Salman Mazahiri
Ọ̀gbẹ́ni Salman Mazahiri (tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹwàá oṣù kẹwàá ọdún 1946 – ó kú lógúnjọ́ oṣù keje ọdún 2020) jẹ́ ọ̀mọ̀wé ọmọ orílẹ̀ èdè India tí ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Gíwá ilé-ẹ̀kọ́ gíga Mazahir Uloom Jadeed.
Ìgbà èwe àti ẹ̀kọ́ life
àtúnṣeWọ́n bí Mazahiri lọ́jọ́ kẹwàá oṣù kẹwàá ọdún 1946. Nígbà tó wà lọ́mọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ó wọ ilé - ẹ̀kọ́ Mazahir Uloom, Saharanpur lọ́dún 1962 (1381 AH), ó sì kàwé gboyè ní 1386 AH. Ó kàwé gboyè nínú imọ̀ Sahih Bukhari pẹ̀lú Muhammad Zakariyya Kandhlawi, Sahih Muslim, Sunan Nasai, Tirmidhi àti Munawwar Hussain, Sunan Abu Dawud pẹ̀lú Muzaffar Hussain àti Al-Aqidah al-Tahawiyyah pẹ̀lú Muhammad Asadullah.[1] Ó kàwé gboyè nínú imọ̀ studied Mishkat al-Masabih pẹ̀lú Muzaffar Hussain títí di ipele "ẹsẹ̀ gbòógì" ("major sins") ó sì parí rẹ̀ pẹ̀lú Muhammad Yunus Jaunpuri.[2]
Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Talha Kandhlawi.[3]
Iṣẹ́
àtúnṣeMazahiri bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní Mazahir Uloom lọ́dún 1968. Ó kọ́ Tafsir al-Jalalayn lọ́dún 1972,nígbà tí ó di ọdún 1976 ó di ọ̀jọ̀gbọ́n hadith ní ilé-ẹ̀kọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn Àfáà níbi tí ó ti ń kọ́wọ̀n ní imọ̀ Mishkat al-Masabih.[2][1] Nígbà tí ó di ọdún 1992,àwọn ìgbìmọ̀ aláṣẹ Mazahir Uloom Jadeed yàn án ní Gíwá ilé-ẹ̀kọ́ náàa. Ó sì gorí òye náà lọ́jọ́ lọ́jọ́ ọgbọ́n oṣù keje ọdún 1996.[1][4] Talha Kandhlawi yàn án gẹ́gẹ́ bí adarí (Sajjada Nashin) ti khanqah ti Muhammad Zakariyya Kandhlawi.[3]
Ní ọdún 2007, Mazahiri tako àbá ìgbìmọ̀ àpapọ̀ Central Madrasa Board ní India.[5][6] Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ All India Muslim Personal Law Board àti Darul Uloom Nadwatul Ulama.[2]
Ikú rẹ̀
àtúnṣeMazahiri kú lógúnjọ́ oṣù keje ọdún 2020.[4][7] Ààrẹ Jamiat Ulama-e-Hind, Arshad Madani kẹ́dùn ikú Mazahiri gẹ́gẹ́ bí àjálù aburú fún gbogbo Musulumi India.[8]
Ebí
àtúnṣeMazahiri jẹ́ àna Muhammad Zakariyya Kandhlawi.[9] Olórí Tablighi Jamat Muhammad Saad Kandhlavi jẹ́ àna Mazahiri.[10]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 1.2 Abdullah Khalid Qasmi Khairabadi. "مولانا سید محمد سلمان مظاہری حیات مستعار کی ایک جھلک" [A biographical sketch of Salman Mazahiri]. millattimes.com (in Urdu). Retrieved 21 July 2020.
- ↑ 2.0 2.1 2.2 Yusuf Shabbir (20 July 2020). "Obituary: Sayyid Mawlānā Muḥammad Salmān Maẓāhirī (1365/1946 – 1441/2020)". islamicportal.co.uk. Retrieved 22 July 2020.
- ↑ 3.0 3.1 Ajaz Mustafa (September 2019). "آہ! حضرت مولانا محمد طلحہ کاندھلویؒ بھی داغ مفارقت دے گئے" (in Urdu). Bayyināt (Jamia Uloom-ul-Islamia). https://www.banuri.edu.pk/bayyinat-detail/%D8%A2%DB%81-%D8%AD%D8%B6%D8%B1%D8%AA-%D9%85%D9%88%D9%84%D8%A7%D9%86%D8%A7-%D9%85%D8%AD%D9%85%D8%AF-%D8%B7%D9%84%D8%AD%DB%81-%DA%A9%D8%A7%D9%86%D8%AF%DA%BE%D9%84%D9%88%DB%8C-%D8%A8%DA%BE%DB%8C-%D8%AF%D8%A7%D8%BA-%D9%85%D9%81%D8%A7%D8%B1%D9%82%D8%AA-%D8%AF%DB%92-%DA%AF%D8%A6%DB%92. Retrieved 20 July 2020.
- ↑ 4.0 4.1 "مولانا سلمان صاحب مظاہری کی رحلت عالم اسلام بالخصوص جامعہ مظاہر علوم سہارنپور کے لئے ناقابل تلافی خسارہ". AsreHazir. 20 July 2020. Archived from the original on 21 September 2021. https://web.archive.org/web/20210921170654/https://asrehazir.com/hydnews-207/amp/. Retrieved 20 July 2020.
- ↑ Muhamamdullah Khalili Qasmi (15 May 2007). "'Central Madrasa Board' is Unacceptable: 3500 Madrasa Delegates Take Unanimous Decision". deoband.net. Archived from the original on 18 September 2020. Retrieved 20 July 2020.
- ↑ Muslim India. 2007. p. 32. https://books.google.com/books?id=KHYMAQAAMAAJ&q=maulana+salman+mazahiri. Retrieved 20 July 2020.
- ↑ "مولانا سید محمد سلمان مظاہری اب اس درافانی سے رحلت فرما گئے | روزنامہ نوائے ملت". 20 July 2020. Archived from the original on 20 July 2020. Retrieved 20 July 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "مولانا سلمان مظاہری کا سانحہ ارتحال ہندوستانی مسلمانوں کے لئے بڑا حادثہ: مولانا ارشد مدنی". Qaumi Awaz. 21 July 2020. https://www.qaumiawaz.com/national/maulana-salman-mazaheris-demise-is-a-big-tragedy-for-indian-muslims-maulana-arshad-madani.
- ↑ Fuzail Ahmad Nasiri (15 August 2019). "وائے افسوس! پیر محمد طلحہ بھی رخصت ہو گئے". Baseerat News (Dailyhunt).
- ↑ "بڑی خبر : مولانا سعد کاندھلوی کی کورونا رپورٹ نیگیٹیو!". millattimes.com (in Urdu). 18 April 2020. Retrieved 20 July 2020.