Sarah Adebisi Sosan jẹ́ olùkọ́ni tẹ́lẹ̀ rí àti igbákejì Gómìnà Èkó láàrin ọdún 2007 sí 2011 nígbà tí Babatunde Fashola jẹ́ Gomina ìpínlè Eko.[1]


Sarah Adebisi Sosan
Ìgbàkejì Gómìnà ìpínlè Eko
In office
29 May 2007 – 29 May 2011
GómìnàBabatunde Fashola
AsíwájúFemi Pedro
Arọ́pòAdejoke Orelope-Adefulire
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí11 Oṣù Kejì 1956 (1956-02-11) (ọmọ ọdún 68)
Ojo, Badagry, British Nigeria (now Ojo, Lagos State, Nigeria)
Ẹgbẹ́ olóṣèlúAll Progressives Congress
Alma materUniversity of Lagos

Ìpìlẹ̀ àtúnṣe

A bí Sarah sí ìpínlẹ̀ Èkó ní 11 Febuary 1956 sínú ìdílé Olóyè àti Ọmọọba Durosinmi ti ì̀lú Irewe ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Ojo, Badagary. Ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọọba Ita-Oníkòyí ní Ìdúmọ̀tà, Èkó, bàbá rẹ̀ sì jẹ́ ọmoọ ẹgbẹ́ òṣèlú Action Group(AG) àti Unity Party of Nigeria(UPN), nítorí pé Ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ ọba, Sarah náà gba orúkọ "ọmọọba".[2]

Ẹ̀kọ́ rẹ̀ àtúnṣe

Ó bẹ̀rẹ̀ ìwé rẹ̀ ní ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Christ Assembly, Àpápá àti ìwé girama rẹ̀ ní Àwórì-Ajeromi.[3] Ó tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Lagos State College of Education, Ijanikin (tí a ti yí orúkọ rẹ̀ padà sí Adeniran Ogunsanya College of Education) ní ọdún 1980 níbi tó ti gba ìwé-ẹ̀rí NCE, lẹ́yìn náà, ó lọ Yunifásítì ìlú Èkó, Àkọkà, níbi tí ó ti gba àmì-ẹ̀yẹ Bachelor of Arts ní ìmọ̀ èdè òyìnbó ní ọdún 1988, ó sì gba àmì-ẹ̀ye Master degree nínú ẹ̀kọ́ àgbà ní ọdún 1989.

Òṣèlú àtúnṣe

Láàrin ọdún 1990 sí 1999, Sosan fi iṣẹ́ rẹ́ gẹ́gé bíi olùkọ́ni kalẹ̀ láti ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó, gẹ́gé bíi òṣìṣẹ́ tó ń rí sọ́rọ̀ ẹ̀kọ́. Gómìnà Babatunde Fashola padà yàn án gẹ́gẹ́ bíi igbákejì rẹ̀ ní ọdún 2007.

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "Sarah Adebisi Sosan". Innovations for Successful Societies. 2009-08-05. Retrieved 2022-05-30. 
  2. "Sarah Adebisi Sosan". Academic Influence. 1956-02-11. Retrieved 2022-05-30. 
  3. "Women You Should Know: Sarah Adebisi Sosan • Connect Nigeria". Connect Nigeria. 2020-10-08. Retrieved 2022-05-30.