Serkalem Biset Abrha
Serkalem Biset Abrha ni a bí ní ọjọ́ kẹjọ, oṣù March, ọdún 1987. Arábìnrin náà jẹ́ asáré tó wá láti orílẹ̀-èdè Ethiopia tó sì tún kópa nínú oríṣiríṣi ìdíje ọ̀nà jínjìn[1][2][3].
Ìgbésí ayé Biset
àtúnṣeBiset kọ́ iṣẹ́ eré-sísá pẹ̀lú Bizunesh Deba, Genna Tufa, àti Atalelech Asfaw ní ilẹ̀ New York àti Albuquerque, New Mexico[4]. Ara iṣẹ́ arábìnrin náà ni eré-sísá lọ sí orí-òkè Addis Ababa, Ethiopia pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ nínú eré-sísá[5].
Àṣeyọrí
àtúnṣeEré-sísá Abrha àkọ́kọ́ ní ìta orílẹ̀-èdè Ethiopia wáyé ní ilẹ̀ India ní Delhi àti Lahore 10k láti ọdún 2005 dé ọdún 2007. Abrha parí pẹ̀lú ipò kejì nínú ìdajì marathon ní ọdún 2006 níbi tó ti gba owó ẹgbẹ̀rún dollar[6]. Ní ọdún 2008, Abrha yege nínú Maas Marathon tó wáyé ní Visè, Belgium. Ní ọdún 2009, arábìnrin náà kópa nínú Atlanta Marathon ní Georgia níbi tó ti ṣáájú àwọn obìnrin tó sì gba ẹ̀bùn ẹgbẹ̀rún mẹ́ta dollar[6]. Ní ọdún 2010, arábìnrin náà parí pẹ̀lú ipò kẹta nínú Marathon ti Las Vegas níbi tó ti gba owó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin dollar. Ní ọdún 2011, Abrha yege nínú Marathon ti California tó wáyé ní Sacramento, California[7]. Ní ọdún 2017, arábìnrin náà gbé ipò kẹta nínú eré-sísá ti France 8K ní oṣù August, ọjọ́ ogún ní agogo 32:01. Ọ̀kan nínú àṣeyọrí arábìnrin náà to ṣè pàtàkì ni pé ó gbé ipò àkọ́kọ́ nínú Marathon ti Philadelphia ní 2:14:47[8].
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 2009 New York City Marathon results
- ↑ Serkalem BISET Profile
- ↑ Abraha Serkelam Biset of Ethiopia was the top women's finisher, at 2:31:39
- ↑ Buzunesh trained with Abrha
- ↑ Ethiopian Runners in the US vie for a level field with athletes from ethiopia
- ↑ 6.0 6.1 ING Georgia Marathon and Half Marathon Atlanta
- ↑ annual California International Marathon in Sacramento.
- ↑ Philadelphia Marathon, held November 18, 2018