Samantha Biffot (tí a bí ní ọdún 1985) jẹ́ ònkọ̀tàn eré, olóòtú àti olùdarí eré ọmo orílẹ̀-èdè-Gàbọ̀n àti orílẹ̀-èdè Faransé.

Samantha Biffot
Ọjọ́ìbí1985 (ọmọ ọdún 38–39)
Paris
Orílẹ̀-èdèGabonese-French
Iṣẹ́Screenwriter, film producer, film director
Notable workThe African Who Wanted to Fly (2016)

Ọ̀rọ̀ ayé rẹ̀ àtúnṣe

A bí Biffot ní Ìlú Párìsì ní ọdún 1985. Ó jẹ́ aláṣá púpọ̀ nítorí liló igbà èwe rẹ̀ ní àwọn ìlú bíi Gàbọ̀n, Gúúsu kòríà àti Fránsì, èyí ti ́ó padà nípa lóri ṣíṣe iṣẹ́ òṣèré rẹ̀.[1].Ó kẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ìwé École Supérieure de Réalisation Audiovisuelle, ìyẹn ní Ìlú Párìsi ńibití ó ti gba oyè-ẹ̀kó nínu ìmọ̀ sinimá ṣíṣe ní ọdún 2007. Lẹ́hìn ìparí ẹ̀kọ́ rẹ̀, Biffot tún lọ kọ́ṣẹ́ bí ati ṣe ń ṣe eré tẹlifíṣọ̀nù àti sinimá àgbéléwò ní orílẹ̀-èdè Fránsì bákan náà. Biffot padà sí orílẹ̀-èdè Gàbọ̀n ní ọdún 2010 níbi tí òun pẹ̀lú Pierre-Adrien Ceccaldi ti dìjọ dá ilé-iṣẹ́ agbéréjáde kan sílẹ̀ táa pè ní “Princesse M Production." Ní ọdún 2011, ó ṣètò àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún eré kíkọ, ṣíṣe olóòtú àti yíya àwòrán eré lásìkò ayẹyẹ International Festival of School Courts tí ó wáyé ní ìlú Libreville .[2]

Ní ọdún 2013, eré tẹlifíṣọ̀nù rẹ̀ kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ L'Œil de la cité (The Eye of the city) gba àmì-ẹ̀ye fún eré tẹlifíṣònù tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ Afirika níbi ayẹyẹ Panafrican Film and Television Festival of Ouagadougou.[3] Eré náà dá lóri àwọn ìwà ọ̀daràn àti àwọn làásìgbò tí ó n dálẹ̀ sáàrin àwùjọ. Ó sọ di mímọ̀ wípé eré náà jẹ́ láti fi ṣe ìbádọ́gba eré Amẹ́ríkà kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Tales from the Crypt.[4] Ní ọdún 2016, Biffot ṣe àgbéjáde The African Who Wanted to Fly, tó dá lóri ìgbésí ayé Luc Bendza, ògbóǹtarìgì oní kung fu ní orílẹ̀-èdè Gàbọ̀n. Fíìmù náà gba àmì-ẹ̀yẹ eré-onítàn tí ó dára jù níbi ayẹyẹ Burundi International Film and Audiovisual Festival ti ọdún 2017.[5] ó sì tún jẹ́ àṣàyàn eré tí wọ́n wọ̀ níbi ayẹyẹ Internationales Dokumentarfilmfestival München àti ayẹyẹ African Film Festival tí ó wáyé ní ìlú New York.[6]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀ àtúnṣe

  • 2013: L'Œil de la cité (TV series)
  • 2016: The African Who Wanted to Fly (documentary)
  • 2016-2020: Parents mode d’emploi Afrique (TV series)
  • 2017: Taxi Sagat (TV series)
  • 2018: Kongossa telecom (TV series)
  • 2019: Sakho & Mangane (TV series)

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "Samantha Biffot, l’avenir d’un cinéma Africain à multiples facettes". Gabon Media Time (in French). 11 May 2018. Archived from the original on 28 September 2021. Retrieved 1 October 2020. 
  2. "Gabon : « Pas de cinéma à valeur internationale sans la rigueur et (...)". Gaboneco (in French). 23 September 2011. Archived from the original on 1 June 2019. Retrieved 1 October 2020. 
  3. "Palmarès de la 23ème édition du Fespaco - CLAP NOIR : cinémas et audiovisuels Africains". Clapnoir.org (in French). 3 March 2013. Retrieved 1 October 2020. 
  4. "Samantha Biffot, " L’œil de la cité " et le Fespaco". GabonReview (in French). 8 March 2018. Retrieved 1 October 2020. 
  5. "Samantha Biffot Biography". African Film Festival. Retrieved 1 October 2020. 
  6. "Samantha Biffot représentera le Gabon aux Africa Movie Academy Awards 2017". Gabon Celebrites (in French). 30 May 2017. Retrieved 1 October 2020. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde àtúnṣe