Sonna Seck (tí àbísọ rẹ̀ jẹ́ Maimouna Seck tí wọ́n bí ní ọdún 1985) jẹ́ òṣèrébìnrin, akọrin àti apanilẹ́rìn-ín ọmọ orílẹ̀-èdè Guinea.

Sonna Seck
Seck in 2020
Ọjọ́ìbíMaimouna Seck
1985 (ọmọ ọdún 38–39)
Mamou, Guinea
Orílẹ̀-èdèGuinean
Iṣẹ́Actress, singer, comedian
Ìgbà iṣẹ́2007-present

Ìsẹ̀mí rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Seck ní ìlú Mamou ní ọdún 1985. Láti ìgbà kékeré rẹ̀ ni ó ti bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ àwọn orin àṣà níbi àwọn ayẹyẹ ìgbéyàwó àti ìrìbọmi. Seck lọ sí ilé-ìwé Lycee Yimbaya fún ètò-ẹ̀kọ́ girama rẹ̀. Ní ọdún 2007, ó lọ́wọ́sí dídásílẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèré kan tí wọ́n pè ní Djouri Djaama Acting Troupe, ó síì kó àkọ́kọ́ ipa fíìmù rẹ̀ nínu fíìmù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Yo-Allah Feounou In. èyí tí ó yọrí sí rere. Seck kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù nípasẹ̀ ẹgbẹ́ Djouri Djaama. Lára wọn ni Guigol Naferai Djoki, Mouyide Allah, àti Ahh Deboot . Àṣeyege àwọn fíìmù wọ̀nyí fún ẹgbẹ́ náà ní ànfàní láti ṣe àwọn iṣẹ́ míràn káàkiri orílẹ̀-èdè.[1]

Ó kópa gẹ́gẹ́ bi akọrin nínu eré rẹ̀ kan tí ó ṣe tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Gourdan-Païkoun. Níbẹ̀ ló ti kọ orin kan tí àkọ́lé rè jẹ́ Saya.[2]

Seck tún ti kọ àwọn orin bíi Bounguai, Sodanelan, àti Inmefidjin.[3] Ó ṣe àgbéjáde orin rẹ̀ tí ó gbajúmọ̀ jùlọ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Tourou Tourou ní ọdún 2015, tí orin náà síì tàn káàkiri orílẹ̀-èdè Guinea àti àwọn agbègbè rẹ̀.[4] Ààrẹ orílẹ̀-èdè náà, Alpha Condé, mẹ́nuba orin náà nígbà tí ó n sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìyẹ́sí àwọn obìnrin ti ọdún 2018.[5] Ní ọdún 2020, Seck bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àdáṣe rẹ̀ lábẹ ilé-iṣẹ́ orin Soudou Daardja Prod . Àkọ́kọ́ orin àdákọ rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ n ṣe Midho Yidhouma jẹ́ orin ìfẹ́ tí ó kọ fún ọkọ rẹ̀ tí n gbé ní Amẹ́ríkà.[6]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Zoom sur l’artiste Sonna Seck – Africa224 – Ne vous trompez pas de site". Africa224 (in French). 8 July 2020. Retrieved 27 October 2020. 
  2. "Zoom sur l’artiste Sonna Seck – Africa224 – Ne vous trompez pas de site". Africa224 (in French). 8 July 2020. Retrieved 27 October 2020. 
  3. "Zoom sur l’artiste Sonna Seck – Africa224 – Ne vous trompez pas de site". Africa224 (in French). 8 July 2020. Retrieved 27 October 2020. 
  4. "En Guinée, la chanson «Tour tour» fait danser tout le monde mais tiquer les femmes" (in French). 13 August 2017. https://www.rfi.fr/fr/afrique/20170813-guinee-chanson-tour-tour-danser-tiquer-femmes. Retrieved 27 October 2020. 
  5. "Le duo Tourou-tourou approché par le couple présidentiel" (in French). 9 March 2018. https://www.gnakrylive.com/guinee/societe/876-le-duo-tourou-tourou-approche-par-le-couple-presidentiel. Retrieved 27 October 2020. 
  6. "Sonna Seck : sa chanson «Midho Yidhouma» franchie la barre des 1 million des vues (video)". Afrique Showbiz (in French). 24 September 2020. Archived from the original on 31 October 2020. Retrieved 27 October 2020. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

àtúnṣe