Sòbìà
Sòbìà, tí a tún mọ̀sí ààrùn sòbìà (GWD), jẹ́ àkóràn ti àràn sòbìà.[1] Ènìyàn maa ń ṣàkóràn rẹ̀ bí ó bá mu omi tí ó ní eṣinṣin omi àkóràn aràn sòbìà ọmọ kòkòrò.[1] Lákọkọ́ kòsí àwọn aamì.[2] Lẹ́hìn ọdun kan, ènìyàn yóòní ìgbóná ara nígbà tí òbí aràn bá fa ọgbẹ́ sí àwọ̀, pàápàá lábẹ́ ẹsẹ̀.[1] Aràn yó̀o jáde lára lẹ́hìn oṣù mélòó.[3] Ní àkókò yíì, ó lè nira láti rìn tàbí ṣiṣẹ́.[2] Kò wọ́pọ̀ kí àrùn yí ó mú ikú dání.[1]
Sòbìà | |
---|---|
Lílo igi ìṣaná láti yọ sòbìà kúrò lẹ́sẹ̀ ènìyàn | |
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta | |
ICD/CIM-10 | B72. B72. |
ICD/CIM-9 | 125.7 125.7 |
DiseasesDB | 3945 |
Àwọn ènìyàn nìkan ni irúfẹ́ ẹranko tí àràn sòbìà ń mú.[2] Àràn yíì a fẹ̀ ní ìwọ̀n mìlímítà méjì àwọn tí ó ti dàgbà nínu wọn a maa gùn tó 60 sí 100 sẹ̀ntìmítà(àwọn akọ ló kúrú jù).[1][2] Láìsí lára àwọn ènìyàn, àwọn ẹyin lè pẹ́ tó oṣụ̀ mẹ́ta.[4] Lámilámi gbọ́dọ̀ jẹ wọ́n ṣáájú èyí .[1] Ọmọ inú lámilámi lè wà láyé fún bí oṣù mẹ́rin.[4] Èyí nipé àrùn yíì gbọ́dọ̀ wáyé lọ́dọ́ọdún lára àwọn ènìyàn láti wá ní agbegbè.[5] Ìmọ àrùn yíì lè wáyé nìkan nípa àwọn àpẹẹrẹ àti ààmì.[6]
Ìdẹ́kun lè wáyé bí a bá tètè ṣàwarí àrùn àti àìgba ẹni náà láyè láti kó egbò wọ inú omi mímu.[1] Àwọn ipa mìíràn ni: ìráàyè sí omi tómọ́ gaara àti sísẹ́ omi bí kò bámọ́́.[1] Síṣẹ́ nípa lílo aṣọ náà to.[3] Omi tí ó ti ní àbàwọ́n ni a lè tọ́jú nípa lílo kẹ́míkà tí a ńpè ní temefos láti pa ọmọ kòkòrò.[1] Kòsí egbògi tàbí òògùn ìtọjú tí o ṣiṣẹ́ lòdì sí àrùn náà.[1] A lè yọ àràn náà kúrò díẹ̀díẹ̀ láárin ọ̀sẹ̀ díẹ̀ nípa yíyí lóri igi.[2] Ọgbẹ́ ti àràn tí o ń jáde yi ńfa ni o lè ní kòkòrò àkóràn.[2] Ìrora lè tẹ̀siwajú fún àwọn oṣù díẹ̀ lẹ́hìn tí a yọ aràn kúrò.[2]
Ní 2013 ìṣẹlẹ̀ 148 àrùn náà ni a jábọ̀ rẹ̀.[1] Èyí wálẹ̀ sí 3.5 mílíọ́nù ìṣẹlẹ̀ ní 1986.[2] Orílẹ̀ èdè mẹ́rin péré ni ó wà ní Áfíríkà, èyí tí ó wálẹ̀ láti orílẹ̀ èdè 20 ní àwọn ọdún 1980.[1] Orílẹ̀ èdè tí ó ní jù ni Gúúsù Sudan.[1] Ó jọ bí àkọkọ́ kòkòrò àkóràn àrùn láti yọkúrò.[7] Àrùn sòbìà tì wà láti ìgbà àtijọ́.[2] A sọ nípa rẹ̀ nínu ègbògi Íjíbítì Ebers Papyrus, láti 1550 BC.[8] Orúkọ tí a ń pè ní dracunculiasis jẹyọ láti Látínì "Ìdojúkọ pẹ̀lú lámilámi kékeré",[9] nígbà tí orúkọ "sòbìà" jẹyọ nígbà tí àwọn òyìnbó rí àrùn náà ní Guinea etí òkun Ìwọ̀ oorùn Áfíríkà ní 17th ọgọ́rùn ọdún.[8] Irúfẹ́ ọ̀wọ́ tí àwọn sòbìà ńfa àrùn lára àwọn ẹranko.[10] Èyí kò jọ pé o ń ran ènìyàn.[10] A pin sí ìpele àrùn ipa ọ̀nà orùn tí a gbàgbé.[11]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.00 1.01 1.02 1.03 1.04 1.05 1.06 1.07 1.08 1.09 1.10 1.11 1.12 "Dracunculiasis (guinea-worm disease) Fact sheet N°359 (Revised)". World Health Organization. March 2014. Retrieved 18 March 2014.
