Family on Fire
Family on Fire Jẹ́ eré tí wọ́n gbé jáde ní ọdún 2011, tí Tade Ogidan darí rẹ̀. Àwọn gbajú-gbajà òṣèré bíi: Saheed Balogun, Segun Arinze, Sola Fosudo àti Sola Sobowale ni wọ́n kópa nínú rẹ̀.[1] Wọ́n ṣàfihàn fiimu náà ní ọjọ́ Kẹrin oṣù Kọkànlá ọdún 2011ní gbọ̀ngàn Lighthouse ní Camberwell ní ìlú London.[2] Lara àwọn gbajúmọ̀ òṣèré tí wọ́n tún kópa nínú rẹ̀ ni: Kunle Afolayan, Richard Mofe Damijo, Ramsey Nouah, Teju Babyface, Saheed Balogun, Segun Arinze àti Bimbo Akintola.[3] Wọ́n ṣàfihàn eré yí ní Ìpínlẹ̀ Èkó ní inú oṣù Kẹrin ọdún 2012. Lara àwọn òṣèré jànkàn-jànkàn tí wọ́n wá síbẹ̀ ni: Femi Adebayo, Desmond Elliot, Yemi Shodimu, nígbà tí àwọn lààmì-laaka eniyan tí wọ́n tún kópa níbiẹ̀ ni : Molade Okoya-Thomas, Business magnate, Abimbola Fashola àti Oladipo Diya, tí ó jẹ́ ọ̀gágun ajagun fẹ̀yìntì tẹ́lẹ̀ nílé iṣẹ́ ológun orí ilẹ̀ Nàìjíríà Chief of the Defence Staff.[4]
Family on Fire | |
---|---|
Adarí | Tade Ogidan |
Olùgbékalẹ̀ | Tade Ogidan |
Òǹkọ̀wé | Tade Ogidan |
Àwọn òṣèré | Saheed Balogun Segun Arinze Sola Fosudo |
Ilé-iṣẹ́ fíìmù | OGD Pictures |
Olùpín | OGD Pictures |
Déètì àgbéjáde | 2012 |
Àkókò | 145 minutes |
Orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Èdè | Yoruba and subtitled in English |
Bí wọ́n ṣe gbé eré náà kalẹ̀
àtúnṣeKunle (Saheed Balogun) gẹ́gẹ́ bí olú ẹ̀dá ìtàn ṣe ẹ̀ṣẹ̀ kan tí ó ń ti àwọn Oba rẹ̀ lójú. Ohun tí ó ṣe ni wípé, ó fi àpò oògùn olóró Kokéènì sínú báàgì Ìyá rẹ̀, tí ó ń lọ sí ìlú London láti lọ kí àbúrò rẹ̀. Ìyá Kúnlé ja ajà bọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ aṣọ́bodè ní ìlú London, Kúnlé fúnra rẹ̀ náà pòfo láti mú oògùn olóró yí kúrò nínú àpamọ́wọ́ Ìyá rẹ̀ látàrí bí wọ́n ṣe yí ìrìn-àjò ọkọ̀ òfurufú tí ó wọ̀ padà láti lọ sí UK. Amọ́, ìyàwó Fẹ́mi tí ó jẹ́ àbúrò ìyá rẹ̀ ṣalábàá-pàdé oògùn olóró náà nígbà tí ó ń tu eru óńjẹ tí Ìyá ọmọ rẹ̀ gbé bọ̀ láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ọmọ ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Moyọ̀ tí ó sì tún jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ji oògùn olóró náà gbé níbi tí wọ́n tọ́jú rẹ̀ sí tí ó sì tàá ní owó gọbọi. Kò pẹ́ kò jìnà, àwọn tí wọ́n gbéṣẹ́ fún Kúnlé bẹ̀rẹ̀ sí ń dààmú ẹbí Kúnlé. [4]
Awọn amì-ẹ̀yẹ tí eré náà gbà
àtúnṣeEré yí gba amì-ẹ̀yẹ ti 8th Africa Movie Academy Awards tí ó wáyé ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù Kẹrin ọdún 2012 ní Expo Centre ní Èkó Hotel &Suites ní Ìpínlẹ̀ Èkó.[5] Wọ́n yan eré náà fún amì-ẹ̀yẹ Best Nigerian Film ní orílẹ̀-èdè Naìjíríà. Àwọn àmì-ẹ̀yẹ yí ni wọ́n fún Adesuwa àti State Of Violence lọ́tọ̀ọ̀tọ̀.[6]
Àwọn ẹ̀dá ìtàn
àtúnṣeÀwọn itọ́ka sí
àtúnṣe- ↑ "Tade Ogidan plans to take Family on Fire to the people". Vanguard News.
- ↑ "Tade Ogidan sets family on fire". Vanguard News.
- ↑ "Family Ties, Drugs & Drama! Tade Ogidan’s New Blockbuster "Family on Fire" premieres in London this November". BellaNaija.
- ↑ 4.0 4.1 "Nollywood comes alive as Family on Fire premieres". The Punch - Nigeria's Most Widely Read Newspaper. Archived from the original on 2012-05-16. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "AMAA Nominees and Winners 2012 - Africa Movie Academy Awards". ama-awards.com. Archived from the original on 2014-02-14. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Nigeria and South Africa lead AMAA nominations - Africa Movie Academy Awards". ama-awards.com. Archived from the original on 2015-04-11. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)