Sanusi Lamido Sanusi
Muhammadu Sanusi II tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Sanusi Lamido Sanusi tí wọ́n bí Ọjọ́ kọkànlélọ̀gbọ̀n oṣù keje ọdún 1961 (31 July 1961) jẹ́ Emir àná ti Ìlú Kánò tí Ìjọba Ìpínlẹ̀ Kano lábẹ́ ìṣàkóso Gómìnà Abdullahi Umar Ganduje rọ̀ lóyè lọ́jọ́ kẹsàn-án oṣù Kẹta ọdún 2020.[1] Lọ́jọ́ yìí kan náà ni ìjọba ìpínlẹ̀ Kano kéde Aminu Ado Bayero gẹ́gẹ́ bí i Emir tuntun fún ìlú Kano. Ọdún 2014 Lamido Sanusi ló gorí ìtẹ́ àwọn Babańlá rẹ̀, lẹ́yìn ikú Ọba Emir ìjẹ́ta, Ado Bayero.[2][3]
Muhammadu Sanusi II | |
---|---|
Reign | 8 June 2014 – 9 March 2020 |
Coronation | 7 February 2015 |
Predecessor | Ado Bayero |
Spouse | See
Sadiya Ado Bayero
Maryam Rakiya Sa'adatu Musdafa |
Issue | |
See
Aminu
Shaheeda Saddiqa Saliha Ashraf Muhammad Sanusi Khadija Aisha Husna Maryam Muhammad Inuwa | |
Full name | |
Sanusi Lamido Sanusi | |
House | Dabo |
Father | Aminu Sanusi |
Mother | Saudatu Hussain |
Born | 31 Oṣù Keje 1961 Kano, Northern Region, Federation of Nigeria |
Religion | Sunni Islam |
Ki o tó jọba, Sanusi jẹ́ ògbóǹtarìgì onímọ̀ nípa okoòwò àti Gómìnà Ilé Ìfowópamọ́-àgbà tí Nàìjíríà láti ọdún 2009 sí 2014,tí Ààrẹ àná, Goodluck Jonathan pàṣẹ kí ó dáṣẹ́ dúró látàrí owó kan tí Sanusi ṣẹnu bóró pé ó sọnù lápò ilé-iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ tí ó ń ṣe kòkárí epo lọ̀bì, NNPC.[4]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "BREAKING: Kano government appoints new emir to replace Sanusi". Premium Times Nigeria. 2020-03-09. Retrieved 2020-03-09.
- ↑ Bukar, Muhammad (2020-03-09). "BREAKING: Emir of Kano Muhammadu Sanusi dethroned". Daily Post Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-03-09.
- ↑ "Kano dethrones Emir Sanusi". Punch Newspapers. Retrieved 9 March 2020.
- ↑ "Special Report: Anatomy of Nigeria's $20 billion 'leak'" (in en). Reuters. 2015-02-06. https://www.reuters.com/article/us-nigeria-election-banker-specialreport-idUSKBN0LA0X820150206.