Soji Cole
Olusoji Henry Cole jé olùkọ́ àgbà ilé èkó kan ní Nàìjíríà, tí í şe ti kan Yunifásitì t'ìlú Ìbàdàn. Gbajú-gbajà akòtàn àti onkòwé ní ó jé pèlú. Ó jé olùgba èbun fún Lítíréşo ní Nàìjíríà t'odún 2018. Àwọn agbègbè tàbí àfojúsùn ìwádìí rẹ dá l'órí i eré òun ìtójú u àwọn ìjìnlè ogbè àti ìwádìí iṣé àdáṣe ti àṣà.
Ìwé e rè, Embers je òkan nínú u àwọn ìwé Nàìjíríà tí ó dára jù lọ fún ọdún 2018 nínú u àkójọ ìwe ìròyìn ÀgbékèléOjoojúmó (DailyTrust).
Cole jé akẹ́kọ̀ọ́ jáde ilé ìwé gíga ti Yunifásitì Ìbàdàn (University of Ibadan). Ó tún jé ẹlégbé àbèwò ní ilé èkó gíga ti Roehampton.
Cole ṣo fún Dailytrust pé kíkọ àwọn ìtàn kúkúrú ni bí òun ṣe ní ìkéde àkókó ọ rè. Nígbà tí ó ń s'òrò l'órí i àwọn ìtaláyà tí àwọn onkòwé tí ó ṣé yọ ní orílè èdè Nàìjíríà. Ó s'ọ̀rọ̀ àwọn ìdíwó ìnáwó àti ìdínkù àwon olùgbé ìlú bí i àwọn okùnfà tí ń dín awon awakò ìmòwé kù l'óríle èdè ná à. Ó tún ṣ'àlàyé bí iná ṣe jé ìpèníjà ń lá l'ákòókò tó ńko àwọn ìwé àkọólè rè. Nínú u ìfòròwánilénuwò pèlú Ìwé Ìròyìn Oòrùn (The Sun), Cole rántí pé òun béèrè ìwé kíkọ l'ákòkóò tí òun wà ní ilé ìwè alákòóbèrè láti ta yo láàárín in àwọn ojúgbé e rè. Ó tún sọ àsọtélè bí i òdó kékeré mi ṣe di ìwé ìtàn àtèjáde àkókó rẹ. Ó ṣe àtèjáde eré àkókó ọ rè, "Bóyá ní òla" (2014), ìtàn tí ó dá l'órí i ipò tí àwọn ènìyàn Niger Delta wà. Ìwé ná à ní atokọ fún ìgbà pípé l'énu gbígba ìwé àṣẹ l'órílè èdè Nàìjíríà l'ódún un 2014. L'éhìn-ò-r'ẹhìn, ó padà gba àmì èrí Àpéjo Àwon Onkòtàn (Association of Authors, ANA) ti Nàìjíríà. Ní Oṣù Kẹwàá (Oṣù Òwàrà), ọdún 2018, íwé e Cole mìíràn, Embers, f'arahàn gégè bíi èyí tó dára jùlọ nínú u àwọn òkàndínláàdórùn- ún(89) tí a şe àfihàn won fún pípéye, tó sì jo'jú fún ìwé lílò ní 2018. Ìwé náà dá l'órí i ipa tí ìwà ipá àti ìkolù ti èsìn ń kó l'órí i ìbágbépò àwọn ènìyàn ní Àríwá Nàìjíríà.
- Odò kékeré mi (2010)
- Ghost (2014)
- Bambo Bambo (2014)
- Bóyá Òla (2014)
- Agbègbè Ogun (2017)
- Embers
Yàyò sí àwọn àmì èyẹ tí ó wà ní ìsàlè, Cole ti ní atokọ fun Wolé Şóyínká Prize fún Lítíréşo ní Áfíríkà àti ìdíje ìfigagbága iṣé kíkọ BBC World.