Ruth Ndulu Maingi tí a bí ní ọjọ́ kejìlélógún Osù kàrún Ọdún 1983, jẹ́ òṣèré orílẹ̀ ède Kenya kan . Ó jẹ́ olókìkí fún àwọn ipa tí ó ti kó nínú àwọn eré oníse 18 Hours, The Distant Boat and Midlife Crisis.

Ruth Maingi
Ọjọ́ìbíRuth Ndulu Maingi
Ọjọ́ kejìlélógún Osù kàrún Ọdún 1983
Machakos, Kenya
Orílẹ̀-èdèKenyan
Ẹ̀kọ́Kathiani High School
Township Muslim Primary School
Iṣẹ́Òsèré
Ìgbà iṣẹ́Ọdún 2007–di àsìkò yí

Ìgbésí ayé rẹ̀

àtúnṣe

A bí ní ọjọ́ kejìlélógún Osù kàrún Ọdún 1983 ní ìlú Machakos, orílẹ̀ ède Kenya tí ó sì jẹ́ ẹ̀ẹ̀kẹ̀rin nínú ọmọ ìyá mẹ́fà. Ó lọ sí Kathiani High School àti Township Muslim Primary School ní Machakos fún ẹ̀kó rẹ̀. Ó parí ìwé-ẹ̀kọ́ gíga ní ẹ̀ka ìṣèdúró (insurance) lẹ́yìn ilé-ìwé gíga.

Iṣẹ́

àtúnṣe

Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí oníjó. Síbẹ̀, ó padà lọ se iṣẹ́ ìse láti ní isẹ́ kan. Ó sì darapọ̀ mọ́ Kenya National Theatre Performing Arts School fún ọdún méjì. Ní ọdún 2007, ó darapọ̀ mọ́ Kigezi Ndoto Musical Theatre Performances. Lẹ́yìn náà ní ọdún 2008, ó lọ sí orílẹ̀ ède India ó sì kópa Sauti Kimya ati Githa .

Ní ọdún 2011, ó ṣe eré oníse àkọ́kọ́ rẹ̀ pẹ̀lú eré "The Marshal of Finland" . Ní ọdún kan náà, wọ́n yàn án fún ipa aṣáájú nínú járá amóhùnmáwòrán Lies that Bind, èyítí ó ṣì jẹ́ àkọ́kọ́ eré amóhùnmáwòrán rẹ̀. Nínú járá ńà, ó kó ipa 'Salome', ìyàwó kẹta àti ìfẹ́ òtítọ́ Richard Juma, àti ìyàwó kẹta. Lẹ́yìn náà ní ọdún 2013, ó kópa nínú eré olókìkí Swahili "Mama Duka pẹ̀lú ipa orúko eré náà. Fún ipa rẹ̀, wọ́n dáa lọ́lá ní bi ayẹyẹ 2014 Africa Magic Viewers Choice Awards .

Ó kó ipa pàtàkì gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni nínú járá amóhùnmáwòrán "The Team" pẹ̀lú Media Focus on Africa tí Dreamcatcher ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀. Ní ọdún 2014, ó kópa nínú àwọn eré méjì: The Next East African Film Maker àti Orphan . Ní ọdún 2018, ó ṣe àkọ́kọ́ eré Nollywood pẹ̀lú eré "Family" tí Lancelot Imasuen kọ́kọ́ ṣe adarí rẹ̀.

Eré tí ó ti kópa

àtúnṣe
Year Film Role Genre Ref.
2012 The Marshal of Finland Maria Film
2013 Mama Duka Mama Duka TV Series short
2013 The Distant Boat Ruth Malombe Film
2015 Fundi-Mentals Film
2017 18 Hours Film
2018 Family First Film
2019 The System Rachel TV Series
2020 Lies that Bind Salome TV Series
2020 Midlife Crisis Gigi, Stylist Film

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe