Èdè Lárúbáwá

(Àtúnjúwe láti Arabic language)

Èdè Lárúbáwá tabi ede Araabu Ara èdè Sẹ̀mítíìkì ni èdè Àrábíìkì (Arabic (Èdè Lárúbááwá)). Àwọn tí ó ń sọ ọ́ tó mílíọ̀nù lọ́nà igba gẹ́gẹ́ bí èdè abíníbí ní àríwá Aáfíríkà àti ìlà-oòrùn-gúsù Eésíà (Asia). Àìmoye ènìyàn tí a kò lè fi ojú da iye wọn ni ó ń sọ èdè yìí gẹ́gẹ́ bí èdè kejì, ìyẹn èdè àkọ́kún-tẹni ní pàtàkì ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ̀sìn Mùsùlùmú ti gbilẹ̀. Àwọn tí ó lọ ṣe àtìpó ní pàtàkì ní ilẹ̀ faransé náà máa ń sọ èdè yìí. Ibi tí àwọn tí ó ń sọ èdè yìí pọ̀ sí ju ni Algeria, Egypt, Iraq, Morocco, Saudi Arabia, Sudan, Syria, Tunisia àti Yeman. Àwọn ẹ̀ka-èdè rẹ kan wà tí ó jẹ́ ti apá ìwọ̀-oòrùn tí àwọn kan sì jẹ́ ti ìlà-oòrùn. Èdè tí a fi kọ kọ̀ráànù sílẹ̀ ni a ń pè ní ‘Classical’ tàbí ‘Literary Arabic’. Èdè mímọ́ ni gbogbo mùsùlùmú àgbáyé tí ó tó ẹgbẹ̀rún ó lé ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù ní àgbáyé (1, 100 million) nínú ètò ìkànìyàn 1995 ni ó mọ èdè ‘Classical Arabic’ yìí. Olórí ẹ̀ka-èdè Lárúbáwá wà tí ó sún mọ́ èyí tí wọ́n fi kọ Kọ̀ráànù. Eléyìí ni wọ́n fi ń kọ nǹkan sílẹ̀. Òun náà ni wọ́n sì máa ń lo dípò àwọn ẹ̀ka-èdè Lárúbáwá. Púpọ̀ nínú àwọn tí ó ń sọ ẹ̀ka-èdè lárúbáwá yìí ni wọ́n kò gbọ́ ara wọn ní àgbóyé. Méjìdínlọ́gbọ̀n ni àwọn álúfábẹ́ẹ̀tì èdè Lárúbááwá. Apé ọ̀tún ni wọ́n ti fi ń kọ̀wé wá sí apá òsù Yàtọ̀ sí álúfásẹ́ẹ̀tì ti Rómáànù, ti Lárúbáwá ni àwọn ènìyàn tún ń lò jù ní àgbáyé. A ti rí àpẹẹrẹ pé láti nǹkan bíi sẹ́ńtérì kẹ́ta ni a ti ń fi èdè Lárúbáwá kọ nǹkan sílẹ̀. Nígbà tí ẹ̀sìn mu`sùlùmí dé ní sẹ́ńtúrì kéje ni òkọsílẹ̀ èdè yìí wá gbájúgbajà. Wọ́n tún wá jí sí ètò ìkọsílè èdè yìí gan-an ní séńtúrì kọ́kàndínlógún nígbà tí ìkọsílẹ̀ èdè yìí ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ará. Ìwọ̀-oòrùn Úróòpù. Ní pele-ń-pele ni èdè yìí pín sí (ìyẹn ni pé eléyìí tí olówó ń sọ lè yàtọ̀ sí ti tálíkà tàbí kí ó jẹ́ pé eléyìí tí obìnrin ń lò lè yàtọ̀ sí ti ọkùnrin).

Èdè Lárúbáwá
العربية al-ʿarabīyah
Ìpè/alˌʕaraˈbiːja/
Sísọ níPrimarily in the Arab states of the Middle East and North Africa;
liturgical language of Islam.
Ìye àwọn afisọ̀rọ̀Approx. 280 million native speakers[1] and 250 million non-native speakers[2]
Èdè ìbátan
Sístẹ́mù ìkọArabic alphabet, Syriac alphabet (Garshuni), Bengali script [1] [2]
Lílò bíi oníbiṣẹ́
Èdè oníbiṣẹ́ níOfficial language of 25 countries, the third most after English and French[3]
Àkóso lọ́wọ́Algeria: Supreme Council of the Arabic language in Algeria

Egypt: Academy of the Arabic Language in Cairo
Iraq: Iraqi Academy of Sciences
Jordan: Jordan Academy of Arabic
Libya: Academy of the Arabic Language in Jamahiriya
Morocco: Academy of the Arabic Language in Rabat
Sudan: Academy of the Arabic Language in Khartum
Syria: Arab Academy of Damascus (the oldest)

Tunisia: Beit Al-Hikma Foundation
Àwọn àmìọ̀rọ̀ èdè
ISO 639-1ar
ISO 639-2ara
ISO 639-3ara – Arabic (generic)
(see varieties of Arabic for the individual codes)



Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Procházka, 2006.
  2. Ethnologue (1999)
  3. Wright, 2001, p. 492.