Sa'adu Abubakar
Muhammadu Sa'ad Abubakar <sup id="mwDg">CFR</sup> ( Arabic </link> ) ( ni won bí ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù keje ọdún 1956,) ó jẹ́ Sultan 20th ti Sokoto.[1][2] Gẹ́gẹ́ bí Sultan ti Sokoto, wọ́n kà á sí aṣáájú ẹ̀mí ti àwọn Mùsùlùmí Nàìjíríà.
Abubakar IV CFR | |
---|---|
Amir al-Mu'minin
| |
Predecessor | Muhammadu Maccido |
Successor | No specific Heir apparent in Sokoto Caliphate |
Born | 24 Oṣù Kẹjọ 1956 Sokoto, Northern Region, British Nigeria |
Abubakar ni àrólé sí ìtẹ́ ọ̀rúndún méjì tí baba-ńlá rẹ, Sheikh Usman Dan Fodio (1754–1817) tí ó jẹ́ adarí ilé-ìwé Màlíìkì ti Islam àti ẹka Qadiri ti Sufism .
Ìgbésí ayé Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀
àtúnṣeÌdílé
àtúnṣeA bí Sa'adu Abubakar ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù keje ọdún 1956, ní Sokoto . Òun ni ọmọ àbíkẹ́hìn tí Sultan kẹtàdínlógún, Sir Siddiq Abubakar III, tí ó ṣe Sultanate fún àádọta ọdún.[3]
Ẹ̀kọ́
àtúnṣeSa'adu Abubakar lo sí ilé ìwé gíga Barewa tó wà ní Zaria, ó sì tẹ̀síwájú sí Nigeria Defence Academy ní ọdún 1975 níbi tí ó ti jẹ́ ẹgbẹ́ kejìdínlọ́gún ti Regular Course.[4]
Iṣẹ́ Ológun
àtúnṣeAbubakar ni a fún ní àṣẹ Kejì Lieutenant ní ọdún 1977 ó sì ṣiṣẹ́ ní elite Armored Corps. Ó jẹ́ olórí ẹ̀ka ààbò ààrẹ ti Armored Corps tí ó ń ṣọ́ alákòóso ológun nígbà náà, Ọ̀gágun Ibrahim Babangida ní òpin 1980. Abubakar tún ṣe olórí battalion kan tí àwọn olùtọ́jú àláfíà Áfíríkà ní Chad ní ìbẹrẹ ọdún 1980, gẹ́gẹ́bí apákan ti ológun ti Organisation of African Unity àti pé ó jẹ́ọ́fíísà líásíìnù fún Economic Community of West African States (ECOWAS) ní àárín 1990s.
A fun ní àṣẹ ọ̀gágun apàṣẹ 241 Recce Battalion, Kaduna ní ọdún 1993. Láti ọdún 1995 sí 1999, ó jẹ́ ọ́fíísà líásíìnù ECOWAS àti ọ̀gágun apàṣẹ, 231 Thank Battalion (ECOMOG Operations) ní Sierra Leone, láti ọdún 1999 sí 2000. Láti ọdún 2003 sí 2006, ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi Defence Attaché sí orílẹ̀-èdè Pakistan ( tí ó gbà fún Iraq, Sáúdí Arábíà àti Afghanístàn) ó sì fẹ̀yìntì lenu iṣẹ́ gẹ́gẹ́bí brigadier general in 2006.
Sultan ti Sokoto
àtúnṣeNi ọjọ́ kejì Oṣù kọkànlá ọdún 2006, Abubakar gorí ìtẹ́, lẹ́yìn ikú arákùnrin rẹ̀, Muhammadu Maccido, tí ó kú ní ọkọ̀ òfurufú ADC Airlines 53 .
Àwọn oyè àti àmì ẹ̀yẹ
àtúnṣeGẹ́gẹ́bí Sultan ti Sokoto, Abubakar jẹ́ olórí ti àṣẹ Sufi Qadiriyya, èyítí ó jẹ́ ipò Mùsùlùmí pàtàkì jùlọ ní Nàìjíríà àti ọ̀gá sí Emir ti Kano, olórí ti ìlànà Sufi Tijjaniyya jùlọ jùlọ. Òun tún jẹ́ olórí ẹgbẹ́ Jama'atu Nasril Islam (Society or the Support of Islam – JNI), àti ààrẹ àgbà fún Ìgbìmọ̀ gíga jùlọ ti Nàìjíríà fún Àwọn ọ̀ràn Ìsìláàmù (NSCIA). [5]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ CFR, mni--sultan-sokoto The Muslim 500: "Amirul Mu’minin Sheikh as Sultan Muhammadu Sa’adu Abubakar" Archived 25 June 2014 at the Wayback Machine. retrieved 15 May 2014
- ↑ "The Quintessential Chief Imam of Lagos - Muslim News Nigeria". muslimnews.com.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-09-21. Retrieved 2024-08-22.
- ↑ "The Sokoto Caliphate and its legacies". dawodu.com. Archived from the original on 4 March 2016. Retrieved 2 January 2018. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Chiama, Paul. "From Barracks To Royalty: 6 Prominent Ex-Military Officers Now Royal Fathers". Leadership Nigeria. Archived from the original on 25 July 2015. Retrieved 25 July 2015. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Paden, John N. (2008). Faith and politics in Nigeria. Washington, DC: US Institute of Peace Press. pp. 32f. ISBN 978-1-60127-029-0.