Sheila Munyiva (tí wọ́n bí ní 27 Oṣù Kẹẹ̀ta Ọdún 1993) jẹ́ òṣèrébìnrin àti olùdarí eré ọmọ orílẹ̀-èdè Kẹ́nyà

Sheila Munyiva
Ọjọ́ìbí27 Oṣù Kẹta 1993 (1993-03-27) (ọmọ ọdún 31)
Nairobi, Kenya
Orílẹ̀-èdèKenyan
Iṣẹ́Actress, film director
Ìgbà iṣẹ́2018-present

Ìsẹ̀mí rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Munyiva ní ọdún 1993 ní Ìlú Nairobi.[1] Ó maá n wo eré Hannah Montana lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbà tí ó wà lọ́mọdé.[2] Ó maá n ṣe àbẹ̀wó sí Ilẹ̀ọba Aṣọ̀kan lóòrèkóòrè nítorí wípé níbẹ̀ ni ìyá rẹ̀ n gbé.[3] Munyiva kọ́ ẹ̀kọ́ láti jẹ́ òṣìṣẹ́ ìròyìn ní ìbẹ̀rẹ̀ ṣáájú kí ó tó ṣíjú sí ṣíṣe fíìmù. Lẹ́hìn ìparí ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó tún bẹ̀rẹ̀ sí ní lọ sí àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan láti lẹ̀ túnbọ̀ dára si gẹ́gẹ́ bi ònkọ̀tàn.[4]

Ní ọdún 2018, Munyiva kó ipa Ziki nínu eré Rafiki. Eré náà dá lóri ìwé-ìtàn kan tí Monica Arac de Nyeko kọ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Jambula Tree, tó síì n ṣàlàyé ìfẹ́ tí ó n bẹ láàrin àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin méjì kan ní ìlú tí ìbálòpọ̀ ẹlẹ́yà kan náà ti jẹ́ èèwọ̀. Ní ìbẹ̀rẹ̀, Munyiva ṣeyèméjì láti kó ipa náà títí ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan fi gbàá níyànjú tó sì ń jẹ́ kó mọ rírì ìdí tó fi gbọ́dọ̀ ṣe ipa náà.[5] Wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé fíìmù náà ní ìlú Kẹ́nyà nígbà tó ṣe wípé òfin kò fàyè gba ìbálòpọ̀ obìnrin sóbìnrin tàbí ọkùnrin sọ́kùnrin. Rafiki ni àkọ́kọ́ fíìmù ilẹ́ Kẹ́nyà tí yóó jẹ̀ẹ́ wíwò níbi ayẹyẹ Cannes Film Festival.[6] Ann Hornaday gbóríyìn fún Munyiva àti akẹgbẹ́ rẹ̀ Samantha Mugatsia fún ipa wọn nínu eré náà.[7] Wọ́n yan Munyiva fún àmì-ẹ̀yẹ òṣèré tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ Africa Movie Academy Awards.[8]

Ní ọdún 2019, Munyiva kó ipa Anna gẹ́gẹ́ bi òṣìṣẹ́ oníwòsàn kan nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Country Queen.[9] Ní Oṣù Keèje ọdún 2019, Munyiva ṣe àkọ́kọ́ ipa rẹ̀ lórí ìpele nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Sarafina!.[10] Ó ti darí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìkéde àti ìpolówó ọjà ní orílẹ̀-èdè Kẹ́nyà, ó síì n ṣiṣẹ́ láti gbé eré oníṣókí kan jáde tí ó pe àkọ́lé rẹ̀ ní Ngao, èyí tí ó dá lóri àwọn ìrírí ìgbà èwe rẹ̀.[11]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀

àtúnṣe
  • 2018: Rafiki as Ziki Okemi
  • 2018: L'invité (TV series)
  • 2019: Country Queen as Anna (TV series)

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Rafiki" (PDF). Festival de Cannes. Retrieved 8 November 2020. 
  2. Leighton-Dore, Samuel (26 June 2019). "'Rafiki' star Sheila Munyiva on the colourful, queer future of African cinema". SBS. https://www.sbs.com.au/topics/pride/fast-lane/article/2019/06/25/rafiki-star-sheila-munyiva-colourful-queer-future-african-cinema. Retrieved 8 November 2020. 
  3. "Sheila Munyiva: The New Sarafina". Kenya Buzz. 3 July 2019. https://www.kenyabuzz.com/lifestyle/sheila-munyiva-the-new-sarafina/. Retrieved 8 November 2020. 
  4. "Rafiki" (PDF). Festival de Cannes. Retrieved 8 November 2020. 
  5. "Rafiki" (PDF). Festival de Cannes. Retrieved 8 November 2020. 
  6. Darling, Cary (9 May 2019). "Kenyan gay life comes into focus in ‘Rafiki’". Houston Chronicle. https://www.houstonchronicle.com/entertainment/movies_tv/article/Kenyan-gay-life-comes-into-focus-in-Rafiki-13829398.php. Retrieved 8 November 2020. 
  7. Hornaday, Ann (6 May 2019). "Movie about teenage girls in love is a breakthrough for Kenyan filmmaker". The Washington Post. https://www.washingtonpost.com/goingoutguide/movies/movie-about-teenage-girls-in-love-is-a-breakthrough-for-kenyan-filmmaker/2019/05/06/a910b1e4-6c5d-11e9-be3a-33217240a539_story.html. Retrieved 8 November 2020. 
  8. Dia, Thierno (19 September 2019). "AMAA 2019, the nominees". Africine. Retrieved 8 November 2020. 
  9. "'Country Queen' a David vs Goliath tale". https://www.the-star.co.ke/sasa/entertainment/2019-04-05-country-queen-a-david-vs-goliath-tale/. Retrieved 8 November 2020. 
  10. "Sheila Munyiva: The New Sarafina". https://www.kenyabuzz.com/lifestyle/sheila-munyiva-the-new-sarafina/. Retrieved 8 November 2020. 
  11. "Rafiki" (PDF). Festival de Cannes. Retrieved 8 November 2020. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

àtúnṣe