Sarah Adegoke (ojoibi 1997) je elere tenisi omo orilẹ-ede Naijiria. Lọwọlọwọ oun lo jẹ agbabọọlu tẹnisi ti o ga julọ ni isọri ẹyọkan ti awọn obinrin gẹgẹ bi Federation Tennis Nigeria.

Sarah Adegoke
Orílẹ̀-èdè Nigeria
Ọjọ́ìbí16 Oṣù Keje 1997 (1997-07-16) (ọmọ ọdún 27)
Ọwọ́ ìgbáyòRight-handed (double–handed backhand)
Ẹnìkan
Iye ìdíje1–8 (WTA)
Ẹniméjì
Iye ìdíje1–10 (WTA)
Ipò rẹ̀ gígajùlọNo. 874
Ipò rẹ̀ lọ́wọ́No. 884(2019)
Last updated on: 06 March 2019.

Iṣẹ-ṣiṣe

àtúnṣe

Ti o dagba ni ilu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, Adegoke kọ ẹkọ bọọlu tẹnisi lati owo baba rẹ, Adedapo Adegoke, ẹniti o ṣe akiyesi pe ko lẹkọ nipa ere idaraya na, ṣugbọn o ka ninu iwe awọn nkan ere idaraya ati iwe iroyin lati kọ ọ ni awọn ofin ti ere naa. Ọdun 2010 lo bẹrẹ si ṣoju orilẹede Naijiria, nigba ti o fi di ọdun 2014 o ti jẹ obinrin to ga julọ ni ipo tẹnisi ni orilẹ-ede Naijiria. O ṣapejuwe Serena Williams gẹgẹbi iwuri rẹ ti o tobi julọ ninu ere naa. Adegoke ni o gbe ipo keji ninu ẹka obinrin agba ni idije 34th ti CBN Tennis Open Championship ni ọdun 2012. Ó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Nàìjíríà díẹ̀ tí wọ́n ti dé àṣekágbá ìdíje Gómìnà Cup Tenisi Lagos, iṣẹ́ ìyanu kan tó ṣe lọ́dún 2014, tí o si pàdánù si owo Zarah Razafimahatratra ti Madagascar nínú eré tó kẹ́yìn. Ni idije Ikoyi Club Masters Tennis Championship ti 2014, Adegoke to je omo odun merindinlogun nigba naa lo fa idamu nigba to jawe olubori ninu idije ifesewonse Open Tennis ti CBN lodun 2013, Ronke Akingbade ninu idije ifesewonse obinrin.

Ni oṣu keji ọdun 2017, o bori Ikoyi Club Masters Tennis Championship . Ninu odun naa bakanna, o gba ami eye ti ẹka àwọn obirin ni idije 39th CBN Tennis Open Championship, nibiti o ti bori Marylove Edwards. Ni osu kejila ọdun 2017, o bori orogun re, Blessing Samuel, 6–3, 6–3 lati gba idije Rainoil Tennis Open ni Lagos Country Club.

Ni Oṣu Kẹjọ ọdun 2018, o de ipo akọkọ ati ikẹta ninu ẹka ẹyọkan ati ti eeyanmeji ni ibamu si Fedirasan Tenisi Nigeria.

Awọn itọkasi

àtúnṣe

Ita ìjápọ

àtúnṣe