Èdè Shíkọmọ

(Àtúnjúwe láti Shikomor)

Èdè Shíkọmọ (Shikomor) tàbí èdè Kòmórò ni èdè tó gbalẹ̀ jùlọ ní ní Kòmórò (àwọn erékùṣù olómìnira ní Òkun Ìndíà, nítòsí Mòsámbíkì àti Madagáskàr) àti ní Mayotte. Ó jẹ́ ẹ̀ka èdè Swahili sùgbọ́n ipa púpọ̀ lọ́dọ̀ èdè Lárùbáwá ju Swahili lọ. Erékùṣù kọ̀ọ̀kan ní ọ̀nà ìsọ èdè ti wọn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀; ti Anjouan únjẹ́ Shindzuani, ti Mohéli Shimwali, ti Mayotte Shimaore, ati ti Grande Comore Shingazija. Kò sí álfábẹ́tì oníbiṣẹ́ kankan fún un títí ọdún 1992, sùgbọ́n ọnà-ìkọ́ Lárùbáwá àti Latin únjẹ́ lílò fun.

Èdè Kòmórò
Shíkọmọ
Sísọ níComoros àti Mayotte
Ọjọ́ ìdásílẹ̀1993
AgbègbèKáàkiri Comoros àti Mayotte; bákannáà ní Madagascar àti Réunion
Ìye àwọn afisọ̀rọ̀700,000
Èdè ìbátan
Àwọn àmìọ̀rọ̀ èdè
ISO 639-3variously:
zdj – Ngazidja dialect
wni – Ndzwani (Anjouani) dialect
swb – Maore Comorian
wlc – Mwali dialect



Àwon Itokasi

àtúnṣe