Salawa Abeni

Akọrin obìnrin

'Sàláwà Àbẹ̀ní Álídù ni wọ́n bí ní (5 May 1961), ó jẹ́ olórin ọmọ orílẹ̀ èdè Nàj̀íríà.[1] Ó wá láti Ìjẹ̀bú etí-Òsà nị́ ìpínlẹ̀ Ògùn. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin wákà kikọ nígbà tí ó ṣe orin tó sọọ́ di ìlú-mọ̀ọ́ka tí ó pè àkọ́lé rẹ̀ ní Late General Murtala Ramat Mohammed, ní ọdún 1976, lábẹ́ ilé iṣẹ́ (Leader Records). Orin yìí ni ó jẹ́ orin àkọ́kọ́ tí obìnrin yóò kó jáde lédè Yorùbá tí ó sì tà iye tí ó lé ní Mílíọ́nù kan ní ilẹ̀ Nàìjíríà.

Sàláwà Àbẹ̀ní
Queen of Waka
Orúkọ àbísọSalawa Abeni Alidu
Ọjọ́ìbí5 Oṣù Kàrún 1961 (1961-05-05) (ọmọ ọdún 63)
Epe, Lagos State
Ìbẹ̀rẹ̀Epe
Irú orinWaka music
Occupation(s)Musician
Years active(1975 –present)
LabelsLeader records, Kollington, Alagbada

Àbẹ̀ní kò dá iṣẹ́ orin rẹ̀ dúró lábẹ́ ilé-iṣẹ́ 'Leader' títí di ọdún 1986, nígbà tí ó fòpin sí ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ẹni tí ó nilé iṣẹ́ Leader Records, ìyẹn Lateef Adepoju. Ó fẹ́ Olóyè Kollington Àyìnlá, tí ó sì dara pọ̀ mọ́ ilé iṣẹ́ ọkọ rẹ̀ tí ó sì wà pẹ̀lú ilé iṣẹ́ náà títí di ọdún 1994.

 Aláàfin Ọ̀yọ́, Ọba Làmídì Adẹ́yẹmí ní ọdún 1992 dé Sàláwà Àbẹ̀ní ládé "Queen of Waka Music".[2] Orin  Wákà ní ó jẹ́ orin tí ẹ̀sìn Islam kópa tó pọ̀ nínú rẹ̀  (Islamic-influenced) tí a fi àdàpọ̀ orin ìbílẹ̀ èdè Yorùbá gbé kalẹ̀. Ṣáájú Àbẹ̀ní Sàláwà,  Batile Àlàkẹ́ ni ó kọ́kọ́ kọ orin náà tí ó sì sọọ́ di àgbọ́ málè lọ fún àwùjọ Yorùbá; ẹ̀ka orin yìí (Waka) ti wà tipẹ́ ṣáájú  jùjú àti fuji.

Rúkè rúdò lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀

àtúnṣe

Nị́gbà tí Sàláwà ń bá ilé iṣẹ́ ìròyìn kan sọ̀rọ̀. Oríṣiríṣi rúkè-rúdò ló wáyé nígbà tí gbajú-gbajà olórin náà ń gba àwọn ènìyàn níyànjú láti yàgò fún ìwà "Akọ sí Akọ" tí ó sì di ẹ̀bi ìwà náà lé ìwà lílò ògùn olóró lórí.[3] Ọ̀pọ̀ àwọn lámèyítọ́ ló sọ wípé Àbẹ̀ní sọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú "Àìmọkan".[4] Ṣùgbọ́n arábìnrin kan Ọlájùmọkẹ́ Òrìságunà tí ó jẹ́ onípolówó ló tún fan rere ọ̀rọ Sàláwà wípé: 'lábẹ́ òfin ilẹ̀ Nàìjíríà tí ó sì tún dá lórí òfin ilẹ̀ Bríténì wípé "ìbálòpọ̀ akọsákọ jẹ́ ìwà ọ̀daràn tí ó sì tọ́ sí ìjìyà lábẹ́ òfin ilẹ̀ Nàìjíríà láti ọmọ ọdún mẹ́rìnlá lọ sókè  yálà kí wọ́n t̀i wọ́n mọ́lé tàbí kí wọ́n yẹjú wọn". Èyí jẹyọ nínú fídíò rẹ̀ tó fi léde nínú àpo YouTube Olajumoke Sauce 7:  ní oṣù Kejì ọdún 2018.[5] 

Àwọn orin tó ti kọ[6]

àtúnṣe
  • Late Murtala Muhammed (Leader, 1976)
  • Iba Omode Iba Agba (Leader, 1976)
  • Shooting Stars (Leader, 1977)
  • Ijamba Motor (Leader, 1978)
  • Okiki Kan To Sele/Yinka Esho Esor (Leader, 1979)
  • Orin Tuntun (Leader, 1979)
  • Irohin Mecca (Leader, 1980)
  • Ile Aiye (Leader, 1980)
  • Omi Yale (Leader, 1980)
  • Ija O Dara (Leader, 1981)
  • Ikilo (Leader, 1981)
  • Enie Tori Ele Ku (Leader, 1982)
  • Challenge Cup ’84 (Leader, 1983)
  • Adieu Alhaji Haruna Ishola (Leader, 1985)
  • Indian Waka (Kollington, 1986)
  • Ife Dara Pupo (Kollington, 1986)
  • Mo Tun De Bi Mo Se Nde (Kollington, 1986)
  • Awa Lagba (Kollington, 1987)
  • Abode America (Kollington, 1988)
  • Ileya Special (Kollington, 1988)
  • I Love You (Kollington, 1988)
  • We Are The Children (Kollington, 1989)
  • Maradonna (Kollington, 1989)
  • Candle (Kollington, 1990)
  • Experience (Alagbada, 1991)
  • Congratulations (Alagbada, 1991)
  • Cheer Up (Alagbada, 1992)
  • Waka Carnival (Alagbada, 1994)
  • Beware cassette (Sony, 1995)
  • Live In London ’96 cassette (Emperor Promotions, 1996)
  • Appreciation cassette (Sony, 1997)
  • with Barrister Evening Of Sound cassette (Zmirage Productions, 1997)
  • Good Morning In America (Alagbada, 1999)

Àwọn ìtọ́ka sí

àtúnṣe
  1. Denselow, Robin (2001-07-20). "Queen Salawa Abeni". The Guardian. https://www.theguardian.com/culture/2001/jul/20/artsfeatures10. Retrieved 23 January 2010. 
  2. (7 July 2016). 'Biography of Alaafin Of Oyo, Oba Lamidi, Olayiwola Atanda Adeyemi III'. Uche & Maureen. (Nigerian Biography). (Nigeria)
  3. (28 March 2018). 'Salawa Abeni upholds indigenous traditional music'. P.M. News. (Nigeria).
  4. (1 April 2018). "‘Stay away from homosexuality’ local Nigerian musician advises colleagues". nostrings.com. (Nigeria)
  5. (February 21, 2018). 'Olajumoke Sauce 7: Trends and Acceptance featuring Actor Yemi Blaq'. YouTube.
  6. "Abeni, Queen Salawa." Encyclopedia of Popular Music, 4th ed.. Oxford Music Online. Oxford University Press, accessed February 17, 2016,