Samantha Mugatsia (tí a bí ní ọdún 1992) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Kẹ́nyà.

Samantha Mugatsia
Ọjọ́ìbí1992 (ọmọ ọdún 31–32)
Nairobi, Kenya
Orílẹ̀-èdèKenyan
Iṣẹ́Actress
Ìgbà iṣẹ́2018-present

Ìsẹ̀mí rẹ̀

àtúnṣe

A bí Mugatsia ní ọdún 1992. Ó jẹ́ ọmọ Grace Gitau. Ó dàgbà ní ìlú Nairobi, ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ẹgbẹ́ àyàn kan tí wọ́n pè ní The Yellow Machine.[1] Ó tún ti jẹ́ afẹwàṣiṣẹ́ nígbà kan rí.[2] Mugatsia kẹ́kọ̀ọ́ ìmòfin ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Catholic University of Eastern Africa, ṣùgbọ́n ó dáwọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀ dúró láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré rẹ̀. Ní Oṣù kọkànlá Ọdún 2016, ó pàdé olùdarí eré tí orúkọ rẹ̀ n ṣe Wanuri Kahiu, ẹnití ó pe Mugatsia láti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínu eré tuntun tí ó n gbèrò láti gbé jáde, Mugatsia náà síì faramọ.[3]

Ní ọdún 2018, Mugatsia kópa gẹ́gẹ́ bi Kena Mwaura, ọ̀kan lára àwọn olú-ẹ̀dá-ìtàn ti eré Rafiki. Ìtàn náà dá lóri ìwé-ìtàn Jambula Tree tí ònkọ̀wé ọmọ orílẹ̀-èdè Ùgándà kan kọ. Ní ìgbaradì fún ipa náà, Mugatsia ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbìyànjú láti ri dájú wípé yóó le ṣẹ̀tọ́ ipa náà pẹ̀lú irọ̀rùn.[3] Wọ́n fi òfin de fíìmù náà ní orílẹ̀-èdè Kẹ́nyà, nítorí wípé òfin orílẹ̀-èdè náà kò fàyè gba ìbálòpọ̀ láàrin àwọn ẹlẹ́yà kannáà. Rafiki jẹ́ àkọ́kọ́ fíìmù ti Kẹ́nyà tí ó jẹ́ wíwò níbi àwọn ayẹyẹ Cannes Film Festival.[4] Mugatsia gba àmì-ẹ̀yẹ òṣèrébìnrin tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ FESPACO ti ọdún 2019 tó wáyé ní ìlú Ouagadougou, orílẹ̀-èdè Bùrkínà Fasò fún bí ó ti ṣe kó ipa Kena.[5]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀

àtúnṣe
  • 2018: Rafiki gẹ́gẹ́ bi Kena Mwaura
  • 2018: L'invité

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

àtúnṣe