Sẹ́ríkí ń góómà
Sẹ́ríkí ń Góómà
àtúnṣeỌba mẹ́wàá ìgbà mẹ́wàá,
Ìgbà kan ò lolé ayé gbó
Sẹ́ríkí ń góómà, sànmọ́nì góómà
Ìgbà ti lọ ńlẹ̀ yìí
Ohun gbogbo ti yí padà ni wàràwàra.
Ejò ìgbà ti wọ́ kúò níbi tàná,
Ìgbà tó dé làwá ń lò ẹ̀bi wa kọ́ rárá,
Ọ̀pọ̀ èèyàn tí ò bá fẹ́ bágbà yí ló le máa jàgbùrín èṣí lọ́bẹ̀
Mo rántí lákòókò kan nílẹ̀ yí
Mo kúkú ti gbọ́njú, ń ò tí ì bàlágà ni.
Pẹ́bẹ́ lọ, pẹ́bẹ́ bọ̀ àtẹ́lẹsẹ̀ ni láti Èkó títí dé ‘Bàdàn,
Kò sí mọ́tò bẹ́ẹ̀ ni kò sí bàtà lẹ́sẹ̀
Bóòrùn ti ń pawọ ori, ...
Akinwùmi Fẹ̀yìn tì
àtúnṣeÒréré ilé ayé rèé,
Kò sóhun tó nibẹ̀rẹ̀ tí ò ní í lópin jọjọ
Bóòrùn ti lágbára to,
Tiná ọmọ ọrara ń pa tẹru-tọmọ
Bó pẹ́ bó yá ojú ọjọ́ a rọ̀ wọ̀ọ̀,
Òòrùn a sì wọ̀ọ̀kùn, ààjin dùndùn.
Òṣúpá jèréjèré, a-mọ́-láwọ̀ bí ọ̀kinkin,
Nǹkan rìbìtì tó ń tànmọ́lẹ̀ lálẹ́.
Tí gbogbo wá fí ń tànmọ́lẹ̀ lálẹ́.
Ti gbogbo wá fi ń gbáfẹ́ orí,
Ìgbà tòṣù bá sì dàràn-mọ́jú,
Ara kálukú a sì rọ̀ wọ̀ọ̀,
A sì di wọ̀mù lórí ibùsùn.
Bó ti wù kọ́mọdé gbádùn eréṣùpá tó.
Bóṣú bá paná, eré a sì dìkàsìn,...
Ori mi àpé
àtúnṣeOrí mi àpé,
Àyà mi àkóbì-bọ
Nígbà tórí ń gbeni
Kín lòòṣà ń wò?
Orí lẹja fi í labú já,
Orí lọ̀kàsà fi í ṣe rere lálẹ̀ odò
Orí la fi í mẹ́ran láwo
Tá à kì í fì í méyìí tó léegun
Orí lobìnrin fí í yan ọkọọre ńlé ayé,
Orí lobìnrin fí í jókòó nílé ọkọ rẹ̀
Kó tóó dòpìtàn.
Orí ló ṣọba tó fi dádé owò,
Orí ló ṣèjòyè tó fi tẹ̀pá ilẹ̀kẹ̀. ...
Bí mo bá lówó
àtúnṣeOnígbèsè mọ ọbẹ̀ẹ́ sè owó ni ò sí lọ́wọ́
Tálákà náà lè jẹ̀dọ̀ ẹran,
Ó le jẹ Ṣàkì, jabọ́dìí, jẹ ibi iké inú ẹran.
Ẹrú le ṣe bí Ọba, kò tún tẹ̀páàlẹ̀kẹ̀.
Ẹni bá ń ṣe fújà láìlówó lọ́wọ́,
Ṣe ló fẹ́ gbéra rẹ̀ sí kòtò
Èèyàn ò lówó lọ́wọ́.
Ó ní pẹ́tẹpẹ̀tẹ́ lè jábọ́
Bá a bá bẹ̀dí ọ̀rọ̀ wò,
Onitọ̀hún fẹ́ ṣu bára ni.
‘N ò nigbá, ń ò láwo’
Ẹni náà ò tí ì sọ ǹkan tí kò ní. ...
Débọ̀ Awẹ́ (2004), Ẹkún Elédùmarè Elyon Publishers, ISBN 978 2148 17
2, oju-iwe 1-20.