Sanusi Olusi
Ọba Sànúsí Olusi nígbà ayé rẹ̀ jẹ́ ọlọ́rọ̀ oníṣòwò; ó kú ní ọdún 1935. Ó jẹ́ Ọba tí ó jẹ lẹ́yìn Ọba Ìbíkúnlé Akítóyè gẹ́gẹ́ bíi Ọba Ìlú Èkó láti ọdún 1928 sí ọdún1931. Ọba Sànúsí Olusi jẹ ọmọ-ọmọ Olusi, àti ọmọ-ọmọ-ọmọ Ọba Ologun Kutere. Ó tún jẹ́ Ọba ìlú Èkó àkọ́kọ́ tí ó jẹ́ ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí.
Iṣẹ́ àti Jíyoyè Ọba ti Ìlú Èkó
àtúnṣeSànúsí Olusi jẹ́ oníṣòwò tí ó gbé ní 25 àdúgbò Bridge ní Ìdúmọ̀tà. Ó fi ìgbà kan rí dupò Ọba Ìlú Èkó ní ọdún 1925, ṣùgbọ́n Àrẹ̀mọ Ìbíkúnlé Akítóyè tí wọ́n jọ dupò yìí ló jáwé olúborí. Ní kòpẹ́ tí àwọn ìjọba aláwọ̀funfun-amúnisìn Bírítìsì gbẹ́sẹ̀ lé dúkìá rẹ̀ tó wà ni àdúgbò Bridge ni ó gba ipò Ọba ti ìlú Èkó, lẹ́yìn tí Ọba Ìbíkúnlé Akítóyè ti papòdà. Àwọn ìjọba aláwọ̀funfun-amúnisìn Bírítìsì gbẹ́sẹ̀ lé ogún rẹ̀ láti kọ afárá Carter.
Ìrọ̀lóyè gẹ́gẹ́ bíi Ọba ti Ìlú Èkó
àtúnṣeNí ìpadàbọ̀ Ọba tí wọ́n yọ lóyè tẹ́lẹ̀, ìyẹn Ọba Eshugbayi Eleko, àwọn ìjọba aláwọ̀funfun-amúnisìn Bírítìsì ní kí Ọba Sànúsí Olusi fi ààfin sílẹ̀; wọ́n sì fún un ní ilé tó tó ìwọ̀n ẹ̀gbẹ̀rún kan owó páńsì (£1,000) ní ọ̀nà agbègbẹ̀ Broad, pẹ̀lú owó àjẹmọ́nú ọdọọdún irínwó páńsì (£400). Ní ìgbà tó tún yá, wọ́n fún un ní àyè tirẹ̀ ní Oke-Arin tí ó tún jẹ́ Oke-Arin.
Ìtúnpò Ọba Ìlú Èkó dù ní ọdún 1932
àtúnṣeLẹ́yìn ikú Ọba Eshugbayi Eleko ní ọdún 1932, Sànúsí Olusi dupò Ọba ìlú Èkó; nígbà yìí, Àrẹ̀mọ Fálolú Dòsùnmú ni wọ́n jọ dupò, ṣùgbọ́n Sànúsí Olusi tún fìdí rẹmi. Ní ọdún 1935, àwọn aáwọ̀ bẹ́ sílẹ̀ láàárín Sànúsí Olusi àti Ọ̀ba Fálolú Dòsùnmú. Ọba Fálolú fèhónú hàn lórí ìwà Sànúsí Olusi tí ó rí bíi ìwà ìjẹgàba, ẹni tí ó ń lo ohun àmì ọba tí ó sì ń mú ìmúra Ọba, àfi bíi pé Ọba ni. Ní ìdáhùn sí ìfẹ̀hónúhàn Ọba Fálolú, Gómínà Cameron sọ fún Sànúsí Olusi kí ó yé hu irú ìwà bẹ́ẹ̀.
Ikú
àtúnṣeSànúsí Olusi kú ní ọdún 1935; wọ́n sì sin ín sí itẹ́ Okesuna.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- "Log into Facebook". Facebook. Retrieved 2024-06-20.
- "Sanusi Olusi". prabook.com. Retrieved 2024-06-20.
- "Sanusi Olusi". DarkOct02 - LitCaf verifies professionals with the Digital Business Card solution. 2016-01-19. Retrieved 2024-06-20.