Ṣọlá Ṣóbọ̀wálé tí wọ́n bí ní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kejìlá, ọdún 1963, jẹ́ òṣèré sinimá àti adarí eré ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [1] Ó di olókìkí ní ọdún 2001, nínú ìṣàfihàn ti Ìtàn-àkọọ́lẹ̀ Super Story  : Oh Father, Oh Daughter.

Ṣọlá Ṣóbọ̀wálé
Ọjọ́ìbí26 Oṣù Kejìlá 1963 (1963-12-26) (ọmọ ọdún 60)
Ìpínlẹ̀ Oǹdó, Nàìjíríà
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Ọmọ orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iṣẹ́
  • òǹkọ̀wé
  • òṣèré
  • adarí eré
Parent(s)Joseph Olagookun, Esther Olagookun

Iṣẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Ó dara pọ̀ mọ́ eré orí ìtàgé nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù tí Ẹgbẹ́ Awada Kẹrikẹri ṣe lábẹ́ adarí Adébáyọ̀ Sàlámì . [2] Láàárín ọdún díẹ̀, ó ti ṣe iṣẹ́ akọ̀wé, ìtọ́sọ́nà àti ìgbéjáde ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù Nàìjíríà. [3] Ó ṣe akọ̀wé, àgbékalẹ̀ ati ìtọ́sọ́nà, Ohun Oko Somida, fíìmù Nàìjíríà kan tí ó jáde ní ọdún 2010 èyí tí ó ṣe ìràwọ̀ Adébáyọ̀ Sàlámì . [4] Ó ṣe ìfihàn nínú Dangerous Twins, fíìmù ti Nàìjírà tí ó jáde ní ọdún 2004 tí Tádé Ògìdán ṣe, ẹni tó kọ fíìmù yìí ni Níji Àkànní . [5] Ó tún ṣe ìfihàn nínú Family on Fire ìṣelọ́pọ̀ ati ìtọ́sọ́nà nípasẹ̀ Tádé Ògìdán . [6]

Ìgbésí Ayé rẹ̀

àtúnṣe

Sola Sobowale jẹ́ ìyàwó Dotun Sobowale. Ó bí ọmọ mérin fún ọkọ rẹ̀.[7]

Àwọn àmì ẹ̀yẹ

àtúnṣe

Ní ọdún 2019, ó gba àmì ẹ̀yẹ African Academy Academy (AMAA) fún Òṣèré tó dára jù lọ fún ipá rẹ̀ ní fíìmù King of Boys tó jáde ní ọdún 2018.

Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀

àtúnṣe

Òṣèré

àtúnṣe

Olóòtú

àtúnṣe

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe