Solomon Adeboye Babalọlá ni won bi ni ojo Ketadin-logun osu Kejila, odun 1926, o ku ni  ojo Keedogun osu Kejila, odun 2008 (December 17, 1926- December 15, 2008), ni  Ipetumodu, Osun StateNaijiria. O je Oluko, akewi ati elebun opolo.[1]

igbesi aye reÀtúnṣe

Babalọlá lo si ile eko Achimota College ni orile ede Ghana. leyin ti o keko gboye tan ni odun 1946,  o sise oluko ni Igbobi College. Ni 1948, o gba ebun eko ofe elekeji lati ko eko nile eko  Queens' College, Cambridge, nibi ti o tun ti gba  oye imo eko elekeji ni odun 1952. O tun pada si  Igbobi College lati te siwaju lori ise ikoni re ti o si ri agbega ti o fi di oluko agba ti o je adulawo ile eko naa , pelu bi o se je oluko ti o kere julo ninu awon oluko ile eko naa. Won fun ni eko ofe Omowe (doctoral scholarship) ninu litireso ede Yoruba. Ni 1962, won yan an gege bi oluko nile eko  Institute of African Studies ti Obafemi Awolowo University.[2] O tun je anfani eto imo eko ofe lo sile eko  University of London lati gba oye imo Omowe. Ni odun 1963 , o di ojogbon ninu imo ede ile adulawo (professor of African Languages)  ni ile University of Lagos. Ni odun 1966, o te iwe The Content and Form of Yoruba Ijala,ti ile ise itewe Oxford University Press gbe jade. Ise naa so nipa alo nitan Yoruba,awon ewi lorisirisi ati akojopo awon ewi Ijala ode (hunter's songs) poems, ti wo sogbufo re si ede Geesi. Iwe naa gba ami eye ti Amaury Talbot Prize fun ise to pegede julo lodun naa fun litireso awon eniyan apa iwo Oorun ile Adulawoa. Iwe naa tun silekun fun iwadi nipa ede ile Adulawo ni gbogbo abgaye, labe akoso Babalọlá ni University of Lagos. Eka eko to ri si io nipa ile Adulawo ati Asian ni won da sile ni odun 1967 ni Yunifasiti ilu Eko, ni eyi ti Babalola je okan lara awon oluko meta eka eko naa, ti won si gbajumo Nigerian languages gege bi Yoruba, Igbo, Edo ati Hausa.[3]

Awon Itoka siÀtúnṣe

  1. "S. Adeboye Babalola". Encyclopedia Britannica. 1926-12-17. Retrieved 2018-05-22. 
  2. "Merriam-Webster's Encyclopedia of Literature". Google Books. Retrieved 2018-05-22. 
  3. "Brief History of the Department of African and Asian Studies [archived]". About Us - Faculties of ARTS »» Department AFRICAN & ASIAN STUDIES [archived]. University of Lagos. Retrieved 18 April 2018. 

Àdàkọ:Authority control