Sánmọ̀
Sánmọ̀ tabí Ojú Ọ̀run jẹ́ gbogbo ohun tí ó wà lókè Ilẹ̀ níbi tí ohun bí Kùrukùru, Oòrùn, Òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ti ń yọjú wo ilẹ̀ lásìkò ìkọ̀ọ̀kan wọn. Ní inú ìmọ̀ ojú-ọ̀run, sánmọ̀ yí ni wọ́n ń pè ní ahòho, níbi tí oòrun, òṣùpá, àti àwọn ìràwọ̀ ti dàbí ẹni wípé wọ́n ń rọ̀ kiriká ọ̀run fúra rẹ̀,ní ọ̀gangan ilẹ̀.
Ọ̀nà tí sánmọ̀ pín sí
àtúnṣeSánmọ̀ tàbí ojú-_ọ̀run yí náà pín sí ọ̀nà méjì. Àkọ́kọ́ ni kùrukùru, èyí jẹ́ ìpele akọ́kọ́ àti ohun tí ó bo ojú-ọ̀run gan an fúra rẹ̀. Èkejì ni ahòho ọ̀run, ní i tí àwọn ìràwọ̀,Oòrùn , ati Òṣùpá ti ń yọjú lásìkò wọn gbogbo.[1] Lọ́pọ̀ ìgbà, kùrukùru ojú sánmọ̀ ni ó súnmọ́ ilẹ̀ jùlọ tí ó jẹ́ wípé bí a bá gbójú sókè, oun ni akọ́kọ́ máa rí.
Àwọn àríwòye sánmọ̀
àtúnṣeNí ojú mọmọ tàbí ní àsìkò ọ̀sán, ojú sánmọ̀ sába ma ń ní àwọ̀ búlúù tàbí yẹ́lò tí Oòrùn yóò sì tàn kálẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ tí a kò fi ní nílò iná tabí ihun kan mìíràn tí a lè fi òye rẹ̀ ríran ju òye ọjọ́ lọ. Bí ó ti di àṣálẹ́, sánmọ̀ yóò dúdú kẹlẹ kẹlẹ, ní èyí tí ilẹ̀ náà yóò dúdú pẹ̀lú nítorí ìmọ́lẹ̀ sánmọ̀ ni ìmọ́lẹ̀ ilẹ̀. Ní àsìkò yí, gbogbo ohun alàyé pátá ni wọn yóò nílò ohun tí ó lè jẹ́ gẹ́gẹ́ bí òye tàbí iná tí yóò ms fi wọ́n mọ̀nà. Àwọn àsìkò yí ni òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀ yóò yọ tí wọn yóò sì tànmọ́lẹ̀ sí orí ilẹ̀.[2][3][4][5].
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Baird, J. C., & Wagner, M. (1982). The moon illusion: I. How high is the sky? Journal of Experimental Psychology: General, 111, 296-303.
- ↑ John Tyndall (December 1868). "On the Blue Colour of the Sky, the Polarization of Skylight, and on the Polarization of Light by Cloudy Matter Generally". Proceedings of the Royal Society 17: 223–233. Bibcode 1868RSPS...17..223T. doi:10.1098/rspl.1868.0033. JSTOR 112380.
- ↑ Lord Rayleigh (June 1871). "On the scattering of light by small particles". Philosophical Magazine 41, 275: 447–451.
- ↑ J.G. Watson (June 2002). "Visibility: Science and Regulation". J. Air & Waste Manage. Assoc 52 (6): 628–713. doi:10.1080/10473289.2002.10470813. PMID 12074426. https://scholar.google.com/scholar?hl=en&lr=&q=cache:aulPiqN6uTUJ:www.awma.org/journal/pdfs/2002/6/Crit_Review.pdf+. Retrieved 19 April 2007.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ Gibbs, Philip (May 1997). "Why is the sky Blue?". Usenet Physics FAQ. Retrieved 11 December 2012.