Adeniran Ogunsanya College of Education

Adeniran Ogunsanya College of Education, tí àgékúrú rẹ̀ ń jẹ́ (AOCOED), jé ilé-ẹ̀kó gíga (Higher Education) tí ó wà ní ìlú Ọ̀tọ̀-Àwórì lábẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀jọ́, Ìpínlé̀ Èkó.[1] ilé- ẹ̀kọ́ Adéníran Ògúnsànyà ń ṣètò ìmọ̀ ìkọ́ni gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ tí ó sì ń pèsè ìwé ẹ̀rí  'Nigeria Certificate in Education' (NCE) àti ìmọ̀ ìkọ́ni tí ilé-ẹ̀kọ́ àgbà alákọ́kọ́ (undergraduate first degree), pẹ̀lú ìbáṣepọ̀ ilé-ẹ̀kọ́ àgbà ti ìpínlẹ̀ ( Èkìtì State University ) [2]

Adeniran Ogunsanya College of Education
Ẹnu ọ̀nà àbáwọlé Adeniran Ogunsanya College of Education
MottoKnowledge, Culture and Service
Motto in Englishknowledge,culture and service
Established1958
TypePublic
ProvostOjogbon Lafiaji Okuneye Bilikis
LocationOto-Awori, Lagos State, Nigeria
WebsiteOfficial website

Ìtàn ilé-ẹ̀kọ́ náà àtúnṣe

Ilé-ẹ̀kọ́ gíga náà tí wọ́n kọ́kọ́ ń pè ní "ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti ìpínlẹ̀ Èkó" (Lagos State College of Education), ni wọ́n dá sílẹ̀ ní ọdún 1958 gẹ́gẹ́ bí ilé-ẹ̀kọ́ àwọn olùkọ́ onípele kẹ́ta, tí wọ́n sì kọ́kọ́ gbà àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó tó Àádọ́sàán (90) ní ọdún àkọ́kọ́. Ní ọdún 1982, wọ́n gbé ilé-ẹ̀kọ́ náà kúrò ní Súrùlérè lọ sí Ọ̀tọ̀-Àwórì, látàrí àìtó àwọn ohun amáyé-dẹrùn ìgbà-lódé àti pípọ̀ tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń pọ̀ si lọ́dọọdún.

Lára àwọn lààmì-laaka tó ti jáde níbẹ̀ àtúnṣe

  • Kunle Ajayi
  • Sarah Adebisi Sosan
  • Sanai O. Agunbiade

Awon ile-eko mefa ti o wa ni inu ile-eko giga Adeniran Ogunsanya ni: àtúnṣe

  • school of science
  • school of education
  • school of art and social science
  • school of vocational and technical education
  • school of early childhood and primary education
  • school of language

Lára àwọn olùkọ́ tó gbajúmọ̀ níbẹ̀ ni àtúnṣe

  • Afeez Oyètòrò

Ẹ tún lè wo àtúnṣe

  • List of schools in Lagos
  • List of colleges of education in Nigeria

Àwọn ìtọ́ka sí àtúnṣe

  1. "About Us". Archived from the original on 6 August 2015. Retrieved 5 July 2015. 
  2. "EKSU sandwich students warned against cultism". Daily Independent Nigeria. 27 March 2013. Archived from the original on 6 July 2015. Retrieved 5 July 2015. 

Ìjápọ̀ ìta àtúnṣe