Ọ̀gbẹ́ni Syed Anwarul Haq Haqqi (tí a tún mọ̀ sí S. A. H. Haqqi; tí wọ́n bí lọ́jọ́ kejìlélógún oṣù kìíní ọdún 1922 – ó kú lọ́jọ́ kẹwàá oṣù kejì ọdún 2010) jẹ́ ọ̀mọ̀wé ọmọ orílẹ̀-èdè India tí ó fìgbà kan jẹ́ olórí Ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìṣèlù ní Aligarh Muslim University fún ọdún ogún ọdún. Ó jẹ́ àbúrò sí Abrarul Haq Haqqi

Syed Anwarul Haq Haqqi
Born22 January 1922
Hardoi, United Provinces of British India
Died10 February 2010(2010-02-10) (ọmọ ọdún 88)
CitizenshipÀdàkọ:Bulleted list
Alma materÀdàkọ:Bulleted list
Doctoral advisorMohammad Habib

Ìtàn ìgbésíayé

àtúnṣe

Wọ́n bí Syed Anwarul Haq Haqqi lọ́jọ́ kejìlélógún oṣù kìíní ọdún 1922 in Hardoi.[1] Ó kàwé gboyè B.A.University of Lucknow, bẹ́ẹ̀ náà ó kàwé gboyè M.A nínú ìmọ̀ ìtàn ní Aligarh Muslim University. Ó kọ̀wé iṣèwádìí ìkàwé-gboyè ọ̀mọ̀wé lórí Timur lábẹ́ ìmójútó Ọ̀gbẹ́ni Mohammad Habib. Ó kọ̀wé iṣèwádìí ìkàwé-gboyè ọ̀mọ̀wé kejì lórí "Ètò Ìṣèjọba Àwọn Òyìnbó Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì" ní London School of Economics.[1]

Haqqi jẹ́ adarí ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ ìmò ètò-ìṣèlú ní Aligarh Muslim University fún ogún ọdún.[1] Lọ́dún 1967, ó bẹ̀rẹ̀ àtẹ̀jáde jọ́nà tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ Indian Journal of Politics. Ó sinmi lénu isẹ́ lọ́dún 1982. Lẹ́yìn èyí, ó tún ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní University of Warsaw, Middle East Technical University àti University of Kashmir gẹ́gẹ́ bí ààrè Ọ̀jọ̀gbọ́n visit.[1]

Ẹ̀gbọ́n Haqqi ọkùnrin, Abrarul Haq Haqqijẹ́ ọ̀mọ̀wé ìmọ̀ ẹ̀sìn Mùsùlùmí tí ó dá Ashraful Madaris sílẹ̀ ní Hardoi. [2]

Haqqi kú lọ́jọ́ kẹwàá oṣù kejì ọdún 2010. [1]

Àwọn ìwé iṣẹ́ ọ̀nà

àtúnṣe

Lára àwọn ìwé iṣẹ́ ọ̀nà Haqqi ni: [3]

  • Chingiz Khan: The life and Legacy of an Empire Builder[4]
  • Indian democracy at the crossroads
  • The Union-State relations in India
  • Secularism under siege : the Ayodhya tragedy in retrospect and prospect
  • Democracy, Pluralism and Nation-Building
  • The Turkish Impact on India the First Phase [5]
  • The Atatürk Revolution and India [6]
  • The Faith Movement of Mawlānā Muḥammad Ilyās
  • The colonial policy of the Labour Government
  • Problems of representation in the new states
  • Machiavelli and Machiavellism (Urdu)

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 Professor Shan Mohammad. "IN MEMORIAM PROFESSOR SYED ANWARUL HAQ HAQQI (1922‐2010)". Aligarh Muslim University. https://www.amu.ac.in/pdf/psim.pdf. 
  2. Àdàkọ:Cite thesis
  3. "Books authored by S A H Haqqi". viaf.org. Virtual International Authority File. Retrieved 28 July 2020. 
  4. "Chingiz Khan: the Life and Legacy of an Empire Builder". academic.oup.com. Retrieved 28 July 2020. 
  5. "The Turkish Impact on India the First Phase, 1206-1414". Middle East Technical University. 1984. Retrieved 28 July 2020. 
  6. Danforth, Sandra C.; Tachau, Frank (1982). "Scholarly Meetings Held in Commemoration of the Ataturk Centennial". Middle East Studies Association Bulletin 16 (2): 5. doi:10.1017/S0026318400011627. JSTOR 23057674.