odun 1918, Gordon àti Gregory Kelly seré ninú filmu tí apèlé rè jé Seventeen Ni odun 1920, Gordon lo sí ilé ìwòsàn kan ní ìlú Chicago níbí tí wón ti kan egungun esè rè ti wón sì ti to padà, wón se yí láti mú ki esè rè to wó télè dúró.[6]
Àwon Ìtókasí
àtúnṣe- ↑ "Ruth Gordon - Biography, Movies, Plays, & Facts". Encyclopedia Britannica. 1985-08-28. Retrieved 2022-08-23.
- ↑ "Who was Ruth Gordon? Everything You Need to Know". Famous People in the World. 1946-12-03. Retrieved 2022-08-28.
- ↑ "Clara Louise Jones Webb (1886-1970)". Find a Grave Memorial. 1970-10-31. Retrieved 2022-08-28.
- ↑ worldcat.org https://www.worldcat.org/issn/0024-3019. Retrieved 2022-08-28. Missing or empty
|title=
(help) - ↑ "Ruth Gordon". Wikipedia. 2001-10-10. Retrieved 2022-08-28.
- ↑ "The Day Ruth Gordon Broke Both Her Legs!". Coffee With Jeff. 2021-03-28. Archived from the original on 2022-08-28. Retrieved 2022-08-28.