- ↑ 2.0 2.1 2.2 2.3 2.4 2.5 2.6 2.7 2.8 Greenaway, C (Feb 17, 2004). "Dracunculiasis (guinea worm disease).". CMAJ : Canadian Medical Association journal = journal de l'Associationmedicalecanadienne 170 (4): 495–500. PMC 332717. PMID 14970098. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=332717.
- ↑ 3.0 3.1 Cairncross, S; Tayeh, A; Korkor, AS (Jun 2012). "Why is dracunculiasis eradication taking so long?". Trends in parasitology 28 (6): 225–30. doi:10.1016/j.pt.2012.03.003. PMID 22520367.
- ↑ 4.0 4.1 Junghanss, Jeremy Farrar, Peter J. Hotez, Thomas (2013). Manson's tropical diseases. (23rd edition ed.). Oxford: Elsevier/Saunders. p. e62. ISBN 9780702053061. http://books.google.ca/books?id=GTjRAQAAQBAJ&pg=RA1-PA62.
- ↑ "Parasites - Dracunculiasis (also known as Guinea Worm Disease) Eradication Program". CDC. November 22, 2013. Retrieved 19 March 2014.
- ↑ Cook, Gordon (2009). Manson's tropical diseases. (22nd ed. ed.). [Edinburgh]: Saunders. p. 1506. ISBN 9781416044703. http://books.google.ca/books?id=CF2INI0O6l0C&pg=PA1506.
- ↑ "Guinea Worm Eradication Program". The Carter Center. Carter Center. Archived from the original on 2015-03-11. Retrieved 2011-03-01.
- ↑ 8.0 8.1 Tropical Medicine Central Resource. "Dracunculiasis". Uniformed Services University of the Health Sciences. Archived from the original on 2015-06-14. Retrieved 2008-07-15.
- ↑ Barry M (June 2007). "The tail end of guinea worm — global eradication without a drug or a vaccine". N. Engl. J. Med. 356 (25): 2561–4. doi:10.1056/NEJMp078089. PMID 17582064. Archived from the original on 2010-07-06. https://web.archive.org/web/20100706035742/http://content.nejm.org/cgi/content/full/356/25/2561. Retrieved 2015-09-02.
- ↑ 10.0 10.1 Junghanss, Jeremy Farrar, Peter J. Hotez, Thomas (2013). Manson's tropical diseases. (23rd edition ed.). Oxford: Elsevier/Saunders. p. 763. ISBN 9780702053061. http://books.google.ca/books?id=GTjRAQAAQBAJ&pg=PA763.
- ↑ "Neglected Tropical Diseases". cdc.gov. June 6, 2011. Retrieved 28 November 2014.