Segun Adewale (Aeroland)
Ọ̀túnba Ṣẹ́gun Adéwálé,ti gbogbo eniyan mo si Segun Aẹṛ́oland, ti a bi ni ojo keedogun sukarun odun 1966, je ogbontarigi onisowo, eleyinjuanu ati oloselu ibere pepe ni ilu Eko, o si je omo bibi EbiKlei ti nijpionleba ibile Ijero ni ipinle Ekit, i o wa ni apa Guusu Iwo-oorun Naijiria, oun si ni asoju fun ekun iwo oorun ipinle EkOoni ile asofin aga orile-ede ONijAria latA ibnu Egbe ose PDP nolonmiunira atio idiibo si ile asofin agba ni odun 2l 015.[1][2]
Otunba Segun Adewale | |
---|---|
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 15 Oṣù Kàrún 1966 Lagos, Nigeria |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | Peoples Democratic Party (PDP) |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Victoria Taiwo (Nee Owoeye) |
Alma mater | University of Ibadan Lagos State University |
Occupation | Entrepreneur, politician |
Website | Official website |
Nickname(s) | Aeroland |
Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé
àtúnṣeA bí Ṣẹ́gun Adéwálé sínu ẹbí Ọ̀̀gbẹ́́ni àti Ìyáàfin Mikaeli Adéwálé tí agbo ilé Àrẹmọ àti agbo ilé Ọ̀gẹ́gẹ́nìjó ní ọjọ́ kẹ̀ẹ̀́dógún oṣu karùn ọdún 1966.[3]
Ṣégun Adéwálé lọ sí ilé-ìwé alákọ̀bẹ̀rẹ̀ ti Seventh Day Adventist, tí ó wà ní Abúlé Ọjà, ní ìlú Èkó láàrín ọdún 1972 àti 1978. Ní ọdún 1979, àwọn òbí rẹ̀ pinnu láti mú àkọ́bí ọmọ wọn padà sí ìlú Èk̀itì kí ó lè kọ́ àṣà, ìṣẹ̀dálẹ̀ àti iṣẹ́ ìlú Èkìtì dáadáa; fún ìdí èyí, ó wọ ilé ẹ̀kọ́ girama ti Ìpótì ní ọdún kan náà. Ní ilé-ìwé yìí, òun ni ó kéré jùlọ lọ́jó orí nínú àwọn tí ó ń gbá bọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá. Látìgbà yí ni ìwà ẹlẹ́yinjú-àánú ti bẹrẹ sí fi ara hàn nínú rẹ̀ ní àkókò tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò tíì tó ǹkan nítorí tí ó ń ran àwọn aláiní lọ́wọ́ ní ìlú Ìpoti nípa bíbá wọn ṣe iṣé ọmọ-ilé láì gba owo ọ̀yà! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò parí ẹ̀kọ́ girama rẹ̀ ní ìlú Èkìtì, síbẹ̀-síbẹ̀ ó ti ní òye tí ó pọ̀ jọjọ nínú ìwà ọmọlúwàbí àti ìṣẹ̀dálè ìlú Èkìtì, èyí t́i a mọ̀ mọ àwọn ọmọ Èkìtì. Lópin rẹ̀, ó parí ẹ̀kọ̣́ girama rẹ̀ ní ilé Ẹ̀kọ́ Girama Oríwù, ní ìlú Ìkòròdú ní ìpínlẹ̀ Èkó ní ọdún 1983, ó sì gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì ẹ̀yẹ ní ilé-ìwé náà.[4]
Ṣeǵun Adéwálé lọ sí ilé-ẹ̀kó àgbà Fásitì Ibadan láàrín ọdún 1986 àti ọdún 1990 ní bi tí ó ti kẹkọ̀ọ́ gboyè ìm̀ọ ìjìnlẹ̀ nípa àyíká. Ó tún kẹ́kọ̀ọ̀ si tí ó sì fi gba oyè ọ̀gá nínú ètò ìṣèjọba láti ilé-ẹ̀kọ́ àgbà Fásitì ti ìpínlẹ̀ Èkó ní ọdún 1995. Bákan náà ni ó tún gba ìwé ẹ̀rí nínú ìmọ̀ nípa ìṣètò ìrìnà òjú òfurufú ní ọdún 2012 tí ó sì gba ìwé ẹ̀rí pé ó mọ̀ nípa àmójútó ètò ìrìnà ojú òfururú láti ̀ilú Texas ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ní odun 2013.
Awon itokasi
àtúnṣe- ↑ "Archived copy". Archived from the original on 2015-02-24. Retrieved 2015-02-24.
- ↑ "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2015-02-24. Retrieved 2018-04-28.
- ↑ "2018: How I'll fix Ekiti state economy - Segun Adewale". Vanguard News. 2018-04-13. Retrieved 2018-05-23.
- ↑ "Ekiti 2018: ADP adopts Segun Adewale as gubernatorial candidate". The Nation Nigeria. 2018-03-07. Retrieved 2018-05-23.