Shola Allyson

Akọrin obìnrin

Shola Allyson-Obaniyi (lédè Yorùbá: Ṣọlá Allyson-Ọbáníyì), jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó jẹ́ akọrin ẹ̀mí (soul) àti ìbílẹ̀, ó sì tún jẹ́ olùkọ́ orin. Ó di gbajú-gbajà akọrin pẹ̀lú ìkan lára àwọn orin rẹ̀ tí ó pè ni "Ejì Òwúrọ̀" ní ọdún 2003, orin yìí sì tún jẹ́ orin àgbàsílẹ̀ fún fíìmù kan tí ó dẹ̀ pè ni "Ejì Òwúrọ̀". Lẹ́yìn tí ó gbé àwo yìí jáde, àwọn àwo orin mìíràn tí ó tẹ̀ lé pọ̀. Nínú àwo orin rẹ̀ "Ejì Òwúrọ̀" bí gbogbo àwọn àwo orin tí ó ṣe lẹ́yìn èyí, orin tí ó kọrin dẹ̀ pọ̀, fún àpẹẹrẹ "Obinrìn Ni Mi", "Àṣeyẹ", "Ìsinmi", àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ wà nínú àwo "Ejì Òwúrọ̀" rẹ̀..[1]  Yàtọ̀ sí wí pé Ṣọlá jẹ́ olórin, ó tún jẹ́ akọ́ni lóhùn orin àti olùgbànímọ̀ràn.[2]

Shola Allyson-Obaniyi
Orúkọ àbísọOlusola Allyson
Ọjọ́ìbíIkorodu, Lagos State
Irú orin
Occupation(s)
Years active2003–present
LabelsGalaxy Music
Associated actsCobhams Asuquo
Websitesolaallyson.com

Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí-ayé rẹ̀ àti ìrìn-àjò ẹ̀kọ́ rẹ̀ àtúnṣe

Won bi Shola Allyson ni ilu Ikorodu, ni ipinle Eko ni ibere odun 1970. O lo si ile-iwe alakoobere Anglican , ti ilu Ikorodu, leyin eyi ni o te siwaju ni ile-iwe Girama Shams-el-deen, ni ilu Ikorod fun ipele eko eleekeji. Leyin eyi ni o lo si ile-iwe Gbogbonise  ti ijoba  (Technical College) ni Agidingbi Ikeja, ni bi ti o ti ko nipa imo okowo  (Business Studies) ti o si gba iwe eri  (NBTE).[3]

Ni odun 1997, o wo ile-iwe Polytechnic, Ibadan ti o si ko nipa imo Ayinike Orin (Music Technology), ti o da lori bi a se n lo ohun ninu orin. Ibe ni o ti ni iwe eri (HND) Higher National Diploma pelu ipo ti o ga julo.[3][4]

Ìgbòkègbòdò iṣẹ́ rẹ̀ àtúnṣe

Arabinrin Shola Allyson bere igboke-gbodo ise orin re ni opin odun 1980s, nigba ti o wa ni omo odun Metala (13 yrs).[3][4] Leyin eyi ni o di elegbe to yanranti leyin awon olorin ilu-mooka bi: Yinka Ayefele, Gbenga Adeboye, Wasiu Alabi (Pasuma), Akande Abass (Obesere) ati olorin rege (Daddy Showkey). Iwonba afani ti o ri lati se awo orin tire akoko jade iyen "Eji Owuro" waye nigba ti o pade orakunrin kan ti o mu iwe eto ere ori-itage kan dani ninu oko akero, ti okunrin naa si ba Sola takuroso lori ere nise ori-itage ti won sese se laseyori ti akole re n je "Orekelewa" (You at a distance). Bayi ni okunrin naa se pe Sola Allyson lati wa korin fun ere naa, ti orin re si sokunfa bi won se yi akole ere naa pada si "Eji Owuro" (The morning Dew). Nigba ti sinima  Eji Owuro jade tan, ile ise ti o ya aworan sinima naa pinu lati gbe awo orin jade pelu akole sinima yii iye "Eji Owuro". Aseyori nla gbaa ni awo orin yii je fun ile ise ati olorin funra re "Shola Allyson" ti o si so Sola di ilu-mooka olorin ni awujo awon korin korin.[2][4]

Ìgbésí-ayé rẹ̀ àtúnṣe

Shola Allyson se igbeyawo ninu osu Erena, odun 2003 (March 2003). O pade olowo ori re arakunrin, Toyin Obaniyi ninuy egbe akorin ijo won. Won si bi awon omo meta fura won: Ayobami, Mopelola and Obafunmiwo.[3][4][5]

Àwọn àwo orin rẹ̀ àtúnṣe

Àwo àtúnṣe

  • Eji Owuro (2003)
  • Gbe Je F'ori (2005)
  • Ire (2007)
  • Im'oore (2009)
  • Adun (2012)

Awon Itoka si àtúnṣe

  1. Akinnagbe, Akintomide (30 December 2011). "GALAXY MUSIC BOSS,AHMED ENDS 3-YEAR RIFT WITH SHOLA ALLYSON". Modern Ghana. Retrieved 27 August 2016. 
  2. 2.0 2.1 Salami, Tayo (17 February 2015). "I’m privileged to enter into people’s souls – Sola Allyson-Obaniyi". News Watch Times. Archived from the original on 9 February 2016. Retrieved 27 August 2016. 
  3. 3.0 3.1 3.2 3.3 "Sola Allyson - Biography". Archived from the original on 2018-02-26. Retrieved 2018-07-17. 
  4. 4.0 4.1 4.2 4.3 "WHY I DON’T WEAR SKIMPY DRESSES –SOLA ALLYSON-OBANIYI". Nigeria Films. The Nigerian Voice. 6 August 2007. Retrieved 27 September 2016. 
  5. "My music heals suicide-prone minds, Says SOLA ALLYSON-OBANIYI". The Nation. Osun Defender. 15 December 2013. Archived from the original on 1 February 2019. Retrieved 27 September 2016. 

[Ẹ̀ka:Àwọn ọmọ Yorùbá]]